Second Term SSS 1 Yoruba
SECOND TERM E-NOTE
SUBJECT; YORUBA. CLASS-; SS1
ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI
Ose kinni- Ede-Atunyewo awon isori oro
- oro aropo oruko
- oro aropo afarajoruko
- oro atokun
- oro asopo
- oro-ise
Asa- Oge sise
Litireso-Itupale asayan iwe litireso
Ose keji Ede- Awon isori gbolohun gege bi ihun won.
Asa- Oge sise
Aso wiwo laarin okunrin ati obinrin
Awon ayipada ti o de ba aso wiwo aye atijo ati ode-oni.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose keta Ede- Awon isori gbolohun gege bi ise won.
Asa- Asa ila kiko
– pataki ati iwulo ila.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose kerin Ede- Aroko Asapejuwe;ilana kiko aroko
– Awon ori-oro to je mo aroko asapejuwe.
Asa- Asa Igbeyawo Ni Ile Yoruba.
- Awon igbese igbeyawo abinibi
- Awon ohun elo idana.
Litireso – Itupale asayan iwe litireso.
Ose karun-un Ede- Aayan Ogbufo; ilana sise aayan ogbufo.
Asa – Orisii igbeyawo ti o wa
- igbeyawo nisu loka
gbigbe ese le iyawo
ana sise ni ile Yoruba.
Litireso- Itupale asayan iwe litireso.
Ose kefa Ede – Aayan Ogbufo; sise ogbufo ayoka ede Geesi si ede Yoruba.
Asa – Igbeyawo ode-oni-soosi, Yigi,Kootu.
- iyato ati ijora ti o wa ninu igbeyawo ode-oni ati atijo.
Litireso- itan olorogeere gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba
-itan isedale Yoruba
– itan awon eya Yoruba
ose keje- Ede- Onka Yoruba;onkaye lati ori ookan titi de Egbaa (1- 2000)
Asa- Oyun nini,itoju oyun,ibimo.
Igbagbo Yorubanipa agan,omo bibi ati abiku
Aajo lati tete ni oyun.
Eewo ati Oro idile.
Litireso – Itan oloro geere gege bi orisun itan ati asa Yoruba; Asa bi Yoruba se n sin oku sinu ile.
Ose kejo- Ede- Atunyewo eko lori eka ede Yoruba; Ijesa, Ekiti,Oyo.abbl.
- iwulo Yoruba Ajumolo
Fifi eka ede we Yoruba ajumolo
Asa- Isomoloruko Ni Ile Yoruba
- Pataki siso omo loruko
- Ohun elo ati isomoloruko.
Litireso-Itupale asayan iwe litireso.
Ose kesan-an
EDE-Aroko asotan/ oniroyin.
Orisii ori-oro ti o je mo aroko oniroyin
Asa- Orisii oruko ti a le so omo
- oruko amutorunwa
- abiso abbl
Litireso alohun oloro wuuru; Aalo orisirisi- apamo, apagbe,
iwulo aalo
awon ona ede ti o wa ninu aalo.
Ose kewaa- Ede- Isori oro-oruko
Oriki
Orisii
Ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun.
Asa- Ipolowo oja; Iwulo ati pataki ipolowo oja.
Orisiirisii ona ipolowo oja ti abinibi-ikiri, ipate,ipolowo pelu ohun enu.
Litireso – Ewi alohun gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba; oriki orile,ijala abbl
Ose kokanla- Agbeyewo ise saa keji lapapo..
Ose kejila- Idanwo saa keji.
OSE KINNI
ORI-ORO-;ATUNYEWO AWON ISORI ORO
-Oro-oruko
ORO AROPO ORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo oruko
- Ate oro aropo oruko
- Irisi oro aropo oruko.
AKOONU
Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere
‘Bolu je akara.
‘O je e.’
‘ewure je agbado Bola’
‘ewure je agbado re.
Abuda oro aropo oruko.
- Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere
O lo [ eyo ni o ]
Won wa [ opo ni won]
- oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.
enikinni /eyi ni eni ti o n soro.
Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.
Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.
Mo ko leta.
O ko leta
O ko leta.
- Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.
IYE Eyo opo
Enikin-in-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won.
- A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere
mo ati o
wa ati won.
- A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere
mo n ko?
E da?
O ko?
- A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere
mo naa
e gan-an
IRISI ORO AROPO – ORUKO.
Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.
- O le sise oluwa
- Abo
- Eyan ninu gbolohun.
Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,
IYE EYO OPO.
Enikin-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won
Apeere;- mo n jo
O n jo
Won n jo
E n jo
A n jo.
Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.
Iye Eyo Opo.
Enikin-in mi wa
Enikeji o/e yin
Eniketa faweli won
Oro-ise gun
Baba na mi.
Bolu n pe o/e
Oluko pe e.
Oba ri wa.
Ipo eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.
IYE EYO OPO.
Enikin-ni mi wa
Enikeji re/e yin
Eniketa re/e won.
Apeere; –
Aja mi
Aja re
Aja re
Ile wa
Aso yin
Aja won.
IGBELEWON.
- Kin ni oro aropo oruko?
- salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.
ORO AROPO AFARAJORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo afarajoruko
- Irisi oro aropo afarajoruko.
- AKOONU : –
Oro aropo-afarajoruko ni isesi to farajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin,awon.fun apeere.
Emi ko ri Bola.
Ile awa dun.
Abuda oro aropo afarajoruko.
- Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.
Ate oro aropo afarajoruko.
IYE EYO OPO.
Enikin-ni emi awa
Enikeji iwo eyin
Eniketa oun awon.
Fun apeere : – iwo ni won ran
Awa naa n bo.
- A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.
emi ati iwo.
Awa ati eyin.
iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere
iwo n ko?
Oun da?
Eyin ko.
- Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.
emi – e /mi.
iwo – I /wo.
- Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere
emi naa wa.
Awon gan-an wa.
- A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
- Eyin ni oga n pe.
- emi ni mo ra iwe naa.
IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.
Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.
Emi naa mu osan.
Oun ni won n bawi.
LITIRESO.
Kika iwe litireso.
ORO APONLE
AKOONU
Oro-aponle je oro ti o maa n pon oro-ise ninu gbolohun, o ma n se afikun itumo fun apola-ise, ti yoo si je ki itumo re si tubo ye ni yekeyeke.
Tobi jeun die
Bolu n rin kanmokanmo bo
Ninu apola-ise ni oro-aponle ti maa n jeyo ninu gbolohun
Oro-ise ni oro-aponle maa n pon ninu gbolohun oro-aponle maa n se afikun ituom fun oro-ise.
Tade dide fuu
Igi naa ga fiofio
Irufe oro-aponle inu ede Yoruba orisii meji ni oro-aponle, awon naa ni:-
Awon oro-aponle aiseda
Awon oro-aponle aseda
Oro aponle aiseda ni oro-aponle ti a ko seda, iru oro yii kii ni ju silebu kan tabi meji lo. A won ni fio, kia, gan-an logan
O lo logan
Ile naa ga fio
- Oro-aponle aseda:- ni oro-aponle ti a seda lati ara oro-aponle, nipa sise apetunpe oro-aponle ponbele
Kia + Kia = Kiakia
Wadu + Wadu = waduwadu
Pele + pele = peleple
Jan + jan = Janjan
Kele + kele = kelekele
Tobi n laagun yoboyobo
Mo n laagun yobo
Aso naa funfun gboo
Obe naa ti tan yanyan
Osupa mole rokoso
ORO-ISE
- Oriki
- Iwulo oro ise
- Ona ti a le gba lati da oro ise mo.
- Isori oro ise.
AKOONU : –
Oro-ise ni oro ti o ba le duro bii koko fonran ninu gbolohunoro-ise ni oro ti o n toka si ohun ti oluwa se ninu gbolohun laisi oro ise ninu gbolohun ko le ni itunmo nitori ohun ni o je opomulero fun gbolohun.Ap.
Baba ra bata.
Olu fo aso.
Bi a ba yo oro-ise kuro ninu awon gbolohun wonyii ko le ni itunmo.
ONA TI A FI LE DA ORO-ISE MO.
