JSS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
ALPHA TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN JSS3
YORUBA LANGUAGE
OSE | AKORI EKO |
1 | EDE – Atunyewo fonoloji Ede Yoruba iparoje ati isunki
ASA – Isinku ni ile Yoruba LITIRESO – Awon Ewi Alohun ti o je mo esin abalaye iyere: ifa, Sango pipe |
2 | EDE – Aroko Alalaye ASA – Ogun pinpin LITIRESO – Awon ewi alohun ti o je mo esin abalaye – yala, iwi egungun, oya pipe |
3 | EDE – Atunyewo awon apola ninu gbolohun ede Yoruba. Apola oruko ati Apola ise
ASA – Asa ati suyo ninu awon ewi atohun ti o fem o esin abalaye ijale, iwi egungun, Oya pipe, Sango pipe. LITIRESO – Kika iwe litireso apileke ti Yoruba |
4 | EDE – Atunyewo awon eye gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba
ASA – Atunyewo awon ere idaraye ile Yoruba LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
5 | EDE – Gbolohun ibeere – awon iwure ti a fi n se ibeere da, nko, nje, taki
ASA – Atunyewo asa iran a enilowo, owe, aaro, obese, esuse, ajo LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
6 | EDE – Atunyewo ami ohun ati silebu
ASA – Atunyewo asa iran ra eni lowo owe, aaro, obese, esusu, ajo LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
7 | EDE – Atunyewo lori ibasepo laarin awe gbolohun ede Yoruba
ASA – Awon orisa ile Yoruba obalale LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
8 | EDE – Atunyewo orisirisii eya awe gbolohun
ASA – Awon oris ile Yoruba – Ogun LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan |
9. | Akaye: Kika Akaye lori itan aroso |
10 | Apeko: Awon gbolohun keekee Yoruba |
11 & 12 | Atunyewo ise saa yii |
13 | Idanwo ase kagba fun saa yii |
OSE KINNI
AKORI EKO: FONOLOJI EDE YORUBA
Fonoloji ni imo eto amulo iro lapapo. Eko ti o je mo bi a se n to iro papo ninu oro ede Yoruba ti oro ede Yoruba si fi yori si gbolohun ede Yoruba ni a n pen i fonoloji.
Iro Faweli: Eyi ni awon iro ti a maa n gbe jade nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edo foro oo. Orisii iro faweli meji ni o wa ninu ede Yoruba, awon ni:
Iro faweli airanmupe: a, e, ȩ, i, o, ǫ, u
Iro faweli aranmupe: an, en, in, on, un
Iro Konsonanti ede Yoruba: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ş, t, w, y
Iro Ohun: orisii meta ni iro ohun ede Yoruba, awon ni:
- Iro ohun oke / (mi)
- Iro ohun aarin — (re)
- Iro ohun isale \ (do)
Apeere amulo iro ede Yoruba pelu ami ohun lori:
- Igbaale
- Agbalagba
- Omoboriola
Ise Asetilewa
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku. Ni ile Yoruba, ayeye isinku agba je ohun Pataki ti o fese mule ni awujo awon Yoruba paapaa ti o ba je agbalagba ti o fi owo rori ku.
Inawo ati ipalemo oku maa n po fun awon molebi ati ana oku. Gbogbo molebi oku ti o wan i irinajo ati ti itosi ni won gbodo peju pese si ibi isinku naa.
Igbese Isinku ni ilu Yoruba
- Itufo ikede
- Ile oku gbigbe
- Wiwe oku
- Oku tite
- Oku sinsin
- Igbalejo
Iranse olodumare ni iku je. Oun ni Adebola maa n ran lati mu eniyan ti akoko to da ba to lo si orun. Awon Yoruba gbagbo wipe gbese ni iku, ko si eda ti ko ni san-an. Won ni “Aye” ni oja orun ni ile. Irinajo ni awon Yoruba ka iku si. Idi niyi ti won fi maa n sin awon nkan jije, mimu aso ati bata mo oku agba ki o le ri nkan lo ni irinajo aye. Awon oba ni ile Yoruba tile maa n ni abobak ti yoo maa ran-an lowo ni ona orun.
