Ilana ise fun saa kinni SS1 YORUBA
FIRST TERM E-NOTE
SUBJECT: YORUBA
CLASS: SS1
Ilana ise fun saa kinni
Ose kinni-Ede
Atunyewo awon eya ifo
-Eyi ti a le fojuri ati eyi ti a o le fojuri
-Afipe asunsi ati akanmole
Asa- Owe lorisiirisii-owe imoran ,ibawi abbi.
Litireso –Atunyewo orisii eya litireso,ohun ti litireso je
Awon eya litireso.
Ose keji-Iro-ede Yoruba
Ohun ti iro-ede je
-orisii iro-ede ti o wa-konsonanti,faweli ati ohun.
Idako konsonanti ati faweli.
Asa-Awon owe ti o je mo asa Yoruba
-igbeyawo,isomoloruko,isinku abbi.
Litireso-Igbadun ti o wa ninu litireso alohun..
Ose keta-Apejuwe iro faweli
-oriki,abuda
-yiya ate faweli
Asa-Awon owe ti o suyo lati inu itan ati ise Yoruba.
Litireso-Eko lori igbadun ti o wa ninu litireso alohun ,ere onise,esa egungun,
Ijala abbl.
Ose kerin atiikarun -Apejuwe iro konsonanti
-oriki,abuda.
Asa -Iwa omoluabi ati anfaani re
-Awon amuye iwa omoluabi
Litireso –Ogbon itopinpin litireso
Ose kefa –Itesiwaju lori iro-ede Yoruba
-iro-ohun.
Asa –Ise abinibi ile Yoruba
Litireso-Ogbon itopinpin litireso.
Ose keje –Silebu ninu ede Yoruba
-oriki,ihun silebu
-odo ati apaala silebu.
Asa – Awon ise ona abinibi.
Litireso-kika iwe litireso.
Osekejo-Akoto ede Yoruba
-Itan bi ede Yoruba se di kiko sile
-awon ayipada to de ba kiko ede Yoruba sile[ilana akoto ode-oni]
Asa- Awon ise abinibi ile Yoruba-eto ati ilana ekose,gbigba iyonda.
-anfaani ti o wa ninu ikose.
Litireso-kika iwe litireso
Ose kesan-an-Aroko kiko-ilana ati ogbon ti a n ta fun aroko kiko
-ifaara,ipinro,ilo-ede.
-orisii aroko ti o wa..
Asa-Elegbejegbe tabi irosiro
-ipa ti won n ko.
Litireso- kika iwe litireso.
Ose kewaa-Akanlo-ede
-iwulo akanlo-ede
akanlo-ede ati itumo won
Asa- asa iranra-eni-lowo
Litireso-kika iwe litireso.
Ose kokanla-Akanlo-ede
- lilo won ni gbolohun lati fi itumo won han.
- Asa – asa iranra-eni-lowo.
- -Atupale asayan iwe litireso.
Iwe itokasi
Imo,Ede,Asa Ati Litireso.S.Y Adewoyin
Eto Iro ati Girama fun sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
Ijapa Tiroko.
OSE KINNI
ORI-ORO : Awon Eya Ara Ifo
-Eyi ti a le fojuri ati eyi ti a ko le fojuri
-Afipe asunsi ati akanmole.
Akoonu
Eya ara ifo-;eyi ni awon eya arati won n sise papo lati gbeiro-ede jade.
Eya ara ifo-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.
Apeere awon eya ara ifo ni;
Ahon,,ete,,afase, eyin, erigi,komookun,tan-an-na,olele,aja-enu,gogongo,alafo tan-an-na abbl.
Isori eya ara ifo
Eya ara ifo pin si ona meji
1.Awon eya ara ifo ti a le fojuri
ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri.
Eya ara ifo ti a le fojuri-;eyi ni awon eya ara ti a le fojuri paapaa ti a ba lo digi.
Ap;
Iwaju ahon
Aarin ahon
Eyin ahon
Ete oke
Ete isale
Olele
Afase
Erigi
Eyin oke abbl.
ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri-;eyi ni awon eya ara ifo ti a ko le fojuri,ti won wa ninu ikun wa.
Ap
Edofooro
Eka komookun
Tan-an-na
Inu gogongo
Kaa ofun
Afipe
Afipe-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.afipe pin si ona meji
Afipe asunsi ati
akanmole.
Afipe asunsi-eyi ni awon eya ara ifo to le sun soke tabi sodo nigba ti a ba n soro.obere latiete isale wa si agbondo.
Apeere afipe asunsi ni;
Eyin isale
Ete isale
Iwaju ahon
Eyin ahon
Olele
Aarin ahon
Afipe akanmole;-Eyi ni awon eya ara ti ko le sun kuro ni oju kan,ti won maa n duro gbari nigba ti a ba n soro .o bere lati oke enu wa apeere
Ete oke
Eyin oke
Erigi oke
Afase
Kaa imu
Aja enu
IGBELEWON
Daruko eya ara ifo mewaa.
ASA
ORI-ORO-;Owe ile Yoruba
AKOONU
Yoruba bo won ni ‘Owe ni esin oro,oro ni esin owe,boro ba sonu owe ni a fi n wa.
Owe je ijinle tabi koko ewa-ede ti o n fi asa,ero,ati ise awon Yoruba han.
Owe wulo pupo ni opolopo ona
Opolopo ona ni owe gba wulo, awon ohun ti a n lo owe fun niwonyii;
Owe ikilo
Owe ibawi
Owe efe
Owe imoran/isiri.
OWE IKILO.
Owe ikilo ni a n lo lati kilo iwa fun tomode –tagba.Bi omode kan ba n kegbe buruku awon,awon agbalagba le pe iru omo bee ki won wi fun-un pe ki o sora nitori pe;-
-Agutan ti o ba ba aja rin yoo jegbe.