- Oro-ise ni o maa n jeyo leyin oluwa.ap ‘mo je eba.’ ‘won gba owo’.
- oro ti o ba le tele erun oro-ise ‘n’ gbodo je oro-ise.ap ‘Ade n ko iwe’ ‘ mama n se obe.’
- oro ti o ba jeyo leyin yoo,maa,fi ati ti gbodo je oro-ise.Ap ‘Akekoo yoo se idanwo’ ‘oluko maa wa.’ ‘baba ti de’.
- oro ti o ba tele atoka iyisodi ‘ko/o gbodo je oro-ise.Ap ‘ Bayo ko ra aso.’ ‘ oluko ko je eba’.
ISORI ORO ISE.
Orisiirisii isori ni awon onimo girama pin oro ise si ninu ede Yoruba.
- Oro –ise Agbabo : – ni oro-ise ti a maa n lo abo pelu re ninu edeap ‘Tolu sun’ Tope kuru.’ ‘ ojo ro’.
- Oro ise asebeere : – meji naa ni o wa ninu ede Yoruba,awon naa ni da ati nko.fun apeere ‘ mama da’ ‘Bisi nko’.
- Oro ise asokunfa : – Eyi ni oro –ise ti o maa n se okunfa isele,awon oro-ise asokunfa ni;so,mu,se,ko,fi,da. Apeere Bola da erin pa mi. Bade fi iya je Sola. O se iku pa aja re.
- Oro-ise Elela: – Eyi ni oro-ise ti a le fi oro-oruko ti o duro fun abo bo laarin ninu gbolohun.apeere bawi,reje,pada,danu. ‘ mama ba omo wi’ ‘ Bola re mi je’ ‘ Baba da isu nu.
- Oro ise akanmoruko : – Eyi ni a seda lati ara apapo oro-ise ati oro-oruko.Apeere ‘Tope muti yo [mu oti] ‘mama gunyan je [gun iyan] ‘ Abiola lawo pupo [la owo].
- Oro-ise Asapejuwe : – ni oro-ise ti a maa n lo lati so irisi nnkan.Apeere ‘Bisi pupa foo’ ‘Eyin Tolu funfun’ ‘ Tope ga’.
- Oro ise Asoluwadabo : – ni oro-ise ti oluwa ati abo le gbapo ara won.Eyi nip e a le si oluwa ati abo ni ipo pada laisi iyato ninu gbolohun naa.Apeere- ‘ Ojo n se were,were n se Ojo’ ‘ mo ti ju’ ‘oju ti mi’ ‘ mo jaya,aya mi ja’.
- Oro-ise Alapepada: – ni oro ise ti a maa n se apetunpe fun ninu gbolohun.Apeere ‘ iwo ni o ku mi ku’ ‘ E row a ro ire’ ‘Aye ko feni foro’ ‘ ma da mi da wahala’.
- Oro-ise Asinpo : – ni oro-ise ti o maa n je meji tabi meta ninu gbolohun pelu oluwa kan.iye oro ise ti o wa ninu gbolohun yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo.fun apeere, ‘Ola sun isu ta.-Ola sun isu. – Ola ta isu. ‘Tope ji eran je’. – Tope je eran. – Tope ji eran.
Bolu sare lo gbe aga wa.
- Bolu sare
- Bolu lo
- Bolu gbe aga
- Bolu wa.
Ori – oro: Isori oro: Oro-asopo
- Oriki
- Orisii wunren oro-asopo
iii. Ise ti won n se ninu gbolohun
AKOONU
Oro-asopo ni awon wunren ti a n lo lati so awon oro tabi gbolohun bii meji tabi ju bee lo po di gbolohun kan.
Apeere
- Ade feran iresi
- Tomi feran iresi
- Ade ati Tomi feran iresi
- Ile re tobi
- Iyara re kere
Ile re tobi sugbon iyara re kere. Awon wunren oro-asopo inu ede Yoruba ni ati pelu, oun afi sugbon nigba ti, ayafi, abi, amo, bee ni, yala, tabi anbosi bosi abbl
Ise ti won n se ninu gbolohun ise oro-asopo ni fun siso oro tabi gbolohun papo.
- ‘ati’, pelu ati oun ni a fi n so
(a) oro-oruko, meji po ninu oro
apeere:
Tolu ati Oye lo si ilu oba
Tunde Pelu Toyin lo si Ikorodu
Ola oun Bayo jo n kawe
(b) A le fi so oro-aropo afarajoruko meji po ninu iso
apeeere
Iwo ati oun ni oloro
Awon pelu eyin kii se egbe
(d) A le fi ‘ati’, pelu so oro-oruko ati oro aropo afarajoruko po
apeere:
Iwo ati Deinde ni mo ri
Emi pelu Rotimi n ka iwe iroyin
(e) Sugbon, tabi, amo. A n lo awon oro wonyi lati so gbolohun meji po ti abayori re yoo je gbolohun olopo oro ise alakanpo.
Apeere:
Bola pe mi sugbon n ko dahun.
Mama ni owo amo won o ra aso.
Isori oro:- Oro-atokun
Wunren oro-atokun
- Ise ti won n se ninu gbolohun
- Ibi ti won ti n jeyo
AKOONU
Oro – atokun ni oro ti a n lo lati so iha ti oro-oruko meji kosi ara won. Awon wunren atokun inu ede Yoruba ni: si, ti, ni. Oro-atokun maa n jeyo saaju oro-oruko ninu gbolohun.
Apeere:
Ade ti Ikeja lo si Oyingbo ni ana
Ise ti oro-atokun maa n se
Ninu ihun gbolohun, oro-atokun maa n toka
- Ibi ti eniyan tabi nnkan n lo. Oro atoka re ni – si
Apeere:
Mo lo si Ibadan
Oduduwa tedo si Ile Ife
II O maa n fi ibi ti eeyan tabi nnkan ti n bo han. ‘ti’ ni wunren re
Apeere:
Dele ti Akure de lanaa
Eru ti ori aja ja lule
III. Oro_atokun maa n se afihan ibi ti eeyan tabi nnkan wa. ‘ni’ ni atoka re.
Apeere:
Talabi wa ni Ikeja
Olu wa ni Eko
Mama wa ni ile Hausa
ORO APEJUWE
Oro-apejuwe-; ni oro ti o maa n yan oro-oruko ninu gbolohun.A n lo oro-apejuwe lati se alaye yekeyeke ohun ti a n soro ba ninu iso.
Ap.
Omo pupa ni Bunmi.
Esin funfun ni baba ra.
Oti lile ko dara.
Iwa rere ni eso eniyan.
Iro konsonanti lo maa n bere oro apejuwe.
ap
Omo kekere ni mo je.
Inu apola oruko ni oro –apejuwe maa n wa.
ap
Irin rederede ko ye omoluabi.
Orisii oro-apejuwe
Oro-apejuwe ipile-;eyi ni awon oro bii rere,kekere,nla.
Oro-apejuwe iseda-; eyi ni awon wunren oro-apejuwe ti a seda nipa sise apetunpe elebe.
Ap
Mu -mimu
ro -riro
bo -bibo
oro apejuwe ti a seda nipa apetunpe
ap
nla- ile nlanla ni won fun wa.
Igbelewon
Tokasi oro apejuwe ti o wa ninu gbolohun yii
Sile mefamefa ni oluko fun wa.
Omo giga ni Bola.
Oruko rere san ju wura oun fadaka lo.
Igbelewon
- Kin ni oge sise?
- Daruko awon ona ti a n gba se oge ni aye atijo.
kin ni oro-ise?
Salaye isori oro-oruko meta pelu apeere metameta fun ikookan.
IWE AKATILEWA
Imo, ede, asa ati litireso fun ile-eko sekondiri agba i.o. 163
– Eko ede Yoruba titun i. o.105
-ISE ASETILEWA
- ___________oro-aponle maa n pon ninu gbolohun
(a) Oro-Oruko (b) Oro ise (d) Eyan
- Inu ____________ni a ti maa n ba oro-aponle pade
(a) Apola-aponle (b) apola-oruko (d) Apola ise
- ‘lau je je apeere oro-aponle ______________
(a) aseda (b) alaiseda (d)
- . Atoka oro asopo ti a le fi so gbolohun meta po di eyo kan ni
(a) ati (b) yala…..tabi (d) amo
- Iwo oun Deinde kii segbe. Oro asopo inu iso yii ni
(a) iwo (b) oun (d) segbe
Apa keji
- Salaye awon isori oro wonyi pelu apeere metameta fun ikookan
- oro-ise
- oro-atokun
- oro-asopo
OSE KEJI
ORI-ORO- AWON ISORI GBOLOHUN GEGE BI IHUN WON.