Ise Asetilewa
- Eni ti ara san pa
- Eni ti o pokunsi
- Oku abuke
- Oku aboyun
- Oku onigbese
OSE KETA
AKORI EKO: APOLA INU EDE YORUBA
Apola je okan ninu awon abala ihun gbolohun ede Yoruba. Gbolohun le je eyo oro kan tabi akojopo oro ti oni itumo. Ihun gbolohun ede Yoruba dabi igba ti a bah un eni, a ni lati to awon oro wonyii jo lona ti yoo fi le e mu itumo ti o gbamuse lowo. A tun le fi we awon ohun elo ikole ti o toju lorisirisii lona ti yoo fi gbe ile ti o dara, ti o si lewa jade.
Lara awon isori oro ti a to jo lati hun gbolohun ede Yoruba ni:
- Oro Oruko
- Oro Aropo Oruko
- Oro Apejuwe
- Oro Ise
- APOLA ORO ORUKO (NOUN PHRASE): Eyi le je oro kan tani akojopo oro ti a maa n lo gege bi oluwa ati abo ninu gbolohun yala pelu eyan tabi laisi eyan. Ihun apola oruko le je:
- Oro – Oruko kan soso pere: Ojo rǫ
- Oro – Aropo oruko: Mo sun
- Oro aropo afarajoruko: Eyin ni mo ri
- Apapo oro oruko pelu eyan:
Okunrin yen ni o mu
Ewure merin ni won pa bo ifa
Bola aburo Kemi ti wolu de
Ounje die ni ki o se
[mediator_tech]
ȩ. Apapo oro – oruko ati awe gbolohun: Oro ti Kemi so dun won.
- APOLA ISE (VERB PHRASE): Apola maa n je eyo oro tabi akopo awon eyo oro ti o le se ise oluwa ninu awe gbolohun ati odidi gbolohun. O le je oro-ise ponbele, oro ise agbabo, asaaju oro ise ati enyan. Oun ni o n sise opomulero ninu gbolohun ede Yoruba. Bi Apeere:
Jokoo, sare, jade, dide, ati bee bee lo. Apeere:
Bisi ra iyan
Komolafe je efo
Ayo sese de Ijanikin
Gbadebo gbin ododo
- APOLA APONLE: Apola aponle ni awon oro ti o n se ise epon tabi eyan fun oro-ise ninu gblohun ede Yoruba. Apola aponle maa n fi itumo ti o kun fun oro-ise inu apola ise ni. Apola aponle ti maa n jeyo. Fun apeere:
O n tan yerieyeri
O n rin kemokemo
Aso funfun balau
O tutu niginnigin
Ise Asetilewa
Tooka si awon apola ti a fa ila si nidii ninu awon gbolohun isale yii:
- Ade jeun o si yo
- O mu oti lile
- Sare lo jeun
- Dide wa
- Ayinde rin jelenke
- Mo ra eran ogunfe
- Bisade rin pelepele
- Emi ni won pe
OSE KERIN
AKORI EKO: EWI AKOMOLEDE
JE OLOGBON OMO
A ko mi nifee
Mo mo fee su
A ko mi lror
Mo moro atata I pe
Awon agba lo ko mi ni samusamu
Ti mot i menu ije
Ife mi yato si teni ti n yinmu
Oro mi yapa si tala taan toto
Ipede mi mogbon dani
Ife temi si ye eye to leti gidi
Beeyan ba n soro ti o ni koko ninu
Be e ba n pede ti o yeeyan
Bi eni to n lu afefe lasan ni
Ife mi kii se faditi eye rara
Oro mi kii se fomugo eeyan
Ologbon lo si le ye gidi
Omoran lo si le modi oro
Boo ba fe mfe mi ore
Boo ba fe gbadun oro atata
Je ologbon omo to dori eja mu
Ma se jomugo atode to tiya pokii
Itunmo awon oro to ta koko ninu ewi
- Samusamu: didun tie nu maa n dun bi a ba nje nkan lenu
- Tala taa tontoto: tumo si omode ti o mo roo so se maa n pede
- Pokii: omo ti o ya alaigboran paraku (eni ti o ti baje ninu iwa buburu)
[mediator_tech]
OSE KARUN
AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN
Gbolohun ni oro tabi akojopo oro ti o ni itumo. Gbolohun le je ipede ti o ni itumo tabi ni ise ti o n se nibikibi ti o ba ti jeyo. Bakan naa a le pe gbolohun ni oro ti a le pin si spola oro-oruko ati apola ise.
ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA
- Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode
- Gbolohun alakanpo
- Gbolohun ibeere
- Gbolohun olopo oro-ise
- Gbolohun alaye
- Gbolohun ase
- Gbolohun iyisodi
- Gbolohun iba tabi kani
- Gbolohun akiyesi alatenumo
- Gbolohun asodoruko
- Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode: eyi ni ipede tabi afo ti o ni oro-ise kan ninu. Irufe gbolohun yii ni a tun mo si gbolohun kukuru. Bi apeere:
- Bisi sun
- Dayo gun igi
iii. Fadekemi we gele
- Gbolohun alakanpo: eui ni ipede tabi gbolohun ti a lo oro asopo lati so gbolohun meji tabi ju bee lo po di eyo gbolohun kan soso. Bi apeere:
Ile re tobi, iyara re kere = ile re tobi sugbon iyara re kere
Temidayo lo si ibi ayeye naa
Adeyemi lo si ibi ayeye naa
= Temidayo ati Adeyemi lo si ibi ayeye naa
- Gbolohun ibeere: eyi ni awon gbolohun ti a fi n se ibeere. Awon wunren gbolohun ibeere ni, da, nko, tani, ati bee bee lo. Bi apeere:
Adegoke da?
Badejo nko?
Ta ni o wa nibe?
- Gbolohun olopo oro-ise: gbolohun yii naa ni a mo si gbolohun onibo. Gbolohun yii maa n ju eyo oro-ise kan lo, oro-ise inu gbolohun yii le je meji tabi meta. Bi apeere:
Mo jeun mo si yo
Won n rin won n yan won si se oge
Ise asetilewa: Ko apeere meji lori orisii gbolhun ti o mo
ITESIWAJU ISE LORI ISORI GBOLOHUN
- Gbolohun alaye: eyi ni gbolhun ti a n lo lati so bi n kan se ri. Bi apeere:
Won ti jewo bi oro ti se ri gan-an
Iwe meweaa ni Bolude ka
Ojo naa fere wu oku ole
- Gbolohun iba tabi kani: eyi ni gbolohun ti a fi n so bi nkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Atoka re ni ‘bi’, ‘kaka’, ati ‘dipo’. Bi apeere:
Bi mo ma lowo maa dara
Kaka ki n jale, maa di eru
Dipo ki n ra eran, maar a eba
- Gbolohun iyisodi: awon oro atoka gbolohun yii ni ‘ko’, ‘kii’, ‘ko’, ‘ma’. Bi apeere:
Bisi ko wan i ana
Femi o ri osere naa
Akande kii wa si ipade dede
Jegede kii je ewa
- Gbolohun akiyesi alatenumo: A maa n fi pe akiyesi si apa ibikan pato tabi koko kan ninu odidi gbolohun nipa lilo ‘ni’ ninu gbolohun abode ti a fe se atenumo. Bi apeere:
Mo ra ile tuntun ni Abuja
Rira ni mo ra ile
Abuja ni mot i ra ile tuntun
- Gbolohun Ase: Eyi maa n waye nipo ipede ti o je kan-an nipa fun eniti a ba soro. A maa n lo o gege bi igba ti a fi n mu u je dandan fun eni naa. Bi apeere:
Dake je!
Dide duro ati bee bee lo
Ise asetilewa
Ko apeere kan-kan lori orisii gbolohun ti o se le ni ki o si ko meji lori gbolohun asodoruko.
[mediator_tech]
OSE KEFA
AKORI EKO: ERE IDARAYA
Ere idaraya ni awon ere t tewe – tagba maa n se lati mu ki ara won jipepe. Bi awon Yoruba se feran ise – sise to bee naa ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti ise ba dile tabi awon eniyan ba dari bo lati ibi ise oojo won ni won maa n fi aboo si ibi ere idaraya. Ere idaraya wa fun omode ati agbalagba.
A le pin ere idaraya ti o wopo laarin awon Yoruba si meji. Awon ni:
- Ere osupa ati
- Ere ojoojumo
- ERE OSUPA: ni awon omode maa n se ti ile bat i n sun i akoko osupa nitori aisi ina monamona ni oye ojoun (atijo)
Awon ere bee ni:
- Bojuboju
- Ekun meran
- Eye meloo tolongo waye
- Booko – booko
- Isa – n – saa – lu – bo
- Kini newu
- Alo apamo ati alo apagbe
- ERE OJOOJUMO: eyi ni ere ti tomode – tagba maa n se ni owo osan si irole. Iwonyi le je ere abe ile bii: (i) ayo tita (ii) moni – ni – moni – ni
- ERE ITAGBANGBA: eyi le je:
(i) eke tabi ijakadi (ii) okoto tita (iii) Ere arin
ANFAANI ERE IDARAYA
- O n mu nii ronu jinle
- O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo (atayebaye)
- Erin ati awada maa n waye
- O maa n ko ni bi a ti ri fi oju sun ohun okere (ninu ere arin)
- O n mu ki omode ni agbara ki o si ni aya lati le koju sioro (ija fun idaraya kii je ki omode saisan)
- O n mu ajosepo to danmoran wa laarin awon omode
- O n mu ki omode gbagbe wahala ise oojo.
