Asa Iranra Eni lowo- Ajo, Esusu, Egbe Alafowosowopo

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Second Term

 

Week : Week 3

 

Topic :

EDE: Aroko Asapejuwe ( kiko aroko alapejuwe).

ASA: Asa Iranra eni lowo (owe, aaro, arokodoko, ebese )

LIT: Kika Iwe Apileko: ere onise ti ijoba yan

 

 

 

OSE KETA.

AROKO ALAPEJUWE

AKOONU: Deeti………………..

  • Itumo.
  • Apeere.

Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.

 

AROKO ALAPEJUWE

Eyi je mo sise apejuwe eniyan, ibikan tabi ohun kan lona ti o se pekipeki nnkan naa. Tori a le so wi pe aroko alapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe eniyan tabi ibi kan(Descriptive essay). Apejuwe wa gbodo fi han pe a mo ohun ti a n soro nipa re. Apeere ori oro aroko alapejuwe ni:-

  • Ile baba mi
  • Oja ilu mi
  • Ore mi ti bimo feran ju
  • Ile iwe mi

ILANA AROKO (ILE BABA MI)

Ilu wo ni ile naa wa

Adireesi ibi ti ile naa wa

Bawo ni ile naa se ri ( ile ile/alaja)

Oda wo ni ile naa ni?

Ki ni a koko maa ri ni ile naa

Ojule melo ni ile naa

Nje iyato wa laarin ile yii si omiiran bi?

Ko boya o feran ile naa tabi o ko feran re, salaye

IGBELEWON

1 Ki ni a n pe ni aroko?

2 Orisii aroko melo lo wa?

  1. Salaye aroko alapejuwe
  2. Ko ilana lori aroko “ore mi ti mo feran ju”

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji ( J.s.s.2) oju iwe 49-53 Longman Nig Plc.

Jss 1 Yoruba First Term 

SS 1 Yoruba Third Term 

Second Term Examination Yoruba Upper Primary 

Ilana Ise Fun Taamu Keta SSS 2

AKORI ISE: ASA IRANRA – ENI – LOWO.

Asa iranra – eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo tabi ki a so pe asa iranra eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba soore fun arawon. Orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo. Die lara won ni: (i) Aaro (ii) Ebese (iii) Esusu abbbl

Esusu:-Eleyii ni i se pelu owo. Won maa n da owo yii ni. Won maa n ni eni ti yoo maa gba owo yii laarin arawon. Eni ti o n gba owo yii maa gba owo naa kaakiri lodo awon eniyan (omo egbe). Bi won ba ti n da owo yii ni won maa ko si ara iganna/ogiri (wall) won o maa fa igi kookan si ara iganna, igi yii ni iye ti o duro fun.

Ajo:- Ajo naa dabi esusu ni, won maa n da owo fun olori alajo. O ni iye owo ti eniyan yoo maa da bi agbara eeyan ba se to. Iyato to wa laarin esusu ati ajo ni wi pe gbogbo iye ti eniyan ba da ni eeyan yoo ko nibi esusu sugbon nibi ajo eeyan yoo ko ida kan sile fun olori alajo.

Egbe alafowosowopo: egbe alafowosowopo naa ni won n pe ni egbe alajeseku. Egbe yii wopo wa laarin iyaloja,osise ijoba abbl. Won maa n ni oloye laarin won bi akowe, akapo, ayewe owo wo.ki a ranti wi pe awon egbe yii maa n ni eto ati ofin lati odo ijoba. Eyikeyi ninu omo egbe ni o ni anfaani lati ya owo nibe.

IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?.

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe University Press Nig

2 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe 136-146 University Press Nig

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

APAPO IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. Iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?
  3. Salaye kekere lori iwe itan aroso ti o n ka.
  4. Ko onka lati 1-100.

ISE AMURELE

  1. ….. je ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. A. akaye B. gbolohun D. aroko E. aroso
  2. Ti a ba fe ko aroko, a gbodo koko yan ….. A. ikadi B. ifaara D. ori oro E. ikadii
  3. Aroko wa gbodo ……. A. koni logbon B. panilerin D. mu eniyan sun je oni-isipaya
  4. Ewo ninu awon wonyi ni o ni eto ijoba ninu? A. egbe alafowosowopo B. ajo D. esusu E. ebese.
  5. Iru eniyan wo lo le se olori elesusu. Eni ti o ba je ….. A. olowo B.ologbon D. olooto. E. osise ile ifowopamosi.

APA KEJI

  1. Ki ni aroko alapejuwe?
  2. Iyato wo lo wa laarin arokodoko ati aaro?

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share