Gbolohun-; ni ipede ti o kun to si ni ise ti on je.
Won fun gbolohun ede Yoruba ni oruko gege bi ise ti o n se.
Eyi ni awon gbolohun gege bi ihun won;
Gbolohun eleyo oro-ise
Gbolohun olopo-oro-ise
Gbolohun alakanpo
Gbólóhùn eleyo oro-ise-: ni gbolohun ti o maa n ni eyo oro ise kan
Apola oro oruko ati apola oro ise ni o maa n wa ninu gbolohun eleyo oro-lse
Apeere
Apola oro-oruko Apola oro-ise
Olu sun
Mo ra eran
Tisa na titi
Baba te eba.
Gbólóhùn olopo oro-ise-: eyi ni gbolohun ti o maa n ni ju oro-ise kan lo, o le je meji, meta tabi ju bee lo. Iye oro-ise ti o ba wa ninu gbólóhùn yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo ninu re.
Apeere
– Omo naa gba ile baba mo tonitoni
– Omo naa gba ile baba
– Ile baba mo tonitoni
– Bolu sare lo ra aso
– Mama lo ra eran wa
Gbólóhùn -ase ni a maa n lo lati pase.
Gbolohun alakanpo-;eyi ni gbolohun ti a fi oro-asopo so awon gbolohun po mo ara won lati di eyo kan.okookan awon iso yii ni won le da duro.
ap
Ola wa
Ola ko ba mi
Ola wa sugbon ko ba mi.
Awon oro-asopo ni; ati, amo, sugbon,
Titi ati Folake n gbafe ni ita.
O ni aya sugbon ko lowo.
Igbelewon
Salaye awon gbolohun wonyi pelu apeere mejimeji fun ikookan
Gblolohun eleyo oro-ise
Gbolohun olopo oro-ise
Gbolohun alakanpo.
ASA
ORI-ORO-;ASO WIWO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN
Aso wiwo-; je okan lara asa Yoruba ti o se pataki nitori pe ohun ni a fi n bo ihoho wa.
Bakan naa, aso wiwo maa n je ki a dun un wo ki oju wa si gun rege.
Orisiirisii aso ni awon Yoruba ni,ti ohun ti a n lo ikookan won fun si yato si ara won.
A pin awon aso Yoruba si
Aso ise
Aso iwole
Aso imurode
Iran Yoruba ki i wo aso idoti ,ohun ti won fi n pe won ni afinju niyi.Orisiirisii aso ni a ni ni ile Yoruba, aso obinrin yato si ti okunrin bee naa ni aso okunrin yato gedegbe si ti obinrin.Ni ile Yoruba obinrin ki I wo aso okunrin bee ni okunrin ko gbodo wo aso obinrin.
Aso okunrin Aso obinrin
Buba buba
Adiro iro
Dandoogo gele
Agbada iborun
Dansiki ipele
Sapara
Oyala
Sulia
Gbariye
Kafutaani
Kenbe
sooro
Atu
Kamu
Abeti aja
Origi/ ikori
Adiro
Ayipada ti o de baa so wiwo aye atijo
Orisiirisii ayipada ni o ti de baa so wiwo ni aye-ode oni,asa igbalode ti je ki imura ati iwoso yato si ti aye atijo.
Aso lo n basiri ara ju sugbon ni aye ode-oni aso to n fi ihoho awon odo han ni won n wo.
Ni aye atijo awon obinrin ki i wo sokoto.Oge odi sise ti so awon obinrin di eni ti on wo sokoto.
Aso ti won n wo ni aye ode-ni ni
Kootu
Seeti
Tai
Sokoto
Kaba
Sikeeeti
Igbelewon
1.Kin ni oge sise?
b.Daruko orisii ona ti a n gba soge laye atijo.
- Daruko orisii aso okunrin ati obinrin marun-unmarun-un.
IWE AKATILEWA
Simplified Yoruba Language Literature and Culture bk 1 o.i 82-85,21-27.
ISE ASETILEWA
1.Ibo lo ti n bo je
(a) Gbolohun alaye (b) Gbolohun ase (d) Gbolohun ibeere.
- Gbogbo yin, e maa bo je
(a) Gbolohun kani (b) gbolohun ibeere (d) gbolohun ase
- Dandoogo je apeere aso———-
(a) omode (b) okunrin (d) obinrin
- ——— ni a n pea so ti awon ode maa n wo lo si igbe
(a) aso ode (b) gberi (d) jerugbe
- Apeere aso ti a n wo laye ode-oni ni
(a) iro (b) sikeeti (d) oyala
APA KEJI
-
- Salaye awon gbolohun yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.
Gbolohun alakanpo
Gbolohun ase
Gbolohun ibeere.
2,Kin ni oge sise?
b.Daruko orisii ona ti a n gba soge ni aye atijo
- Daruko orisii aso marun-un fun okunrin ati obinrin.
OSE KETA
ORI-ORO-;AWON ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA GEGE BI ISE WON.
Ori-oro Isori gbolohun gege bi ihun won
Ori – oro Isorí gbólóhùn gégé bíi ìse wọn
Oríkì
Ìsorí gbólóhùn pèlú àpẹẹrẹ
àkóónú
Gbólóhùn ni ìpèdè tí ó kún, tí o sí ní ìse tí ó ń jé.
Gbólóhùn jé ìsọ tí ó ní ìtumo kíkún.
A fún àwon gbólóhùn Yorùbá ní orúkọ gégé bí íse tí won ń se
Àpẹẹrẹ
Bólú je èbè
Bàbá kọ ebè
Èyà gbólóhùn
Orisiirisii ni awon eya gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba.
Gbólóhùn Ibeere
Gbólóhùn Ase
Gbólóhùn Alaye
Gbólóhùn Akiyesi alatenumo
Gbólóhùn Kani
Gbólóhùn lyisodi
Gbólóhùn -ase ni a maa n lo lati pase
Apeere
Wa
Jade
Dake
Lo pon omi wa
Gbólóhùn lbeere-: ni a maa n lo lati se lbeere tabi wadii nnkan ni orisiirisii ona nipa lilo wunren lbeere bii kin ni elo, nibo, tani, meloo, nigba wo.
Kin ni oruko re?
Nibo ni o n lo?
Elo ni o ra iwe yii?
Tola da ?
Se olu ti wa?
Gbólóhùn kani-: ni a fi maa n so wulewule bi nnkan se ri ati idi ti o fi ri bee.
Apeere
Bi mo ba lowo, maa kole
Kaka ki n jale, maa seru
Bi bolu ba ro be yoo jeko
Gbólóhùn akiyesi alatenumo-: ni a fi n pe akiyesi si apa kan koko inu odidi gbólóhùn. ‘Ni’ atoka gbolohun yii . A le se atenumo fun oluwa ,abo tabi oro-ise .
Apeere
Mo ra iwe
Iwe ni mo ra (abo)
Rira ni mo iwe (oro-ise)
Emi ni mo ra iwe (oluwa)
Gbolohun iyisodi-: ni a fi n ko isele
Apeere
Bolu ko jeun
Baba ko yo
Se o maa lo?
N ko lo.
Bolu ti de?
Ko tii de
,
Igbelewon:
Kin ni gbolohun?
Salaye eya gbolohun marun-un pelu apeere kookan.
I
ASA
ORI-ORO -;ILA KIKO
Ila kiko je okan lara ise abinibi ti a ni aye atijo,o je ise iran tabi ise idile,ise yii ni o je mo ila kiko.Tokunrin tobinrin, tomode tagba ni o maa n kola laye ayijo.
