ORIKI IBADAN
Pry four
Akole:oriki ilu awon akeekoo
Asa oriki se pataki ose koko pupo ni ile yoruba bi a se ni oriki idile bee naa ni a ni oriki orile.
Oriki orile ni oriki ilu kankan ti abti wa gege bi omo yoruba eje ki a gbo oriki awon ilu bi meta
Ilu eko
Ilu ibadan
Ilu egba
ORIKI EKO
Eko adele,eko akete ile ogbon.Eko aromisa legbe legbe.Arodede maja.Okun lotun osa losi.Omi niwaju omi leyin.Omi ni ibi gbogbo.Ka jeba jeba ka je feselu.Ka mumi tupulu si.Eko niyen.Yanmu yanmu eyin igbeti nko?o le gbadie osoo ro.Obalende le yomo leti eni.Eko akete ile ogbon.Eni to deko tuo ogbon,ogbon oni toun dorun alakeji.
ORIKI IBADAN
Ibadan mesi ogo,nle oluyole,nibi ole gbe jare oloun.Ibadan majamaja lase kara iwaju leru.Ibadan ilu ojo,ilu ajayi,ilu ibikunle,ilu ogunmola,ologbodo keri keri loju ogun.Ibadan kii gbonile biko se ajayi.Aki waye ja ma larun kan lara ija igbooro larun Ibadan.
ORIKI EGBA
Egba omo lisabi
Oniruru egba po nile alake.Olugbonjobi lori won.Ija kan ijs kan,ti won nja loja,lo ntuluu egba orile,nlo so sodeke di baba ohun labe olumo.Oniruru egba po nile alake.Egba agura,egba oke ona,egba owu,egba alake,gbogbo won lo gba ijaye lalejo labe olumo.
Ise kilasi
1.ilu wo n aki bayi pe mesi ogo (a)Ibadan (b)eko
2.ilu wo ni aki bayii pe aromisa legbe legbe (a)epe (b)eko.
3.ilu wo ni a ki bayii pe omo lisabi,olugbonjobi lori won (a)ibadan (b)egba