Gbolohun Ede Yoruba nipa fifi oju ihun wo o.

OSE KERIN

EKA ISE:    EDE

AKOLE ISE:    Gbolohun Ede Yoruba nipa fifi oju ihun wo o.

Gbolohun je akojopo oro ti oni oro ise ati ise ti o n je nibikibi ti o ba ti jeyo.

Gbolohun Abode/Eleyo oro-ise

Eyi ni gbolohun ti ko ni ju oro-ise kan lo.

 

Gbolohun Abode kii gun, gbolohun inu re si gbode, je oro ise kikun.

Apeere;

  1. Dosunmu mu gaari
  2. Aduke sun
  3. Olu ra  iwe

 

Ihun gbolohun Abode/Eleyo Oro –Ise 

  1. O le je oro-ise kan Apeere; lo, sun, joko, dide, jade, wole

 

  1. Oro ise kan ati oro apola Apeere;
  1. Aniike sun fonfon 
  2. Alufaa ke tantan
  3. Ile gagogoro

 

  1. d) Oluwa, oro ise ati abo Apeere
  1. Igejeebe
  2. Ibikunleponomi
  3. Olukoraoko

 

  1. e) O le je oluwa, oro ise kan, abo ati apola atokun. Apeere.
  1. Ainaruiginiona
  2. Ojodailesiodo

 

  1. e) O le je oluwa oro ise kan ati oro atokun. Apeere;
  1. Molosioko
  2. Babawasiibe

 

Gbolohun Alakanpo.

Eyi ni gbolohun ti a fi oro asopo kanpo mora won.

Akanpo gbolohun eleyo oro-ise meji nipa lilo oro asopo ni gbolohun alakanpo.

Awon oro asopo ti a le fi so gbolohun eleyo oro-ise meji po ni wonyi, Ayafi, sugbon, oun, ati, anbosi, amo, nitori, pelu, tabi, koda, boya, yala abbl. Apeere;

  1. Olu ke sugbon n ko gbo.
  2. Atanda je isu amo ko yo
  3. Tunde yoo ra aso tabi ki o ra iwe
  4. Mo san owo nitori mo fe ka we abbl.

 

EKA ISE:    ASA

AKOLE ISE;    SISE AKANSE ISE AWUJO YORUBA (PROJECT)

Awon Ise awujo Yoruba je ise abinibi/ise isenbaye.

 

Ise isebaye ni ise iran ti ajogun lati owo awon babanla wa.

 

Iran Yoruba lodi si iwa imele idi niyi ti won fi mu ise sise ni Pataki.

 

AWON ISE AKANSE ILE YORUBA

  1. Eni hihun
  2. Ikoko mimu
  3. Irin riro
  4. Aro dida
  5. Igba finfin abbl.

Alaye lori die lara ise akanse ile Yoruba.

 

  1. ISE IKOKO MIMO:    ise ikoko mimo wopo ni agbegbe Ilorin, oyo, ipetunmodun, ise obinrin ni ise ikoko mimo, awon ohun elo ikoko mimo ni wonyi; Amo, omi, odo, isaasun obe, ekusu agbado.

 

IGBESE MIMO IKOKO.

Gigun amo ninu odo pelu omi die, yoo mu dada.A oo gbe ikoko miiran/isaasun lati fi se ipinle bee ni a oo da oju ikoko naa de ile nipa mimo amo sii ni idi yika lati se odiwon ohun ti a fe mo.

 

Ti amo yii ba gbe die, a oo yo ikoko ti a fi se ipinle kuro, a oo si fi ekusu gbado se ona si ikoko ti a mo lara , a oo si sa sinu oorun.

 

Leyin ti o ba ti gbe tan, a o fi ina sun ikoko amo naa jinna daada.

  • ISE AGBEDE

Okan lara ise ona ni ise yii je. Awon alagbede ni won n ro ohun elo bii, ada, oko, obe, 

Irinse ise Agbede/irin riro ni wonyi

Owu Gbinrin Ikoko omi abbl
Omo owu Ewiri
Iponrin Emu

  • ISE ARO DIDA

Kaakiri ile Yoruba ni ise aro-dida ti wopo. Ise obinrin ti o gba nini imo kikun nipa aro pipo, imo nipa awo ati batani ni ise aro-dida je.

 

Ohun elo-ise ni:  ikoko nla,omi, aro, orogun gigun/opa, paafa, aso teru, abbl.  

Opa ti a fi n ro aro ninu ikoko aro ni a n pe ni “opa aro”.ori paafa” ni a n yo aso ti a yo ni aro si.

 

IGBESE ARO – DIDA

A oo fi aso teeru sinu aro fun iseju bi mewaa leyin naa, a oo ju aso naa si ori paafa, yoo lo bii iseju mewa pelu lori paafa.