Awon oloola ni o maa n ko ila laye atijo, o si je ise okunrin.Ohun ti won fi n ko ila ni abe sekele,osun,ose dudu,omi ogbin ewe feru.Aaro kutukutu ni won maa n ko ila
AKOON
Pataki ati iwulo ila
Ila kiko je okan lara awon ona ti a n gba sara loge laye atijo,awon Yoruba maa n
ko ila ni orisiirisii ona,bi a ti ri awon to n kola si ereke,iwaju ori ati agbon naa
ni a ri awon ti n ko ila si ara ,lati igbaya titi de isale ikun ati lati eyin de ibadi.
Pataki ila kiko
Idi Pataki ti a fi n ko ila oju ni ile Yoruba pin si ona m
- Ona akoko ni pe ila kiko maa n je ki a da ara wa mo ni aye atijo.
- O maa n bukun ewa wa ni aye atijo.
Ila oju yii pin si orisiirisii bee ni won yato lati agbegbe kan si ikeji,awon ila ti a ni naa ni-;
Pele
Baamu
Abaja
Keke
Ture
Gombo
Ila ondo
Pele-; ni ila meta ooro ti a fa si ereke,o wopo laarin awon Ijebu.
Gombo-; eyi ni ila gigun ti a fa lati ori,ti o si te woroko, o wopo laarin awon Oyo,Ogbomoso,Iwo,Ede ati Osogbo.
Ila ondo-; eyi ni ila kookan ti a fa si ereke, eyi wopo laarin awon Ondo.
Awon oloola lo maa n ko ila laye atijo,ohun-elo ti won maa n lo ni abe,omi igbin abbl.
Igbelewon
- kin ni oge sise?
- Daruko orisii ona ti a n gba sara loge laye atijo.
- Daruko orisii ila ti a ni ati idi meji ti a fi n ko ila laye atijo.
Iwe A katilewa.
Eko Ede Yoruba Titun,Oyebamiji Mustapha et al.203-215.
ISE ASETILEWA
1 Koko ise oloola ni——–
(a) ara finfin (b) eyin pipa (d) ila
- ——– ni ila meta ti a ko ni ooro
(a) keke (b) ila meta (d) pele
- Igba wo ni won maa n ko ila ni aye atijo?
(a) aaro (b) osan (d) ale
- —— ni atoka fun gbolohun akiyesi alatenumo
(a) ti (b) ni (d) si
5.Ade tobi sugbon ko ni agbara je gbolohun
(a) akiyesi (b)alakanpo (d) ase.
APA KEJI
- Salaye awon isori gbolohun yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.
Gbolohun akiyesi alatenumo
Gbolohun iyisodi
Gbolohun kani.
2 Daruko orisii ila merin ti o mo.
b.Daruko ohun elo meta ti a n lo fun ila kiko.
OSE KERIN
ORI-ORO-;AROKO ALAPEJUWE
Aroko alapejuwe-; je aroko ti a fi n se apejuwe nnkan,nnkan yii le je ohun elemii tabi ohun alailemii.
Aroko alapejuwe ni a maa n lo lati yaworan nnkan ti o wa ni ookan aya eni sile ni ona ti eni ti ko si nibe yoo le fi oju inu wo o bi isele tabi nnkan naa se ri gan-an.
Eyi ni apeere awon ori-oro ti o je mo aroko alapejuwe
- Aafin oba kan ti mo wo ri
- Oja ale
- Ija kan ti o soju mi
- Omobinrin kan ti o wu mi lati fe.
- Oja igbalode kan ti mo mo.
Igbelewon
Ko aroko lori
Ile-iwe re.
ASA
ORI-ORO-;ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA
Ni ile Yoruba paapaa laye atijo,awon Yoruba ko fi owo yepere mu igbeyawo rara,won ka a si nnkan pataki,gbogbo ohun to si ro mo igbeyawo naa ni o se pataki.
Gbogbo ohun ti o se pataki ninu igbeyawo yii ni won o ka si mo ni aye ode-oni,eyi si ni ko je ki igbeyawo pe mo ni ode-oni ko to daru. Igbeyawo je ibasepo laarin ebi meji ,o je igbeyawo laarin ebi oko ati ebi iyawo.
Igbeyawo je isopo okunrin ati obinrin lati maa gbe po gege bi oko ati aya.
Awon okunrin n gbe iyawo lati je oluranlowo fun won.
Bakan naa won fe ara won ki won ba a le ni aaro laye.
IGBESE IGBEYAWO
Eyi ni awon igbese igbese igbeyawo ti won maa n tele ni aye atijo
-Ifojusode
– Iwadii
– Alarina
– Isihun/ Ijohen
– Itoro
– Idana
– Igbeyawo
Ifojusode-;eyi ni igbese akoko ninu eto igbeyawo,bi odomokunrin ba ti balaga, yoo fi oju sode lati wa eni ti o wu u lati fe,bi o ba je aye atijo ni awon obi lo maa n foju sode lati wa iyawo fun omo won,ki i se ewa oju nikan ni won n fe bi ko se ati iwa.
Iwadii
Leyin igba ti odomokunrin ba ti ri iyawo to wu u lati fe,ohun ti yoo se ni pe yoo so fun awon obi re,awon obi re yoo si se iwadii iru iwa ti iya omo naa n hu nitori won gbagbo pe bi iwa iya ba ti ri bee ni ti omo re obinrin se maa ri.Won yoo se iwadii finnifinni bi arun buburu kan bi ete, warapa ati ikofee ba wa ninu ebi won,won yoo wadii boya ajigbese ni awon obi re abbl.
Paripari re won yoo wadii lodo Ifa bi igbeyawo won yoo ti ri, bi ifa ba fore abusebuse.
Igbese keta ni alarina,alarina je iko ti o maa n gbokegbodo laarin odomokunrin ati odomobinrin ti won fe fe ara won.
Okan pataki ninu ise alarena yii ni lati se iwadi finifini nipa omobinrin naa ati idile re. Eni to ba se e finu tan ni a maa n lo gege bii alarena nitori ise elege ni ise naa. Oun ni yo mo gbogbo ogbon ati ete ti yoo lo lati ri pe omobinrin naa je hoo. Ni kete ti awon mejeeji ba si ti pade ti won ti moju ara won ise alarena pari niyen. Eyi ni won fi maa n powe pe bi oko ba moju aya tan alarena a yeba.
IJOHEN/ISIHUN
Orisirisi iwadi ni awon idile omobinrin naa maa n se lati mo iru idile ti omokunrin to fe fe omo won ti wa. Boya won ni aisan kan to n ja won tabi idile onigbese ni won. Ti ko ba ti si iwa abuku kankan ni idile naa, ti o si dun mo omobinrin lati fe okunrin naa ni omobinrin naa yoo to wa dahun pe oun gba. Gbigba ti omobinrin yii gba lati fe omokunrin naa ni a n pe ni ijohen tabi isihun.Poun meji sile meji ni owo isihun ti oko yoo san fun iyawo afesona re.
ITORO
Gege bi asa Yoruba, ni kete ti omobinrin ba ti johen fun omokunrin oun ti o kan ni ki awon obi omokunrin naa lo se itoro lodo awon obi omokunrin naa. Ibi ni gbogbo eniyan yoo ti mo won gege bi afesona ti won yoo si da ojo idana
IDANA
Ojo idana ni ojo ti awon ebi omokunrin naa yoo wa san gbogbo ohun ti awon ebi iyawo ba fe gba patapata laiku eyokan. Ariya ranpe lewaye ni iru ojo yii, igba yii ni won to sese ma mo awon mejeeji gege bi oko ati iyawo, won a si da ojo igbeyawo.
IGBEYAWO
Bi idile oko tabi idile iyawo ba se lowo to, bee naa ni ayeye igbeyawo won yoo se larinrin to, yato si pe to ba je won ko gbodo se igbeyawo alariwo gege bi iwadii ti won base.
Gege bi asa igbeyawo ni ile Yoruba owo irole ni iyawo maa n lo ile oko re nitori ero ni won ka asiko yii si. Ki o to di asiko yii ni yoo ma a kaakiri lati gba adura lenu awon obi ati ebi re ti won yoo si maa fun ni amoran lorisirisi. Ni ale ojo keta, o di dandan ki oko sunmo iyawo re lati mo boya o ti mo okunrin ri tele. Abuku gba a ni o maa n je fun iyawo ati awon ebi re to ba ti mo okunrin tele. Sugbon ti ko ba ti i mo okunrin kan tele, orire n la ni fun won.