– Egbe buburu n ba iwa rere je..ohun ti won n wi fun omo bee nipe won kaa si omo rere sugbon o gbodo yera fun awon oniwa buburu.
– Arinrin gbere niyoo moye dele,asure tete kole roye je.
– A kii fi ikanju labe gbigbona.
– Kirakita ko mola,ka sise bi eru koda nnkan.
– A kii korira atokun kadigbo lu eegun.
– Puro ki o niyi,ete ni n mu wa.
LITIRESO
IGBELEWON
1.Kin ni afipe?
b.Salaye afipe asunsi ati akanmole.
2.kin ni owe?
b.Daruko orisii owe merin ti o mo.
IWE AKATILEWA
Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yoruba ss2 o.i 1-5.
ISE ASETILEWA
1.______ ni awon eya ara ti a n lo lati gbe iro-ede jade.
[a]enu [b]eya ara ifo [d]eya ara.
2.Apeere eya ara ti a le fojuri ni ——–
[a]Edofooro [b]gogongo [d]ete
3.Ona ——— ni litireso pin si
.[a]kan [b]meji [d]meta
4.Eya ara ti o le sun kuro ni ojukan nigba ti a ba n soro ni__
.[a]inu gogongo [b]asunsi [d]akanmole.
5.________ ni esin oro,oro lesin owe.
[a]akanlo-ede ]b]owe [d] ijinle oro.
APA KEJI
1’Kin ni eya ara ifo
b.Daruko eya ara ifo mewaa.
2.Daruko ohun merin ti a n lo owe fun.
OSE KEJI
ORI-ORO-;IRO-EDE
ORIKI IRO-EDE
-ORISII IRO-EDE
AKOONU
Iro-ede -; ni ege ti o kere julo ti a le fi eti gbo ninu ede,ti a ba n ba eniyan soro ,iro ifo ni ohun ti eni naa yoo maa gbo.
A le ko iro –ede sile nipa lilo leta tabi ami.Iro-ede ti a ni pin si ona meta;
Iro faweli
Iro konsonanti
Iro ohun.
Iro faweli ;ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.
Ona meji ni iro faweli pin si
Faweli airanmupe
Faweli aranmupe
Faweli airanmupe je meje,awon naa ni a,e,e,i,o,o,u.
Faweli aranmupe je marun-un,awon naa ni an,en,en,in,un..
IDAKO IRO FAWELI
Ilana akoto Ilana fonetiiki
, a [a]
. e [e]
e [ ]
I [i]
o [o]
o [ ]
u [u]
an [a]
en [ ]
in [i]
on [c]
un [u]
IRO KONSONANTI
Iro konsonanti-;ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba.,awon naa ni;b,d,f,g,gb,h,j,k,l,m,n,p,r,s,s,t,w,y.
IRO OHUN
Iro ohun meta ni o wa ninu ede Yoruba awon naa ni
Iro ohun oke
Iro ohun aarin
Iro ohun isale.
IGBELEWON
1.Kin ni iro-ede .
b.Daruko oridii iro-ede tio wa.
ASA
ORI-ORO-AWON OWE TI O JE MO ASA YORUBA
Akoonu
Awon Yoruba je eya Pataki ,ti kii soro ponbele laije pe won lo owe ti o si n tawo tase ninu oro won.
Owe je eroja Pataki ninu awon asa Yoruba bii igbeyawo,isinku isomoloruko abbl.
Eyi ni die lara owe awon owe ti o je mo asa igbeyawo.
-Atigbeyawo o tejo owo obe lo soro.
-Iyawo ta gbe losu aga ti n fiyan mole,yoo ba a nibe lomo reyoo maa je.
-Obe ti bale ile kii je iyaale ile kii se e.
Eni won n gbe iyawo bowa ba kii garun
Baya ba moju oko tan alarina a yeba.
Ohun to wu mi ko wu o,ni o je a pawopo feyawo.
ISOMOLORUKO
-Ile laawo ka to somoloruko.
-Oruko eni ni ijanu eni.
-Tori bomo o daran, la see ni oruko..
IRANRA-ENI-LOWO
-Ajeje owo kan ko gbegba dori .
-Gba mi nigba ojo ki n gba o nigba eerun.
-Owo omode o to pepe tagbalagba o wo kengbe.
-Omode nise agba nise la fid a Ileefe.
IGBELEWON
Pa owe meji fun asa igbeyawo ati isinku
LITIRESO
ORI-ORO-IGBADUN TO WA NINU LITIRESO ALOHUN
AKOONU
Litireso alohun –ni awon litireso ti a jogun lodo awon baba-nla wa ,ti won ko ni akosile ni aye atijo ,opolopo eko ti ako le fowo ro seyin ni a maa n ba pade tabi gbadun ninu awon litireso atenudenu wa ni Pataki julo oro geere ati aalo apamo
ORO-GEERE-;je moitan iwase ati itan laelae,tomode tagba lo le so tabi gbo jtan.. Awon itan wonyii maa n fun wa ni ogbon,imo,eko itaniji atiiwuri nigba miiran lati se ohun ara ti a ro pe a o le se tele.
-O maa n je ki a mo nipa awon itan iranti awon akoni atijo.
-O maa n je ka mo bi idile tabi ilu kan se se,asa atieewo won.
AALO APAGBE
Agba le ko awon omo jotabi ki awon omode ko ara won jo funra won lati gbadun aalo onitan.
-Omaa n ko won ni eko iwa.
-Itan wonyii maa n so idi abajo tabifi ogbon ewe kan han.
-O fun won ni anfaani ipejopo ati idaraya..
-Won tun ni anfaani orin kiko ninu aalo pagbe,eyi ti won lepatewo tabi jo si.
IGBELEWON
1.Kin ni iro-ede?
- Ona meloo ni iro-ede pin si.