 

Leyin iseju mewaa naa, a oo tun so pada sinu aro, eyi ni a oo se titi aso naa yoo fi dudu bi a se fe. Ni gba ti o ba ti mu abajade ti a fe jade,  a oo yo kuro ninu aro lati sa.

 

EKA ISE:    LITIRESO

AKOLE ISE:    LITIRESO ALOHUN TO JE MO AYEYE.

Litireso je ona ti Yoruba n gba lati fi ero inu won han lori ohun ti a je koko tabi iriri aye won.

 

ISORI LITIRESO

  • Litireso alohun
  • Litireso apileko

Litireso alohun ni litiresso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon babanla wa.

Litireso apileko ni litireso ti a se akosile re nigba ti imo moo ko – moo ka de si ile wa.

 

Litireso alohun ajemayeye

Eyi ni awon litireso ti a n lo lati gbe asa laruge nibi ayeye gbogbo.

Awon ewi alohun ajemayeye niwonyi,

  • Ekun iyawo
  • Dadakuada
  • Bolojo
  • Etiyeri
  • Rara
  • Alamo
  • Oku pipe
  • Efe abbl

 

EKUN IYAWO

Eyi ni ewi ti a maan lo ni ibi ayeye ti omobinrin ti n lo si ile oko.

 

O je ewi ti omobinrin ti o n lo si ile oko maan sin lojo igbeyawo lati je ki a mo pe oun mo riri, itoju ti awon obi se nigba ti oun wa ni ewe.

 

Ewi yii wopo laarin agbegbe bi, iseyin ikirun, Ede, Osogbo, oyo, ogbomoso. Ekun iyawo je ewi ti o nko wondia leko lati pa ara re mo titi di ojo igbeyawo.

 

Apeere ekun iyawo sisun

                Iya mo n lo

                Mo wa gbare temi n to maa lo

                E ba sure ki n lowo lowo

                E ba sure ki n sowo, n jere

                E ba sure ki n bimo lemo

                E ba sure ki n ma kelenini loode oko

                Ire loni, ori mi a fi re

                Hi hi hihin  (ekun)

 

ETIYERI

Etiyeri je ere awon odo okunrin ni gbegbe oyo. Awon ohun elo orin etiyeri ni, Agogo, ilu sakara, sekere.

 

Etiyeri maa n gbe ago/eku bori bi egungun sugbon kii bo gbogbo ara re tan. olori ti o gbe ago wo ni yoo maa le orin ti awon yooku yoo si maa gbe.

 

Oro awada, eebu, yeye, apara, po ninu orin etiyeri bee ni oro bi epe bi epe ni won fi n se ihure won 

Apeere

Lile:    Mo setan

    Eyin menugun

    Mo setan ti n o rode

    Kikona ko ma ko mi lona o

Egbe:        Ha ha ha, mo se tan

        Eyin menugun

        Mo setan ti n o rode

        Kikona ko ma ko mi lona o

Lile:        mo setan

        Eyin menugun

        Mo setan ti n o korin

        Ko gbigba ko ma gba mi lohun o

Egbe:        Mo se tan

        Eyi menugun

        Mo setan ti n o korin

        Kogbigba ko ma gba mi lohun o……

 

DADAKUADA

Ewi yii je adapo ilu ati orin.

Iwulo orin dadakuada

  1. Won fi n ki eniyan
  2. Won fi n panilerin
  3. Won fi n bu eniyan
  4. Won fi n kilo iwa
  5. Won fi n toka aleebu awujo

Orin Dadakuada wopo ni agbegbe Ilorin, awon okunrin ni o saaba maa n se ere yi. Olori yoo ma le orin, enikan yoo si maa soro lori orin naa ki awon elegbe to gbe e.

 

Apeere:    “Ko sohun t’olorun o lee se

        Amo ohun t’olorun le se ti o ni

        Se lopo

        Keeyan o geri maagoro ko ka

        Ibepe ni be   

        Oloun le se e o

        Amo bo ba se e, iru wa o tu bu

        Emi mo pe n o lee j’Alaafin oyo

        Laelae

        Iwo naa o si lee joba ilu Ilorin wa

        Afonja enu dun juyo waa te

        Yan – an – yan”.

Igbelewon :

  • Kin ni gbolohun?
  • Fun gbolohun abode loriki
  • Salaye ihun gbolohun abode
  • Fun ise isembaye loriki
  • Daruko awon ise isembaye ile Yoruba
  • Kin ni litireso?
  • Ko isori litireso ede Yoruba
  • Salaye litireso ajemayeye pelu apeere

Ise asetilewa: ise sise ninu iwe ilewo Yoruba Akayege

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share