IGBELEWON
- Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
- Se alaye ise alarena
- Kini ijohen tabi isihun tumo si
- Kini iyato laarin itoro ati idana
AKATILEWA
Imo,Ede,Asa Ati Litireso. Adewoyin S.Y. o .i 286-294.
ISE ASETILEWA
- Igbese akoko ninu igbeyawo ni
(a) alarina (b) ifa iyawo (d) ifojusode
- Ara eru idana niyi, afi
(a) aso (b) ate (d) owo.
- Bi oko ba moju aya tan,—- a yeba.
(a) iya oko (b) baba oko (d) alarina
4 ——- ni a maa n san fun owo isihun
(a) poun kan sile kan (b) poun meji sile meji (d) poun meji sile kan.
- Ewi atenudenu ti a n lo fun ayeye igbeyawo ni
(a) rara (b) ekun iyawo (d) orin iyawo
APA KEJI
- Kin ni igbeyawo
- Daruko awon igbese igbeyawo ti o wa.
- Ko aroko lori egbon re.
OSE KARUN-UN
ORI-ORO-;Aayan Ogbufo
AKOONU
Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran
Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.
Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ode miiran.
A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nii.
A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se been yoo so itumo oro ti a fe tu nu.
Akaye ati akatunka ayoka se Pataki ki o to le se ogbufo to peye. Rii pe o lo akoto to muna doko eyi ni yoo je ki o see ka.
Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.
O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.
Eyi ni aayan ogbufo sise laarin awon akekoo ninu kilaasi.
Please bury the harchet
Jowo fiye denu
He who fight and run away, leaves to fight the other day
Agbo to feyinrin, agbara lo lo mu wa.
Time and tide wait for no man
Akoko ati igba ko duro de enikan.
Paddle your own canoe
Gbo tire
They may have been drumming
Won ti le maa lu ilu
He came in reluctantly
O wole tikotiko
Tumo ayoka yii si ede Yoruba
Birds take a great deal of trouble to give their young a good start in life. The female bird lays hard-shelled egg from which the young animal gradually develop with supplies of good good and air. In most cases the eggs are laid in a carefully prepared nest which is hidden from enemies or out of their reach.
Awon eye a maa se opo wahala lati fun awon omo won ni ibere rere ni aye. Iya eye a maa ye eyin eleepo lile.
Ninu eyin yii ni awon omo eye yo ti maa ri ounje ati afefe ti yo mu won maa gbora diedie. Ni opolopo igba inu ite ti won farablae ko ti o sa pamo fun ota ni won maa n ye won si.
ASA
ORISIIRISII IGBEYAWO TI O WA
Orisiirisii igbeyawo ni o wa ni ile Yoruba ni aye atijo, awon naa ni
Igbeyawo nisu loka
Jiji iyawo gbe
Pade mi ni diiko
Gbigbe ese le iyawo
Igbeyawo nisu loka-: eyi ni igbeyawo ti a se ni ona ti o to,ati eyi ti o ye.Eyi ni igbeyawo ti won tele gbogbo eto, ilana ati igbese igbeyawo ti o ye,ti idile mejeeji si fi owo sii.
Jiji iyawo gbe-; eyi naa je orisii kan ti ko tona ,eyi ni jiji iyawo ti fe fe gbe ni ona oja,lona odo, won a si gbe e lo si ile, o di iyawo niyen.
Pade mi ni idiko-; eyi je ona ti omobinrin ti ko fi ara bale n gba lo si ile oko,eyi nip e adehun ti maa wa laarin omobinrin yii ati oko afesona re lati salo, won yoo si fi ipade si idi oko nibi ti won yoo gba salo
Gbigbe ese le iyawo-; eyi ni nigba ti oba ba gbe ese le iyawo asesegbe ti o sese n lo si ile oko,ti yoo si di iyawo oba lesekese ti oko iyawo o si gbodo so nnkankan,boya iyawo naa fe tabi o ko o di iyawo oba ni yen, ti ohunkohun ko si ni tie yin re wa.
IWE AKATILEWA
ISE ASETILEWA
1.——— ni eni ti o n se ise ogbufo
(a) Aayan (b) Ologbifo (d) ogbufo.
- This is a societal problem.tumo si
(a) Isoro egbe niyi (b) isoro awujo niyi (d) isoro ilu niyi
3.________ nikan ni o le gbe ese le iyawo
(a) Oba (b) Ijoye (d) Ogboni.
- Igbeyawo ti o tele eto ati ilana igbeyawo ile Yoruba ni———
(a) igbeyawo nisu loka (b) pade mi nidiiko (d) iyawo gbigbe ese le.
- Igbeyawo ——- nikan lo le duro gba ase lenu obi.
(a) pade mi nidiiko (b) Iyawo ti a gbese le (d) Igbeyawo nisu loka.
APA KEJI
1.Salaye awon igbeyawo wonyi
- igbeyawo nisu loka
- pade mi nidiiko
iii. iyawo ti a gbese le.
- Salaye ohun merin ti a gbodo mo ki a to se aayan ogbufo.
OSE KEFA
ORI-ORO-;SISE AYOKA EDE GEESI SI EDE YORUBA
ASA
ORI-ORO-; IGBEYAWO ODE-ONI
- IGBEYAWO SOOSI
- IGBEYAWO MOSOLASI
- IGBEYAWO KOOTU
Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisi ona ni a n gba gbe iyawo. A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi. Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.
Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko ko gbe enu re dake laelae. Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po. Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.
Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won ni “me” ni Olorun wi, ti agbara okunrin naa ba ti kaa. Awon musulumi a maa fi omo se saara lae je pe onitohun fi okan sii tele eyi nipe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele. Eyi ni won maa n pe ni iyawo saara.
Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni. Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.
Awon loko laya miiran a maa se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase ijoba, won a si fi bee gba oruka arede. Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo, igbeyawo kootu ni a n pe e.
Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon odo iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko. Ko tile sohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.
IGBELEWON
- Salaye igbeyawo soosi
- Ki ni ohun ti o le so lori igbeyawo kootu
- Se afiwe igbeyawo abinibi pelu igbeyawo ode oni
- Awon ona wo ni awon musulumi n gba se igbeyawo
IWE AKATILEWA
- Eko ede Yoruba titun (J S S ) iwe keji oju iwe 35-54 lati owo Oyebamiji Mustapha.
- Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe114-118 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.
ISE ASETILEWA
- Awon………….. lo n se igbeyawo soosi
(a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
- Awon ________________lo n se igbeyawo Mosolasi
(a) musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
- Awon _____________________lo maa fi omo se saara
(a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi
- kEJI
1 Salaye awon igbeyawo wonyi
– igbeyawo soosi
– igbeyawo mosalasi
– igbeyawo kootu.
OSE KEJE
ORI-ORO-;ONKA YORUBA
OOKAN DE EGBAA
ONA MEJI PATAKI NI ONKA YORUBA PIN SIN
ONKAYE (ON – KA – IYE)
ONKAPO (ON – KA – IPO)
‘m’ ni a fi n da pupo ninu awon onkaye Yoruba mo nigba ti a n fi (i) mo onkapo
Apeere
ONKAYE ONKAPO
Meni (mu eni) = 1 Ikini (iko eni) = 1st
Meji (mu eji) = 2 Ikeji (iko eji) = 2nd
Meta (mu eta) = 3 Iketa (iko eta) = 3rd
Merin (mu erin) = 4 Ikerin (iko erin) = 4th
Marun-un (mu aarun = 5 Ikarun-un (iko arun) = 5th
Mefa (mu efa) = 6 Ikefa (iko efa) = 6th
Meje (mu eje) = 7 Ikeje (iko eje) = 7th
Mejo (mu ejo) = 8 Ikejo (iko ejo) = 8th
Mesan-an (mu esan) = 9 Ikesan (iko esan) = 9th
Mewaa (mu ewa) = 10 Ikewaa (iko ewa) = 10th
Mokanla (mu okan-le-ewa) 11 Ikokanla (Iko-okan-le-ewa) 11th
Mejila (Mu-eji-le-ewa) 12 Ikejila (iko-eji-le-ewa)= 12th
Metala (mu-eta-le-ewa) 13 Iketala (iko-eta-le-ewa) 13th
Merinla (mu-erin-le-ewa) 14 Ikerinla (iko-erin-le-ewa) 14th
Ki ato le mo itumo awon onka marun-un to tele merinla (14) a nilati wo iwaju ki a ri ogun (20) ki a tun woe yin ki a wo iye ti okookan awon onka wonyi (15-19) fi din si ogun bayii.