2.Pa owe mejimej ti o je mo awon asa Yoruba wonyii
isomoloruko
igbeyawo
IWE AKATILEWA
Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yo Se Yoruba bo, won ni.
ruba.(ss2).Adewoyin S.Y. o.i 9-13.
ISE ASETILEWA
1._________ ni ege ti o kere julo ti a le fi eti gbo. [a] ohun [b] iro [d]ede.
2._________ maa n wa ninu aalo apagbe [a]agogo [b]orin [d]ewi
3.Apeere litireso oloro geere ni ______ [a]rara [b]ere onise [d]aalo apamo.
4._______ omode o to pepe ,tagbalagba o wo kengbe. [a]ori [b]ese [d]owo.
5.A le ko iro –ede sile nipa lilo_______ [a]bairo [b]leta tabi ami [d]sisoro jade.
APA KEJI
1.Salaye ohun mejimeji ti a le gbadun ninu oro geere ati aalo apagbe.
2.Pa owe metameta fun awon asa Yoruba wonyii
isomoloruko
iranra-eni-lowo.
OSE KETA
ORI-ORO- APEJUWE IRO FAWELI
ORIKI,ABUDA
IDAKO
ATE FAWELI
AKOONU
Iro faweli-;ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo. ORISII
Ona meji ni iro faweli pin si
Faweli airanmupe
Faweli aranmupe
Abuda fun isapejuwe iro faweli
Eyi ni abuda ti a n lo fun isapejuwe iro faweli
Ipo ti ahon wa
Ipo ti ete wa
Ipo ti afase wa
Ipo ti apa to gbe soke ga de ninu enu.
ABUDA
Ipo ti ahon wa-;bi a ba tele abuda yii,ona meta ni a le pin iro faweli si,nitori pe ona meta ni ahon wa pin si,ipo ahon kookan lo si ni iro faweli ti a fi n pe.
Faweli iwaju
faweli aarin
faweli eyin
Faweli iwaju- eyi ni faweli ti a fi iwaju ahon pe,ap I,e,e
Faweli aarin- eyi ni faweli ti a fi aarin ahon pe.ap “a”
Faweli eyin-eyi ni faweli ti afi eyi ahon pe .ap o,u ,o.
IPO TI ETE WA-;bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si
Faweli roboto
Faweli perese
Faweli roboto-eyi ni iro ti a pe nigba ti ete se roboto.ap u,o,o
Faweli perese-eyi ni iro ti a pe nigba ti ete wa se perese.ap i,e,
IPO TI AFASE WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si
Faweli airanmupe
Faweli aranmupe
Faweli airanmupe-;ni iro faweli ti a pe nigba ti afase gbe soke lati di kaa imu ,ti eemi si gba kaa enu jade.ap i,e,a.ou.
Faweli aranmupe-;eyi ni iro faweli ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa enu ti eemi si gba kaa imu jade.ap a,e i.,u.
IPO TI APA TO GBE SOKE JULO GA DE NINU ENU-;bi a ba tele abuda yii,ona merin ni a le pin iro faweli si
Faweli ahanupe
Faweli ahanudiepe
Faweli ayanudiepe
Faweli ayanupe
Faweli ahanupe/(oke) -;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan lara ahon ba gbe soke ti o si fere ga de aja-enu.ap /I/,/u/,/i/,/u/.
Faweli ahanudiepe (ebake)-;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan to gbe soke ni ara ahon de ebake ,ti a ha enu die pee.ap/e/,/o/.
Faweli ayanudiepe(ebado)-;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan gbe soke to de ebado.ap/
/ / / /.
Faweli ayanupe (odo)-;ni faweli ti a penigba ti apa kan gbe soke ni ara ahon wa ni odo.ap/a/.
ATE FAWELI
Ate yii ni o n so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba n gbe iro faweli jade.
ATE FAWELI AIRANMUPE
Ahanupe i u
Ahanudiepe e o
Ayanudiepe
Ayanupe a
ATE FAWELI ARANMUPE
Ahanupe i u
Ahanudiepe e o
Ayanudiepe
Ayanupe a
ISAPEJUWE IRO FAWELI
[a]- aarin, airanmupe, ayanupe, perese.
[e]- iwaju , airanmupe,ahanudiepe, perese
[ ]- iwaju, airanmupe, ayanudiepe, perese.
[i ] – iwaju, airanmupe, ahanupe, perese.
[o]- eyin, airanmupe ahanudiepe, roboto.
[ ]- eyin,airanmupe, ayanudiepe , roboto.
[u]- eyin, airanmupe, ahanupe , roboto.
[a]- aarin, aranmupe, ayanupe , perese.
[ ]- iwaju ,aranmupe, ayanudiepe, perese.
[i]- iwaju ,aranmupe ,ahanupe , perese.
[ ]- eyin ,aranmupe, ayanudiepe, roboto.
[u]- eyin ,aranmupe , ahanupe, roboto
IGBELEWON
- Kin ni iro faweli?
- Daruko awon abuda fun isapejuwe iro faweli
- Sapejuwe awon iro faweli wonyii a,e u o
IWE AKATILEWA
Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yoruba fun sekondiri agba.Adewoyin S.Yo.i 40-49.
ISE ASETILEWA
1,_______ ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.[a]ohun [b]konsonanti [d] faweli.
2.Iro faweli pin si ona _________ [a]meji [b] meta [d] merin.
3.Ewo ni ko wulo fun isapejuwe iro faweli? [a]ipo ti afase wa.[b]ipo ti alafo tan-an-na wa.[d]ipo ti ahon wa.
4.Idako faweli “e” ni ______ [a] /e/ [b]/E/ [d]
5.Faweli airanmupe je ______ [a]marun-un [b]meje [d] mejo.
APA KEJI
1.Salaye ni soki lori awon faweli wonyii
/i/, faweli iwaju, ii faweli roboto iii faweli aarin.