ALEEBU ERE IDARAYA
- O maa n gba akoko eniyan
- Oro iwosi maa n waye ninu ere idaraya (ayo tita)
- Erupe le gbon si oju omode rabi ki emomiran kan ni orun ese nibi ti won ti n sare kiri
- Eniyan le ti ibi ijakadi di alaabo ara titi ojo aye onitohun.
ASA IRANRA – ENI LOWO (COMMUNAL ASSISTANCE)
Asa iranra – eni lowo je ona ti awon Yoruba fi maa n ran ara won lowo ni aye atijo. Asa yii maa n saba jeyo ninu ise oko riro, ile kiko, owo yiya tabi n kan miiran.
Asa iranra – eni lowo maa n mu ki ise ti o po ti o le gba eniyan ni akoko pupo di sise ni kiakia nipa pipapo se e. ilana jijumo se ise papo maa n mu ki okun ife nipon, o si maa n je ki wahala dinku laarin awon eniyan ti won wan i ayka kan naa.
Orisii ona iranra – eni lowo
- Owe
- Aaro
- Ajo
- Esusu
- Owo ele kiko (so ogundogoji)
- San – an – die – die
- Fifi omo/nnkan ini duro
- Aaro: awon odokunrin ti won je ore ti oko won si wan i itosi ara won ni won maa n be ara won ni aaro fun ise oko ti o bap o. olukuluku ni yoo si jumo se e ni ojo kan titi ti won yoo fi se kari ara won. Ounje tabi ohun mimu kii se dandan, sugbon ise naa gbodo yipo kari.
- Owe: A maa n be owe ni, opo eniyan bi ebi, ore tabi ojulumo ni a le be lowe lati ba ni sise. Won yoo da ojo owe kii sise dandan lati san owe pada, sugbon eni ti o be lowe gbodo pese ohun jije ati mimu.
- Esusu: eyi ni ona ti a maa n gba fi owo pamo lati fise n kan gidi ni ojo iwaju. Ko si ere ninu esusu, sugbon enikan n yoo je olori ti yoo dari won ti gbogbo akopa yoo si fenuko lori akoko ti won fe maa ko boya osose ni tabi osoosu.
- Ajo: Awon eniyan le maa dawo jo si owo enikan titi di ipari osu tabi akoko ti won ba fi adehun si. Eni ti o n gba ni yo maa se eto pinpin re, yoo si yo die lori owo eni kookan ni ibere owo ti won n da.
- Owo ele kiiko tabi sogundogoji: awon eniyan ti o ba koju isoro to le tabi ti o ba wo wahala, ni won maa n ko owo ele lati fi bo asiri ara won. Nigba miiran ele le je ilopo meji owo ti won ya.
- San – an – die – die: eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san – an owo re pada die – die titi yoo fi san gbogbo oeo naa pada.
- Fifi omo tabi ohun ini duro: ti eniyan ba nilo owo, won maa n fi omo tabi nkan ini ti o niye lori duro lati ya owo. Igba ti eni naa ba san iru owo bee tan, ni yoo to gba n kan ti o fi duro pada.
OSE KEJE
AKORI EKO: ATUNYEWO AMI OHUN ATI SILEBU EDE YORUBA
Silebu ni ege oro ti o kere julo ti a le da fi ohun pe ni enu ni ori isemii kan soso. Ege agbaohun (a-gba-ohun) ni silebu je, eyi ni pe iye ibi ti ohun bat i jeyo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han.
Iro meta ni o se pataki ninu ede Yoruba awon ni: iro faweli, iro konsonanti ati iro ohun.
EYA IHUN SILEBU: meta ni eya ihun silebu ede Yoruba. A le fihan nipa lilo ipele koofo: [f], [kf], [N] bi odiwon.
Ipeele kefo
F faweli [ǫ, e, in, an, a, u, o, en]
KF konsonanti [wa, lo, sun, abbl]
N konsonanti aranmupe ase silebu [N] – [n,m].
[mediator_tech]