Meedogun (mu arun-din-ni-ogun) 15
Ikeedogun (iko-arun-din-ni-ogun) 15th
Merindinlogun (mu-erin-din-ni-ogun) 16
Ikerindinlogun (iko-erin-din-ni-ogun) 16th
Metadinlogun (mu-eta-din-ni-ogun) 17
Iketadinlogun (iko-eta-din-ni-ogun) 17th
Mejidinlogun (mu-eji-din-ni-ogun) 18
Ikejidinlogun (iko-eji-din-ni-ogun) 18th
Mokandinlogun (mu-okan-din-ni-ogun) 19
Ikokandinlogun (iko-okan-din-ni-ogun) 19th
Ogun (20) da duro funra re, ko si tumo si
eewa meji, o je akanda onka, oun naa ni a mo si okoo
mokanlelogun (mu-okan-le-ni-ogun) 21
Mejilelogun (mu-eji-le-ni-ogun) 22
Metalelogun (mu-eta-le-ni-ogun) 23
Merinlelogun (mu-erin-le-ni-ogun) 24
A o wo iwaju ri ogbon, ki atun woe yin wo iye ti okookan awon onka yii fi din.
Meedogbon (Mu-arun-din-ni-ogbon) 25
Merindinlogbon (mu-erin-din-ni-ogbon) 26
Metadinlogbon (mu-eta-din-ni-ogbon) 27
Mejidinlogbon (mu-eji-din-ni-ogbon) 28
Mokandinlogbon (mu-ookan-din-ni-ogbon) 29
Ogbon 30
Bi a o se kaa niyi titi de ori
Ogoji (ogun eji = 20 x 2 = 40
Ogota eta (ogun eta) = 20 x 3 = 60
Ogorin (ogun erin) = 20 x 4 = 80
Ogorun-un (ogun arun) 20 x 5 = 100
Ogofa (ogun efa) = 20 x 6 = 120
Ogoje (ogun eje) = 20 x 7 = 140
Ogojo (ogun ejo) = 20 x 8 = 160
Ogosan (ogun esan) = 20 x 9 = 180
Ogowaa (ogun ewa) = 20 x 10 = 200
Ogowaa yii tun ni akanda oruko kan Pataki ninu ede Yoruba
Ilo aadin-(ewa din)
Aadotan (ewa-din-ni-ota) = (20 x 3) – 10 = 50
Aadorin (ewa-din-ni-orin) = (20 x 4) -10 = 70
Aadorun-un (ewa din ni orun) (20 x 5) – 10 = 90
Aadofa (ewa-din-ni-ofa) = (20 x 6) – 10 = 110
Aadoje (ewa-din-ni-oje) = (20 x 7) – 10 = 130
Aadojo (ewa-din-ni-ojo) = (20 x 8) – 10 = 150
Aadosan (ewa-din-ni-osan) = (20 x 9) – 10 = 170
Aadowaa (ewa-din-ni-owa) = (20 x 10) – 10 = 190
Ogowaa (ogun mewaa) = (20 x 10) = 200
Ti a ba lo isiro ilopo ogun, onka naa lo bayii
220 (200 + 20) = Okoolenigba
230 (200 + 30) = Ogbonlenigba
240 (200 + 40) = Ojilenigba
260 (200 + 60) = Otalenigba
280 (200 + 80) = Orinlenigba
300 (200 + 100) = Oodunrun
320 (300 + 20) = Okoolelodunrun
340 (300 + 40) = Ojileloodunrun
360 (300 + 60) = Otaleloodunrun
380 (300 + 80) = Orinleloodunrun
400 (300 + 100) = Irinwo
420 (400 + 20) = Okoolenirinwo
440 (400 + 40) = Ojilenirinwo
460 (400 + 60) = Otalenirinwo
500 (400 + 100) = Eedegbeta (200 x 30) – 100
600 (400 + 200) = Egbeta (200 x 3) = 600
700 (400 + 300) = Eedegberin (200 x 4) – 100
800 (200 x 4) = Egberin
900 (200 x 5) – 100 = Eedegberun
1000 (200 x 5) = Egberun
1200 (200 x 6) (Igba mefa) = Egbefa
1400 (200 x 7) (Igba meje = Egbeje
1600 (200 x 8 (igba mejo = Egbejo
1800 (200 x 9) (igba mesan-an) egbesan
2000 (200 x 10) Igba mewaa) Egbawa (egbaa)
ASA
ASA OYUN NINI
AKOONU
ITOJU OYUN ATI IBIMO
IGBAGBO YORUBA NIPA AGAN, OMOBIBI ATI ABIKU
- ITOJU OYUN
- IBIMO
Gbogbo wa la mo bi omo ti se pataki to laarin awa Yoruba. Ko si bi owo, ola ati ola eniyan ti le po to ti ko ba bimo aye asan ni oluwa re wa. Igbagbo yii fese mule laarin awon Yoruba to bee to fi je pe ko si ohun ti won ko le fi wa omo. Nitori naa asa oyun nini ki i se nnkan ti won n fi owo yepere mu rara, obinrin ti ko ba le loyun ni won n pe ni agan nile Yoruba. Ti okunrin ba gbe iyawo ti iyawo yii ko tete loyun tabi ti omo ba dagba lowo obinrin ti oyun ko ba tetede wonu de fun okunrin naa niyen, ki a ni yoo ti to awon agba lo fun aajo ki iyawo le tete loyun.
Orisirisi itoju ni a maa n fun awon alaboyun ni ile Yoruba, lati igba ti iyawo ba ti so fun oko re pe oun kori nnkan osu oun mo ni yoo ti maa fi inu ro ona ti yoo gba, ti a o gbohun omo ti a o si tun gbo ti iya ti oyun na ko si ni baje. Lara ona ti a n gba se itoju oyun ni Oyun dide eyi saba maa n waye ti oyun ba n baje lara obinrin, ti iru obinrin yii ba loyun miran won maa n de e ki oyun naa ma ba tun baje.
Ohun miran to tun maa n je ki won de oyun ni pe laye atijo won ki i fe se oyun fun obinrin nitori ese ni won kaa si dipo bee se ni won a de e ki oyun naa ma ba soke. Looto ni won n lo orisirisi oogun, sugbon a kii saba lo oogun fun aboyun laarin osu kini si eketa, to ba pe osu meta orisirisi oogun ni won le lo. Oogun ki omo le maa gbera daadaa ninu, ki ara obinrin le fuye, eyi ti yoo maa lo ti ese re ba n wu ati eyi ti yoo fi bi were (oogun abiwere).
Omiran ninu awon oogun wonyi yoo je nnkan bi agbo fun mimu tabi nnkan wiwe, omiran si le je lila. Gbogbo agbo tabi ogun yii lo ni asiko ti a gbodo lo won. Omiran ni osu keta, omiran ni osu karun-un tabi osu keje.
Ti oyun ba ti bere sii mu obinrin daadaa, won a ni ko kunle ko bere si ni gbin kikan-kikan. Agba obinrin kan yoo duro leyin re. ekeji niwaju lati maa so igba ti omo ba fe yo ori sita, ni kete ti won ba ti ri ami pe omo n bo ni won yoo ti te aso sile ti won yoo si fi owo pade re ti o
ba n bo. Nigba miran isoro le wa sugbon gbogbo itu ti won ba mo ni won yoo pa tan.
OMO BIBI/ OJO IKUNLE
Ori ikunle ni obinrin ti maa n bimo.Bi o ba to asiko atibimo. Aboyun yoo ri eje ati omi die lara omira re ami pe o to akoko lati bimo niyen. won a ni ki o maa gbin leralera. Agba obinrin yoo duro leyin re okan niwaju lati ma so igba ti omo maa yo ori sita ni igba miira isoro le wa sugbon gbogbo itu ti agbebi ba le pa ni yoo pa.