OSE KERIN
ORI-ORO ; APEJUWE IRO KONSONANTI
AKOONU
Iro konsonanti; ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o ti inu edofooro bo.Iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba awon naa ni b,d,f,g,gb,h,j,k,l,m,n,p,r,s,s,t,w.y.
ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO KONSONANTI
Eyi ni awon abuda ti a maa tele ti a ba fe sapejuwe iro konsonanti
Ipo ti alafo tan-an-na wa
Ipo ti afase wa.
Ibi isenupe
Ona isenupe.
IPO TI ALAFO TAN-AN-NA WA
Bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro konsonanti si
Konsonantiaikunyun
Konsonanti akunyun
Konsonanti aikunyun-;ni iro ti ti a pe nigba ti alafo tan-an-na fi aye ti o to sile fun eemi ti o n ti inu edofooro bo,eyi ni pe ko si idiwo.apeere konsonanti aikunyun ni t,k,p,f,s,s,h.
Konsonanti akunyun-;ni a pe nigba ti alafo tan-an-na sunmo ara won pekipeki,ti idiwo si wa fun eemi ti n ti inu edofooro bo..ap/b/ /d/, /g/ //l/abbl
IPO TI AFASE WA
Bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si,awon naa ni
Konsonanti airanmupe
Konsonanti aranmupe
Konsonanti airanmupe-;ni iro ti a pe nigba ti afase gbe soke lati kaa imu,ti eemi si gba kaa- enu jade.ap/b/,/d/,/f//,/k/,/l/.
Konsonanti aranmupe-;ni iro konsonanti ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa-enu ti eemi si gba kaa-imu jade.ap /m/,/n/
IBI ISENUPE
Ibi isenupe-;eyi ni o n tokasi afipe asunsi ati akanmole ti a lo lati gbe iro konsonanti jade.
Ibi isenupe pin si ona mejo
Afeji-ete-pe
Afeyin-fetepe
Aferigipe
Afaja-ferigipe
Afajape
Afafasepe
Afafase-fetepe
Afitan-an na-pe
ONA ISENUPE
Ona isenupe-;ni o n tokasi iru idiwo ti o wa fun eemi ni gbigbe awon iro konsonanti jade.
Ona meje ni ona isenupe pin si,awon naa ni
Asenupe
Afunnupe
Aranmu
Arehon
Afegbe-enu-pe
Aseesetan.
IGBELEWON
Kin ni iro konsonanti?
Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti.
ASA
ORI-ORO IWA OMOLUABI ATI ANFAANI RE
AKOONU
Iwa omoluabi-;ni iwa rere ti o to ti o si ye ti eeyan n hu,ti o si farahan si gbogbo eniyan.
Omoluabi ni eni ti o ko gbogbo iwa rere po,ti egbe ati ogba ka si ojulowo eniyan nitori pe iwa rere leso eniyan.
Eyi ni awon iwa ti a fi n da omoluabi mo
Ikini-;omoluabi gbodo je eni ti o maa n ki eeyan yala aladuugbo,alabaagbetabi alabaasise po,laaro, losan an ati lale.
Iforiti-;omoluabi gbodo je eni ti o ni iforiti,nitori pe ko si eni ti o wa laye ti ko ni isoro tire, gege bi omoluabi o gbodo je eni ti o ni emi iforiti.
Iwa iteriba ati irele-;omoluabi gbodo je eni ti o ni iteriba ati owo fun gbogbo eniyan ti o ba ju won lo.
Igboran-;sise igboran je iwa omoluabi nitori eni ti a n ba wi ti ko gboran ki i se omoluabi.
Mimo iyi akoko;omoluabi gbodo je eni ti o mo iyi akoko. Ti o n se ohun ti o ye ni akoko ti o to.
Iwa irele ati suuru;omoluabi gbodo je eni ti o ni suuru ati irele ti kii gberaga,eyi ni yoo si je ki ibagbe re tu awon eeyan lara.
ANFAANI IWA OMOLUABI
- Iwa omoluabi maa n je ki a ba ojurere pade.
- O maa n je ki gbogbo eniyan feran iru eni bee.
- Gbogbo eeyan lo maa n sadura fun omoluabi.
IGBELEWON
1.Kin ni iro konsonanti?
b.Daruko abuda fun isapejuwe iro konsonanti.
2.Kin ni iwa omoluabi?
b.Daruko amuye iwa omoluabi marun-un ti o mo.
IWE AKATILEWA
Imo,Ede,Asa,Ati Litireso Yoruba .ss2.Adewoyin.S .Y o.i22-27.
ISE ASETILEWA
1.Iro konsonanti _______ lo wa ninu ede Yoruba [a[meji [b] mejila [d] mejidinlogun
2.Iro ______ ni a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.[a]ohun [b]konsonanti [d] faweli.
3._______ lo je ka mo iru iro konsonanti ti a pe [a[alafo tan-an-na [b[afase [d]ete.
4._____ ni a ti le huwa omoluabi [a[soosi [b] ile [d] ibi gbogbo
5.Ohun akoko ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka ni _____ [a]itan inu iwe naa [b]eko ti a ri ko [d]oruko iwe ti a fe ka.
APA KEJI
1.Daroko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti..
b.Salaye meji ninu won.
2.Daruko amuye iwa omoluabi merin.
b.Salaye meji ninu won.
.
OSE KEFA
ORI-ORO IRO- OHUN
ORIKI
ORISII
AKOONU
Iro-ohun-; ni lilo soke,lilo sodo tabi yiyo roketabi rodo ohun wa nigb ti ba n soro.
Ona meji ni iro ohun pin si
Iro-ohun geere
Iro –ohun eleyoo.
IRO-OHUN GEERE- eyi ni ki iro-ohun eniyan duro si ipo kannaa laini eyo rara.Iro-ohunlo je ka mo iyato oro kan ti won ni sipeli kan naa yato si ikeji.
