SILEBU
OSE KERIN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: SILEBU
Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo.
Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.
Ihun oro orusilebu kan le je,
I faweli nikan –(F)
ii Apapo konsonati ati faweli (KF)
iii Konsonati aranmupe asesilebu (N)
Apeere faweli nikan,
Gbogbo faweli aramupe ati aramupe je ihun oro onisilebu kan a e e I o o u
an en in on un.
Lilo won
Mo-ra-a (silebu kan ni “a, I, on, ati un”)
Mo-ri-i
Tolu mo-on
Baba-fun-un
Apeere apapo konsonati ati faweli (KF)
Lo – KF
Je – KF
Sun – KF
Fe – KF
Gba – KF
Ta – KF
Ge – KF
Ke – KF
Ra – KF
Ran – KF
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won
Asa ikini je okan lara iwa omoluabi. o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere dandan ni ki omokurin dobale gbalaja ki omobirin si wa lori ikunle ti won ba n ki agba.
Ikini ni aarin eya Yoruba.
Ede Ajumolo Ede Adugbo Ilu
E kaa-aro Wen kaaaro Ijebu
Nkoo Oro Ekiti
In kuo u ro o Ilesa
O koo ri ro Akoko
E kaaro Ife
Apeere miran
Alangbaa ti wo le Alangbaa ti wo le Oyo
Olo do gba ti ole Ijesa
Ijon gba ti wo le Ijebu
[the_ad id=”40090″]
Ounje eya Yoruba
Ouje je ohunkohun ti eniyan tabi eranko n je tabi mu ti o si n sara lore.
Orisirisi awon agbegbe ni ile Yoruba ni o ni iru ounje ti won feran.
Ondo ati Ekiti – Iyan
Ijebu – Ikokore
Egba – Laafu
Ibadan – Oka/amola abbl
Ona ti a n gba se awon ounje ni ile Yoruba
Ewa
Won a sa ewa
Won a gbe omi ka ori ina
Bi omi ba ho won a da ewa sii
Won a re alubosa sii
Bi ewa ba ti fe jinna, won a fi ata lilo epo ati iyo sii
Leyin ti o ba ti jinna, o ti di jije
Oole / moin moin
Won a bo eepo ewa kuro
Won a lo ewa pelu ata ati alubosa
Won a pon ewa sinu ewe
Won a gbe e kana
Bi o ba jina, o di jije
Akara
Won abo ewa
Won a lo ewa pelu ata
Won a gbe epo kana
Won a re alubosa si ewa lilo
Won a da ewa lilo die die sinu epo gbigba
Bi o ba din tan, o di jije
[the_ad id=”40090″]
Isu sise
Won a bo eepo ara isu danu
Won a gee si wewe
Won a gbe e kana pelu omi
Won a fi iyo sii, won a si de ikoko naa
Bi o ba jina, o jije
Iyan
Won a be isu
Won a gee si wewe
Won a da isu si ori ina pleu omi ninu re
Won kii fi iyo si bi isu jije
Bi o ba jinna, won a gun ninu odo
Leyin eyi won a fi obe ti o wu won jee
Asaro
Won a be epo isu danu
Won a gee si wewe
Won a gbe omi lena
Won a da eroja bi ata, epo, eja, iyo, ede alubosa abbl sinu re
Bi omi ba ti ho, won a da isu sii
Won a roo po
Bi o ba jinna, o di jije abbl
Igbelewon:
- Fun ounje ni oriki
- Ko eya Yoruba merin ki o si ko ounje ti won feran ju
- Kin ni silebu?
- Ko ihun silebu pelu apeere meji meji
Ise asetilewa: bawo ni a se n se ekuru ati obe gbegiri nin ile yoruba