Eewo/Oro ile: Oro ile ni nnkan ti obinrin ti o bimo ko gbodo se fun anfaani ara re ati nitori omo to sese bi . Oro idile ibikan yato si omiiran. Fun apeere:
Ni idile olu oje, obinrin to bimo ko gbodo je iyan tabi amala titi ojo ikomojade. Isu ati ekuru ni yoo maa je. Ni idile onigbeeti, iya ikoko o gbodo je obe to ni iyo tabi ata titi di ojo ikomojade iru eyi ni won n pe ni obe ate. Won maa n gun iyan ati iru pelu epo pupa ni idile olokun esin iru ounje yii ni yoo maa je titi di ojo ikomo. Idile olofa ni won ti maa n je obe ate obe afun ni obinrin to sese bimo yoo maa fi je oka amala igbako kan soso lemeeta lojumo
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ABIKU
Abiku ni awon omo ti won maa n bi ju eekan lo. Iru awon omo bayi maa n ku ti won ba ti n bi won. Igbagbo Yoruba nipe iru awon omo bayi ni egbe lorun. Inu le bi awon obi omo ki won ge ika ese tabi ti owo omo naa nigba ti o ba su won. Igbagbo won ni wi pe iru awon omo bee ko ni ya odo won mo ti o ba tun ile aye wa. Abuku ni iru eyi je fun won tori pe awon egbe re o ni gba mo. Orisirisi oruko ni o fi han pe abiku n be. Fun apeere kokumo, Fidimaye,Malomo, Kukoyi, Maku, Kosoko,Rotimi, Durosinmi Kosoko.
IGBELEWON
- Salaye orisii ona ti awon Yoruba n gba se itoju oyun ni aye atijo.
LITIRESO
ORI-ORO-;ITAN OLORO GEEREGEGE BI ORISUN ITAN ATI ASA YORUBA;ASA BI YORUBA SE N SIN OKU SI INU ILE.
Litireso atenudenu-; je awon ewi ati itan ti a jogun ba lodo awon baba-nla wa, o je atenudenu nitori pe won ko si ni akosile nitori pea won baba-nla wa ko mo-on-ko bee ni won ko mo-on-ka.
Awon ewi atenudenu wonyi lo je orison fun opolopo itan ati asa Yoruba, aria won itan atenudenu to n so isedale ati idi abajo asa ile wa lati inu odu ifa ,lati inu itan oniruuru ogunto ti ja koja ni ile Yoruba ati lati inu itan aroso adayeba.
Ni bayii, a fe wo idi ti awon Yoruba fi n sin oku
Ni aye atijo, awon Yoruba ki i.oku to ba ku.Won maa n gbe oku sonu sinu igbo ni to ba wa lebaa ilu ni. Bi oku ba ku ni ibikibi laarin ilu,inu igbo ni won ni won n ju u si tabi ki won so o sinu iho igi ninu igbo.
Nigba ti a n wi yii, okunrin kan wa ti oruko re n je Orunmila,oruko iyawo re ni Idi. Irepo to dan moran ko si laarin won,nitori naa, Idi fe ko oko re sile sugbon Orunmila ko fi aaye sile fun-un,nitori gbogbo ibi ti o n lo,oun pelu Idi ni. Bi ija ba sele laarin won ,iyawo yoo maa hale mo oko re pe oun maa ku si i lorun,oko re naa asi so fun-un pe ti o ba ku,oun maa gbe oku re so sinu igbo ni.
Se Idi ti n wa orisiirisii ona lati ko Orunmila sile,nigba ti o di ojo kan, ero kan wa si i lokan pe bi oun ba dibon pe oun ku,ti won si gbe oun sinu igbo,ki okunrin miiran ti oun fe few a gbe oun kuro nibe leyin ti awon ti to gbe sonu ba ti pada si aarin ilu,bayii ni o ba okunrin naa di awo po.
Kop e ko jinna ni ija nla kan sele laarin Orunmila ati Idi. Were ,Idi ti subu lule to si se bi to ku. Leyin eyi ni awon ara ile ati ara adugbo gbiyanju lati ji i ,ti ko si se e se ,ni won bag be oku re sonu sinu igbo,okunrin ti o fe ti lo fi ara re pamo sinu igbo naa, ki oba le mo ogangan ibi ti won yoo ju oku re si.
Bi won ti gbe oku re sonu tan,ti awon togbe e wa pada si le ni okunrin ti Idi fe fe ba lo ba a nibi ti won ju oku re si,o tu gbogbo ohun ti won fi di i kuro lara re. awon mejeeji si lo si Ejigbo lati maa gbe gege bi oko ati aya: Se won ko tun le pada wo ilu ti won n gbe tele nitori pe awon eeyan yoo tun maa ri i , bee ko si eni to tun le maa ba oku gbele .
Nigba ti won de Ejigbo,oko titun ti Idi fe bere si ni da oko ila ati ikan.Iyawo re a si maa gbe e lo si oja Ejigbo lo ta. Ni gba ti o di ojo kan ,okunrin kan lati lati ilu Orunmila wa si oja Ejigbo lati ko ila, odo Idi taara ni o lo laimo pe oun ni, o bere si ni wo idi laimo pe oun ni,bi Idi ti n fi oju pamo bee ni okunrin naa tubo n ww o si I,nigba ti ara Idi ko gba a mo ,lo ba fi ibinu soro pe
Bo o kola, kola
Bo o gbeni, o gbeni
Ewo laboro woju oloja,loja Ejigbo
A i i wo o
Oju oku lo n wo
Nigba naa ni okunrin naa mo daju pe Idi ni oun ri, nigba ti o de ilu Orunmila o ro gbogbo ohun ti o ri fun Orunmila,Orunmila ranse lo si Ejigbo lati lo mu Idi wale; sugbon ki won to de ibe Idi ati oko re ti kuro nibe.Lati igba naa lo ti di asa pe ki awon eniyan maasin eni ti o ba ku dipo ki won maa gbe e sonu sinu igbo.
Idi abajo keji nipe ko si eni to ri oku to ti ku ni ojukoju
IGBELEWON
- Ona meloo ni onka Yoruba pin si
- Kin ni a fi n da okookan mo. Salaye re pelu apeere
ISE ASETILEWA
- Iro ______________________ni a fi n da pupo ninu awon onkaye mo
(a) n (b) m (d) t
- Iro __________________________ni a fi n da onkapo mo
(a) I (b) m (d) n
- Orinlenirinwo je ____________________________________
(a) 440 (b) 480 (d) 490
- Egbaa je ___________________________
(a) 2000 (b) 200 (d) 20,000
- 14,000 je (a) ogoje (b) egbaaje (d) irinwo
APA KEJI
- Ona meloo ni onka Yoruba pin si?
- Kin ni a fi n da won mo.
- Daruko orisii ona ti awon Yoruba n gba lati se itoju oyun laye atijo.
- salaye lekun-un-rere,idi ti awon Yoruba fi n sin oku.
OSE KESAN-AN
Ori-oro-; Aroko oniroyin
Akoonu:
Aroko oniroyin:- je mo iroyin sise tabi itan isle ti o ti koja seyin ti o si se oju eni ti a n royin re ni sise-n-tele ninu aroko oniroyin fun elomiran ti ko si nibe. A rii wi pe o fi ara pe aroko asapejuwe.
Ki a to le se iroyin yori, a gbodo je eni ti o ni ife si gbigbo tabi kika iwe itan kekere.
Eyi ni apeere ori-or, to je mo aroko oniroyin.
Iroyin ipade maje – o – baje kan ti mo lo.
Ayeye odun eyo ni ilu eko
Ojo buruku, esu gbomi mu.
Ipolongo eto idibo ti o koja
Bi mo se lo isinmi mi ti o koja
Isomoloruko kan ti won se ni odede wa laipe yii.
Igbelewon.
Ko aroko lori
Isomoloruko kan ti won se ni adugbo wa laipe yi.