Ona meta ni iro-ohun geere pin si
Iro-ohun oke
Iro-ohun aarin
Iro-ohun isale.
Iro-ohun oke-;eyi ni iro –ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun si oke.Iro-ohun yii naa ni a mo si “mi”.Ami re ni o lo si apa otun /
Ap
Wa
Gba
Mo
Iro-ohun aarin-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si aarin meji.Iro ohun yii ni a mo si “re”.iro-ohun yii ko ni ami ninu akoto.ap
Mo
Iro-ohun isale-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si isale.ami ni a mo si “do”.Ami re ni o lo si apa osi.ap ta
Ra
Gba
Ori faweli ati konsonanti aranmupe asesilebu ni a maa n fi ami ohun si.
Iro-ohun aarin-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si aarin meji.Ohun ni a mo si (re),iro ohun yii ko ni ami ninu akoto.ap
Gba
Mo
Iro-ohun eleyoo-;eyi ni iro-ohun ti o yo roke tabi rodo nigba ti a ba n soro
Ona meji ni iro-ohun eleyo pin si
Iro-ohun eleyooroke
Iro-ohun eleyoorodo
Iro-ohun eleyooroke-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa lati iro-ohun isale lo si iro-ohun oke.
Ami idamo re ni V.
ap yii, olopa.
Iro-ohun eleyoorodo-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa lati ohun oke lo si iro-ohun isale ami re ni^
ap-; yoo,naa.
A o lo awon ami wonyi mo lode-oni.
ASA
ISE ABINIBI ILE YORUBA.
Ise iran tabi ebi-;je ise idile ti a jogun ba ninu ebi wa.Awon idile miiran wa ti a ara ilu mo won bi eni mowo nitori ise awon idile naa,awon idile miiran je Olode,idile onilu,idile onisegun,onisowo abbl.
AKOONU : – Yoruba bo won ni ‘eni ti ko sise ko ye ki o jeun’.iyen nip e won gba pe eni kookan gbodo ni iselowo.Iran Yoruba lodi si iwa ole,kekere ni won si ti n ko awon omo ni ise abinibi. Ni kete ti won ba ti bimo saye ni awon obi re yoo ti da ifa akosejaye lati mo ise ti eleda yan fun omo naa.
Ise merin ni ise ti o wa ni ile Yoruba ni aye atijo pin si.Awon ni
- ise agbe.;-dida oko egan,oko etile
- Ise ode.: – ode igbe.ode etile, ode asode.
- Ise awo : – babalawo,asawosesegun
- Ise ona : – aso hihun ,eni hihun, aro dida, ilu lilu,epo fifo, gbenagbena,emu dida, irun didi, ikoko mimo, ati bee bee lo.
LITIRESO
ORI ORO-; OGBON ITOPINPIN LITIRESO.
AKOONU-;
Eyi ni awon koko to se Pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a ijoba yan,eyi ti a maa ka.
Ohun akoko ti a gbodo mo ni;
ORUKO IWE
Oruko onikowe,ibudo itan,itan ni soki,awon eda itan,ona isowolo-ede,eko ti a ri ko,asa Yoruba ati bee bee lo.
IGBELEWON
- Kin ni iro-ohun?
- Ona meloo ni iro-ohun pin si?
Salaye iro-ohun geere pelu apeere meji meji fun ikookan.
- kin ni ise abinibi?
- Daruko ise abi
- nibi merin ti o mo.
IWE AKATILEWA
Simplified Yoruba Language,Literature&Culture.S.Y. Adewoyin o.i 70-76-Adakedajo-iran kinni.
ISE ASETILEWA
- Ami ohun geere…….. io wa ninu ede Yoruba.(a) Meji (b) Meta (d) Merin
- Ori……… ni kan ni a maa n fi ami ohun si (a) Faweli (b) Konsonanti ati faweli(d) Faweli ati konsonanti aranmupe asesilebu.
- ‘Ifa akosejaye’ je ki a mo.(a) Ojo ibi omo (b) Iru ise ti omo naa yoo se (d) Oruko ti yoo je
- Ise abinibi ti o je ti gbogbo omo Yoruba ni……(a) Ilu lilu (b) Ode (d) Agbe
- ……..ni Kanmi ati Alade koko fi owo ran ti ole si gbe owo naa lo.(a) Ajadi (b) Adigun (d)Aremu
APA KEJI
- Kin ni ise abinibi?
- Daruko ise abinibi merin ti o mo.
- Daruko awon ohun ti o se pataki ti a ni lati moi nipa iwe ti a we
- Salaye meji ninu won.
OSE KEFA
ORI ORO-SILEBU NINU EDE YORUBA
-ORIKI
-IHUN
-BATANI
-ODO ATI APALA SILEBU
AKOONU
Odo silebu;ni apa to gbe se pataki julo ninu ihun silebu kookan.Iro faweli ati iro konsonanti aranmupe asesilebu ni o maa n sise gege bi odo silebu.
Awon iro odo silebu ni a maa n gbo ju ninu oro.
Ori odo silebu ni a maa n fi ami ohun si
Kan-an-n-pa ni odo silebu je ninu ihun silebu.
Ap
wa
gba
sun
Apaala silebu -;je iro konsonanti yato si konsonanti aranmupe asesilebu [m,n] ni o maa n sise gege bi apaala silebu.
ap
gbo
dun
ko
we
IHUN SILEBU [F1,KF ATI N] NINU ORO OLOPO SILEBU.
Orisiirisii ona ni a le gba se ihunpo silebu ninu oro olopo silebu.
