ERE IDARAYA
OSE KEFA
AKORI EKO: ERE IDARAYA
Ere idaraya ni awon ere t tewe – tagba maa n se lati mu ki ara won jipepe. Bi awon Yoruba se feran ise – sise to bee naa ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti ise ba dile tabi awon eniyan ba dari bo lati ibi ise oojo won ni won maa n fi aboo si ibi ere idaraya. Ere idaraya wa fun omode ati agbalagba.
A le pin ere idaraya ti o wopo laarin awon Yoruba si meji. Awon ni:
- Ere osupa ati
- Ere ojoojumo
- ERE OSUPA: ni awon omode maa n se ti ile bat i n sun i akoko osupa nitori aisi ina monamona ni oye ojoun (atijo)
Awon ere bee ni:
- Bojuboju
- Ekun meran
- Eye meloo tolongo waye
- Booko – booko
- Isa – n – saa – lu – bo
- Kini newu
- Alo apamo ati alo apagbe
- ERE OJOOJUMO: eyi ni ere ti tomode – tagba maa n se ni owo osan si irole. Iwonyi le je ere abe ile bii: (i) ayo tita (ii) moni – ni – moni – ni
- ERE ITAGBANGBA: eyi le je:
(i) eke tabi ijakadi (ii) okoto tita (iii) Ere arin
ANFAANI ERE IDARAYA
- O n mu nii ronu jinle
- O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo (atayebaye)
- Erin ati awada maa n waye
- O maa n ko ni bi a ti ri fi oju sun ohun okere (ninu ere arin)
- O n mu ki omode ni agbara ki o si ni aya lati le koju sioro (ija fun idaraya kii je ki omode saisan)
- O n mu ajosepo to danmoran wa laarin awon omode
- O n mu ki omode gbagbe wahala ise oojo.
ALEEBU ERE IDARAYA
- O maa n gba akoko eniyan
- Oro iwosi maa n waye ninu ere idaraya (ayo tita)
- Erupe le gbon si oju omode rabi ki emomiran kan ni orun ese nibi ti won ti n sare kiri
- Eniyan le ti ibi ijakadi di alaabo ara titi ojo aye onitohun.