ASA
ORI-ORO-;orisiirisii oruko ti a le so omo ni ile Yoruba
Akoonu
Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.
Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.
- Oruko amutorunwa
- Oruko abiku
iii. Oruko Inagije
- Oruko abiso
Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii.
Ap
Oruko amutorunwa:-
Ige Omo ti o mu ese waye
Aina Omobinrin ti o gbe ibi korun.
Ojo Omokunrin ti o gbe ibi korun.
Oke Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa
n ta si ara apo naa, ki o to le tu.
Oke Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.
Dada Omo ti irun ori re ta koko.
Ilori Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun
Oni Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi
Babarinsa Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.
Abiona
Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.
Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap
Oruko Itumo
Durojaye – Ki o duro ni ile aye je igbadun
Rotimi – Duro ti mi, ma se fi mi sile.
Malomo – Duro si aye, ma pada si orun mo
Kosoko – Ko si oko ti a o fi sin oku re mo
Kasimaawoo – Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.
Bamitale – Duro ti mi di ojo ale
Aja – Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.
Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.
Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.
Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise
Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.
Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.
Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.
Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.
Ipo Oruko abiso
Oba – A Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.
Eleegun Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi
Jagunjagun Akintola, Akinkunmi, Akindele
Onisona Onajide, Olonade
Elesin Ifa Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde
Onisango Sangobunmi, Sangodele
Orisa Oko/Idobatala Efunjoke, Opakunle, Soyinka.
Orisa Ogun Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.
Oruko to n tokasi ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.
Oruko Itumo
Ekundayo Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.
Olabode Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.
Tokunbo Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile okeere ti won gbe wa ile.
Igbelewon
- Kin ni Oruko?
- Daruko orisii oruko ti o wa.
IWE AKATILEWA
Imo,Ede ASA Ati Litireso.Adewoyin S.Y o.i 298-301.
ISE ASETILEWA
1.Ojo ——- ni won maa n fun omokunrin ni oruko laye atijo
2.Omo ti a bi ti o mu ese waye ni
(a)Amu-ese-wa (b) Ige (d) Dada
3.——- ni o n bi iku ati arun danu
(a) obi (b) ata (d) abikudanu/
- Efunyela je oruko ti o je mo orisa ———–
(a) Esu (b) Orisa oko (d) Ogun
- Omo ti o maa n daku ti won ba n ro o ni ounje ni ibule ni ———
(a) Oke (b) Oke (d) Abiona.
APA KEJI
- Daruko orisii oruko marun-un,pelu apeere merinmerin fun ikookan.
- Ko aroko lori odun keresimesi ti o koja.
OSE KEWAA
ORI-ORO-;ISORI ORO-ORUKO
AKOONU
– oriki
– orisiirisii oro oruko.
– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.
– lilo oro oruko ninu gbolohun.
Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa,abo tabi eyan ninu gbolohun.AP.
Baba ko ebe.
Tolu fo aso.
Mama se isu ewura.
EYA ORO ORUKO.
- ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan,eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan.Ap
-Rotimi
– Dele
-Ahmed
– Dokita
– Iyalaje…abbl
- ORO-ORUKO ALAISEEYAN: -Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP.okuta,iwe, ewure,omi,iyanrin,bata abbl.
- Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
- Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi.ap iwe,ile,bata,ewe,igi,abbl.
- Oro-oruko le je ohun aridimu : – Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan.apewa,eja,isu,tabili,sokoto,aga,ewedu,abbl.
- Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won.Ap ibo lo n lo? Osodi,Meka,Soosi.
- Oro-oruko le je ohun afoyemo : – Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nip aero opolo.Ap ogbon,ilera,ero,ife,alaafia,igbadun,wahala,imo.
- Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile,ilu,eniyan,iwe,tatapupu.
- Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin,epo,omi,afefe,gaari,irun.
- Oro-oruko le je oruko igba : – Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han.Ap Aaro,ana,odun,irole,oni,ola,ijeta.
ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.
Ona meta Pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun,o le sise:
i.Oluwa,
- abo
iii. eyan.
OLUWA;ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.ap Baba ko ebe.
Bola fo aso.
ABO;ni eni tabi ohun ti a se nnkan si,ap
Mama se obe
Bolu ko leta.
EYAN;ni o maa n se afikun itunmo fun oro-orukoap
Mama se obe eja yiyan.
Bola se isu ewura.
Ona miran ti a tun le gba da oro oruko mo ni pe
Oro-oruko maa n gba oro aropo bii eyan,ap
‘oro yin ni a sese so tan yii.’
‘ile re ni mo n lo.’
Oro-oruko le se e lo fun sise akiyesi alatenumo ti a ba gbe saaju wunren ‘ni’ap
‘iwe ni mo ra.’
Rira ni mo ra iwe yii.
ASA
IPOLOWO OJA
AKOONU
Ipolowo oja-;je ona ti a n gba lati ke gbajare oja ti a n ta si etigbo awon eniyan lati le ba won ra a.
Ona meji ni a n gba se ipolowo oja,awon naa ni
i.ipolowo oja abinibi
- ipolowo oja ode-oni.
Ipolowo oja abinibi-;je ona ti a n gba polowo oja ni aye atijo,awon naa ni;ipate,ikiri.
Ipolowo oja ode-oni-; je ona ti a n gba polowo oja ni ode-oni,lati le je ki oja ti a n ta ya,apeere ipolowo oja ti ode-oni ni; ipolowo lori telifisan,redio,iwe iroyin,fidio ati inu magasinni.
IWULO/PATAKI IPOLOWO OJA
Gege bi a se mo pe ipolowo ni agunmu owo,opolopo anfaani ni o wa ninu ipolowo oja ti anfaani re ko si se e fi owo ro seyin.
- Ipolowo oja maa n je ki oja ta.
- O maa n je ki awon eeyan mo nipa oja titun to sese n jade.
iii. O maa n je ki ohun ti a fe ra wa ni arowoto wa.
.iv.O maa n je ki awon eeyan mo ibi ti won ti le ri oja ti won fe ra.
ORISII OJA TI A N POLOWO
ONA TI A N GBA SE IPOLOWO
O fere je pe gbogbo oja ti a ni ni a maa n polowo,eyi ni die lara awon oja ti a maa n polowo.
OJA IPOLOWO
Efo E refo e sebe.
Gaari gaari,olooyo,ayangbe gaari o
Ata E rata e sebe o
Iresi ofe niresi eran lowo
Epo E repo e sebe.
Iru E raru e sebe.
Orisii ogbon ni awon oloja maa n da lati polowo oja won,ki awon eeyan le ba won ra a,ara awon ogbon naa ni
- Itowo-;Eyi ni pe won a fun onibara ni die ninu oja ti won n ta pe ki o to o wo bi o se ri lenu ap gaari.
- Isiwo-; Eyi ni pe won a ti ni kekere kan ninu oja yen ti won a maa fi han onibara lati wo o bi o se ri ap eko.
- Awin-; Awon oloja maa n ta oja awin fun awon onibarawon lati fi fa oju won mora.
Orisiirisii ede aponle ni awon oloja maa n lo lati fa oju awon onibara won mora,fun apeere “e woju obe e muyan.
Igbelewon
- Daruko awon oja ti a maa n polowo.
- se ipolowo merin ninu won.
- Daruko isori oro-oruko marun-un pelu apeere metameta fun ikookan..
Iwe Akatilewa
Iwe imodotun Yoruba fun olodun kin-in-ni o.i 93, 98.
ISE ASETILEWA
1.———- ni agunmu owo
(a) itowo (b) ipolowo (d) ikiri
- ——- je okan lara ogbon ti awon oloja maa n lolati ta oja won.
(a) ipate (b) itowo (d) eebu.
3.Okan lara ona ti a n gba se ipolowo oja lode oni ni
(a) ikiri (b) itowo (d) redio
- Mama se eja tutu. Eyan ti o wa ninu gbolohun yii ni
(a)mama (b) eja (d) tutu.
- Orisii ise ——- ni oro-oruko maa n se ninu gbolohun.
(a) kan (b) meji (d) meta.
APA KEJI
1,Kin ni ipolowo oja?
b.Daruko orisii oja marun-un ti a maa n polowo,ki o si polowo won.
- Salaye ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun,pelu apeere metameta fun ikookan.