ORO IHUN IYE SILEBU
Aso A/ so 2
f /kf
Bata ba / ta 2
Kf / kf
Igbale i/gba / le 3
F/ kf /kf
Alupupu A/lu/pu/pu 4
f/kf/kf/ kf
Konko ko/N/ko 3
Kf/N/kf
ASA
ORI-ORO-;AWON ISE ONA ABINIBI
AKOONU
Ise ona je okan lara awon ise abinibi ti o ti wa tipe ni ile Yoruba,ise ona pin si orisiirisii
Ise ona igi (agbegilere)
Ise ona okuta
Ise ona ogba finfin
Ise ona awo
Ise ona je ise ti o mu laakaye suuru ati ogbon atinuda dani,ise iran tabi idile ni
Igba finfin
Okan ninu ise ona ni igba finfin je,ni ilu Oyo ni o wopo si ju.Iran onirese lo ni igba finfin idi niyi ti won fi maa n paa lowe pe bi onirese o fingba mo,eyi to ti fin ko lee parun.
Ohun elo ise won ni Igba,abe,ada abbl.
IGBELEWON
1 Kin ni silebu?
- Daruko ihun silebu,salaye won pelu apeere mejimeji
- Daruko orisii ise ona abinibi merin ti o mo
IWE AKATILEWA
EKO EDE YORUBA TITUN SS1.
Oyebamiji Mustapha et al.o.i 35-37
ISE ASETILEWA
1 ……..ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekansoso.(a)Oro(b)Iro(d)Silebu
- Iran……..lo ni igba finfin(a)Onikoyi(b)Onigba(d)Onirese.
- Ise ode adedo ni……..pipa (a) Erin (b) Efon (d) Eja
- Ere gbigbe je apeere ise ona ……..(a) Awo (b) Agbegilere (d) Okuta.
- …….ni a maa n gbo ketekete ninu ihun silebu.(a) odo (b) Apaala (d) silebu iro.
APA KEJI
1.Kin ni silebu?
- Ge awon oro wonyi si silebu
Arogundade Alagbalugbu
Konkojabele
Ojikutu bara orun saaro
2.Salaye odo ati apala silebu pelu apeere.
OSE KEJE
ORI-ORO AKOTO EDE YORUBA
ITAN BI EDE YORUBA SE DI KIKO SILE
AKOONU
Ki owo eru to bere ni iwo oorun Afirika,asa iwe kika sajeji ni ile Yoruba,a kan n so ede Yoruba lenu lasan ni,ko si akosile.
Nigba ti owo eru bere opolopo omo Yoruba ni awon onisowo alawo funfun ko leru lo si ilu won.
Leyin opolopo odun ni won fi opin si owo eru yii gbogbo awon ti won ko leru ni won so di ominira ni ile saro(Freetown) ti won si bere igbe aye titun.
Leyin opin owo eru yii ajosepo si n tesiwaju laarin iwo oorun pelu awon alawo funfun ,won wa ra ohun elo fun ile-ise okowo won.Laarin akokoyii, awon alawo funfun gbagbo pe eniyan dudu ko ni esin pe abogibope ni won, idi niyi ti won fi mu esin kristieni wa fun wa,ti esin titun yoo ba si fese mule,odi dandan ki awon ajhinrere to mu esin wa gbe ni aarin awon eniyan ti won n waasu fun.
Idi niyi ti awon ijo Siemeesi ( C. M. S) fi ran awon alufaa ati awon oluko tele awon onisowo wa si ile Adulawo . ki ise ihinrere ba le lo daadaa,awon ajihinrere wonyii bere sii ko bi a se n so ede Yoruba.
Laarin awon ajihinrere wonyii ni,Koelle, John Rabban,Clapperton, Hannah Kilham,ati awon Yoruba to ti ile Saro de lati se agbateru bi ede se maa di kiko sile.
Orisiirisii igbimo ni won gbe kale lati jiroro lori ona ti o to lati ko ede, Samuel Ajayi Crowther naa je okan ninu won,Osi se gudugudu meje atiyaaya mefa,Oun ni o tumo Bibeli si ede Yoruba.
AYIPADA TI O DE BA KIKO EDE YORUBA SILE.
ILANA AKOTO ODE-ONI.
i.Awon igbimo to sise lori akoto ede Yoruba nip e gbogbo iro to se koko ni a gbodo ko sile.
- Ami ohun kansoso ni o gbodo duro fun iro to se koko kookan.
SIPELI FAWELI
Ni abe sipeli faweli ,won ni iro faweli ti a ba pe nikan ni ki a ko sile.
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Aiye aye
Eiye eye
Eiyele eyele
Pepeiye pepeye
Yio yoo
Won ni bi a ba se pe oro ni ki a maa ko o sile.ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Enia Eniyan /eeyan
Obirin obinrin
Okonrin okunrin
On oun
Kini kin-in-ni
Ikini ikinni
Fun u fun un
Kan a kan an
Gbon o gbon on
Sunmo o sunmo on
Faweli aranmupe ti a fa gun ,a gbodo ko o sile.
Agbodo fa iru si idi e ati o ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Eleja eleja
Aso aso
Ogbon ogbon
Omo omo
Owo owo
Oko oko
Iwe
Ni aye atijo ni a maa n lo ami faagun lati fihan pe a gbodo fa iru faweli bee gun sugbon bayii a gbodo fi ami ohun ti o ye sori silebu kookan.
Ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Ogun oogun
Orun oorun
Alafia alaafia
Egun eegun
Oloto oloooto
Papa paapaa
Dada daadaa
Karoojire kaaaro-o-o-jiire
Gan gan –an
Gbun gbun-un
Ofon ofon-on
SIPELI KONSONANTI
Iye iro konsonanti ti a b ape ninu oro ni a gbodo ko.Konsonanti meji ko gbodo jeyo ninu oro.
Ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Iddo ido
Offa ofa
Jebba Jeba
Ebutte metta Ebute meta
Ottun Otun
Shola Sola
Shaki Saki
Ogbomosho Ogbomoso
Shade Sade –
Ninu sipeli atijo ‘m’ ni a maa n ko sugbon bayii ‘n’ ni
Ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni o
Orombo oronbo bimbo Binbo
M bo N bo
Nyin Yin
Nwon Won
Enyin Eyin
Tinyin Ti yin
Yinka Yinnka
Ng n
Nrin n rin
Nje n je
Sipeli titun fun ohun
Tele ami ohun meji ni a maa n fi si ori oro kan (v )sugbon bayii,a gbodo fi ami ohun ti o ba ye sori oro kookan.
Ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Yi yii
Olopa olopaa
Akuse akusee
Miran miiran
Kowe kowee
Bayi bayii
Ore oore
Na naa
Ma maa
Ologbe oloogbe
IPIN ORO
Awon oro kan wa to ye ki a maa ko ni otooto sugbon ti a n ko papo.
Ap
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Nitoripe Nitori pe
Nigbati Nigba ti
Gegebi Gege bi
Biotilejepe bi o tile je pe
Bakannaa bakan naa.
Wipe wi pe
Nitoriti nitori ti
Gbagbo gba gbo
Jeki je ki
Peki pe ki
Ibiti ibi ti
Ki ije ki i je
Ki ise ki i se
Moo ko mo on ko
Dun u se dun un se
Ninu gbolohun to di oruko a maa n fi daasi sii
Ap
Ajagbe-mo-keferi
Owo-ni-faari
Imo-lokun-ola.
Won ni ki a ma lo ‘y’ dipo ‘h’.
Sipeli atijo Akoto ode-oni
Ehin Eyin
Ehin eyin
Irohin iroyin
Awun ahun
Onje ounje
Gbudo gbodo
Tuntun titun
IGBELEWON
Tun awon oro wonyii ko ni ilana akoto ti ode oni.
. nigbagbogbo
eyiti
igbawo
niwonigbati
2 .Bawo ni ede Yoruba se di kiko sile?
IWE AKATILEWA
ISE ASETILEWA
1.__________ ni o tumo bibeli si ede Yoruba
[a] Clapperton [b] Bishop Ajayi Crowther [d]Hannah Kilham.
2.Ibo ni won ko awon ti won so dominira lo? [a] ilu won [b]Afirika
[d] Freetown.
3.Akoto ode-oni fun “akeko “ ni [a] akeeko [b] akekoo [d]aakeko.
4.Shobanjo yoo di [a] Sobanjoo [b]Sobanjo [d] Sobanjo.
APA KEJI
1.Se atunse ti o ye lori akoto awon gbolohun
1.Shola nlo si ebutte-metta lola.
ii.Ng o sun lodo hyin.
iii.Enyin ni Shobande nbawi.
iv.Igbawo ni orombo maa dinwo.
v.Nkan ti mo ri ni iddo ya mi lenu.
2.Aiye yi fele pupo,oto ni iwwa ti won n hu ni otto,otto ni eyi ti won n hu ni iddo.
OSE KEJO
ORI-ORO ILANA ATI OGBON TI A N TA FUN AROKO KIKO
AKOONU
Itumo,
Orisiirisii Aroko
Aroko je ona ti a fi n mu eniyan ronu lori koko oro kan,ki o si ko ero re sile laifi atamo-mo-atamo..
ORISIIRISII AROKO.
Orisiirisii Aroko ni o wa ninu ede Yoruba,awon naa ni : –
Aroko oniroyin / asotan.
Aroko alapejuwe
Aroko onisorongbesi
Aroko ajemo-isipaya
Aroko alarinyanjiyan
Aroko leta kiko.
EROJA PATAKI FUN AROKO KIKO.
Eyi ni awon ohun ti o gbodo je akekoo logun,ti yoo fii je ki o le gbe aroko ti o gbamuse kale.
- Yiyan ori oro: – Akekoo gbodo yan ori-oro ti o ba mo nipa re daadaa.
- Sise ilapa ero : – Akekoo gbodo ronu jinle lori ori oro ti o yan,gbogbo ero ti o ba n wa si I ni okan ni yoo maa ko won sile,yoo maa tuna won koko wonyii to,ki aroko naa le wa ni sise-n tele.
- Koko ero : – Akekoo gbodo to awon koko ero re lona ti yoo fi je ise ti o fe ran –an.Ki gbogbo ero baa le hun mo ara won.
- Sise ilapa ero ; – Akekoo gbodo se ilapa ero fun ori-oro ti o bay an lati fihan pe o mo ohun ti o fe ko aroko le lori.
- Aarin : – koko kan ni o gbodo wa ninu ipin afo kookan bi akekoo ba sele ronu jinle to bee ni koko re yoo se po to.
- Igunle ; – Igunle aroko gbodo fa eeyan mora,o si gbodo je iso ni soki gbogbo ero aroko lati oke dele.
ASA
ORI-ORO ELEGBEJEGBE
ORIKI
ORISII
IPA TI WON N KO NI AWUJO
AKOONU
– Elegbejegbe ni egbe ti awon odo,agba ni okunrin tabi ni obinrin ti won je iro da sile ni agbegbe won fun igbega ilu ati ara won.
Ni aye atijo,iwonba ni ise ti ijoba maa n se fun awon ara ilu.igbega ati idagbasoke ilu tabi igberiko maa n waye pelu iranlowo awon elegbejegbe wonyii,apeere iru egbe bee ni aye atijo ni egbe ogboni.
Apapo awon agba ilu ti won to omo bii Aadota odun ni won maa n wo egbe ogboni.Ojuse egbe ogboni ni lati fun oba ni imoran.Won ni agbara lati da oba lekun tabi le oba kuro lori ite ti o ba si agbara lo.
Ni ode-oni,awon elegbejegbe po jantirere.Apeere won ni :-
Lion’s club
Rotary club
Majeeobaje
Oredegbe ati bee bee lo.
