IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORISA

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Third  Term

 

Week : Week 2

 

Topic :

 

OSE KEJI

APOLA ORUKO

(Phrases)

Apola ni apa kan gbolohun ti o le je oro tabi akojopo oro. Lara apola inu ede Yoruba ni apola oruko, aopla ise, ati apola aponle.

Apola Oruko (noun phrase): okan ninu apola oro ti a hun po di gbolohun ni apola oruko. Apola Oruko le je:

 

  1. Oro Oruko eyo kan ni ipo oluwa tabi ni ipo abo. Apeere;

Yetunde sun fonfon

Epo wa ni Sapele.

  1. Oro Oruko tabi Akojopo Oro Oruko ti o n sise eyan. Apeere:

Omi kanga maa n lo ni enu.

Ijoba Ibile Somolu ko awon iso wewe.

  • Oro Oruko ati Eyan Alawe Gbolohun: apeere:

Iyabo ti a n soro re ti de.

Ile ti a fi ito mo  iri ni yoo wo.

  1. Aropo Oruko ni ipo oluwa tabi abo ninu gbolohun: apeere:

Mo gba oro naa bee

A ti lo.

Maa ba a wa.

  1. Oro Aropo Afarajoruko nipo Oluwa ninu gbolohun.

Emi ti lo o.

Awa  pelu iwo ki i se egbe.

Iwo ni mo n ki.

IGBELEWON.

Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.S.2 Corpromutt Publishers Nig Lld O. I. 23-24.

 

ASA

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORISA

Opolopo eda lo ro wi pe awon Yoruba ko mo Olorun. Opo lo ro wi pe igba ti awon elesin ajeji ni o fi ye awon Yoruba pe Olorun wa. Eyi ko ri be rara. Awon Yoruba ti mo Olorun ki awon alawo funfun tode. Eyi han ninu oruko orisiirisii ti won fun Olorun bi Olu orun, Eledaa( eni ti o da gbogbo nnkan), Akoda-Aye.

Bee ni, aborisa ni awon Yoruba, ero won ni wi pe elese ni awa eeyan ti Eledumare si je eni mimo. Eni kukuru a maa se egbe eniyan gigun bi? Eyi ni o fa ti won fi gbe awon orisa kale gege bi agbode gba laarin won ati Olorun. Awon orisa wonyi ni won maa n ran lo ba Olorun. Won ki i ku giri lo ba Olodumare. Nitori naa igbagbo awon Yoruba lori awon orisa wonyi ko kere. Apeere awon orisa naa ni Obatala, Sango, Oya, Ogun, Osun, Moremi, Esu/Elegbara, Egungun, Orisa Oko, Oro, Gelede abbl.

IGBELEWON

Se alaye perete lori igbagbo awon Yoruba nipa orisa.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
  2. Se alaye perete lori igbagbo awon Yoruba nipa orisa.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Ko esin abalye/ibile mejo sile.
  2. Ko ewi alohun esin abalaye ti o ko sile.

IWE AKATILEWA

Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun oju iwe 198-204 University Press

ISE ASETLEWA

  1. ….. ni akojopo oro ti ki i ni itumo ninu gbolohun ni (a) apola (b) oro ise (d) akojopo.
  2.  Apola maa n sise ……. abo ati eyan? (a) oluwa (b) oro oruko (d) oro ise.
  3.  Ewo ni ki i se ara won? (a) ekun iyawo (b) iyere-ifa (d) Esu-pipe.
  4. Agbodegba laarin eniyan ati Olodumare ni (a) Orisa (b) Esu (d) Orunmila.
  5. Oriki Ogun saaba maa n jeyo ninu……………(a) sango pipe (b) ijala (d) Iyere

APA KEJI

  1. Ko apeere apola oruko marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
  2. ko ewi alohun esin abalaye meji sile

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share