Ni ilu tabi ileto ti awon egbe wonyii ba wa,orisiirisii ise idagbasoke ni won maa n se bii : – tite tabi titun afara se.
- kiko ile ero kaakiri ibudoko.
IWULO ELEGBEJEGBE.
- Awon egbe ogboni maa n kopa ninu eto iselu awon baba-nla wa.
- Won maa n kopa ninu ise bii:- ona yiye,afara odo titun se,aafin oba kiko.
- Won maa n kopa ninu pipese owo ajemonu fun awon akekoo ile-iwe giga,pipese eko ofe fun awon akekoo ile-iwe girama,sisan owo idanwo iwe mewaa.
- Aaro kiko,owe bibe,eesu kikojo fun iranlowo egbe ati enikookan omo egbe.
LITIRESO
Kika iwe Ijapa Tiroko
IGBELEWON
Kin ni elegbejegbe?
Salaye iwulo elegbejegbe merin ti o mo.
2.Se agekuru itan ti o ka ninu iwe Ijapa Tiroko.
IWE AKATILEWA
IWE KIKA
- Y ADEWONYI,SIMPLIFIED YORUBA LANGUAGE CULTURE AND LITERATURE O.I 77-78
- IWE IGBARADI FUN IDANWO ASEKAGBA O.I.165
ISE AMURELE.
- ——– Ki I se ara erongba elegbejegbe. [a] ona yiye [b] afara tite [d] aibowofagba.
- Apeere elegbejegbe laye atijo ni ——- [a] egbe onimototo [b] egbe ogboni [d] rotary club.
- Awon egbe —— ni o maa n da oba lekun laye atijo ti o ba si agbara lo. [a] rotary club [b] lion’s club [d] ogboni.
- Elegbejegbe wa fun ——– ilu [a] idagbasoke [b] asorira [d] ayeye sise.
- won tun n ko ipa ribiribi nipa eto ——— [a] ile gbigbe [b] eko [d] oro-aje.
APA KEJI.
- Kin ni elegbejegbe?
- daruko apeere elegbejegbe ti a ni lode oni.
- salaye iwulo elegbejegbe.
OSE KESAN- AN
ORI-ORO -;AKANLO EDE
-ORIKI
-IWULO AKANLO EDE
– AKANLO EDE ATI ITUMO WON
Akoonu
Akanlo ede je ipede ti o kun fun ijinle oro eyi ti itumo re farasin pupo.
Isoro ni soki ni akanlo ede wa fun.
O si tun wulo pupo nigba ti a ba fe pe oro so, ti a ko fe ki gbogbo eniyan gbo nnkan ti a n so
Akanlo ede le je eyo oro kan pere apola tabi ki o je odidi gbolohun
ap
AKANLO-EDE ITUMO
o fori gbota o se konge aburu
o tele nibi ile gbe loju o si rin
o faraya o binu gan an
na papa bora salo
pa ni apafon pa ku patapata
pon omi sinu apere se asedanu
ara ile doko ajeji kan de
fi ara sin pamo
di baraku nnkan ti ko se e fi sile mo
gbe odo mi ko sinu wahala
se bi ose tii soju fi iya je ni
ko eti ikun fi gbogbo se akiigbo
ta atapinse tuka lo ni otooto
igi da nnkan ribiribi baje
gba odo mi bo sinu wahala
gbe itiju ta mu itiju kuro
pa ina oro mu oro ija wa sopin
ru igi oyin daran
fi iru fonna daran, fa ijangbon
okete boru nnkan b aje
ika kan ko woo nidii ipa ko kaa
owo re te eeku ida agbara wa lowo re
farasoko sa pamo
kolofin ibi ti o pamo
wo sokoto kan naa dijo fa ijangbon
so oju abe nikoo so otito oro laiparo
IGBELEWON
- Kin ni akanlo –ede?
2.Lo akanlo-ede mewaa ni gbolohun
ASA
ORI –ORO -; ASA IRANRA- ENI-LOWO
- ORIKI
- ORISIIRISII ONA TI AWON YORUBA N GBA RAN ARA WON
AKOONU
IRANRA-ENI-LOWO- – eyi ni o n tokasi ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowolaye atijo.
Orisii ona ti won n gba ran ara won lowo.
AKOONU: – Awon Yoruba gba pe ajeje owo kan ko gberu dori,won si gba pe ika ko dogba,idi niyi ti won fi maa n ran ara won lowo laye atijo.
Asa iranra-eni-lowo yii maa n mu ki ise nla ti o le gba enikan ni akoko di sise ni kiakia.Bakan naa,o n mu ki wahala dinku awon eniyan ti won n gbe ni agbegbe kan naa.
Orisii ona iranra-eni-lowo ; – Eyi ni ona ti awon babanla wa n gba ran ara won lowo laye atijo.
Aaro
Owe
Esusu
Ajo
Owo ele
San diedie
Fifi omo/nnkan ini duro
Gbami-o-ra-mi..
Awon odo ti won ba je ore,ti won ni agbara dogba,ti oko won si wa nitosi ara won ni won jo maa n se aaro,gbogbo won yoo pawopo se ise naa ni ojokan.
Bi won ti n pari ise enikan tan ni won yoo lo se ti enikeji titi ti won yoo fi se ise naa kari,ounje ki I se dandan sugbon eni ti aaro kan le wa nnkan jije ati mimu.Won maa n fi orin da ara won laraya ki ise le ya.
OWE : – Ni bibe opo eniyan bii ebi,ore,tabi ojulumo lati ba ni sise nla bii ile kiko,ise oko.A maa n da ojo owe ni,eni to be owe gbodo pese ounje ati nnkan mimu fun awon eniyan to be lowe.Ki I se dandan ni ki a san owe pada.
FIFI OMO TABI NNKAN INI DURO : – Bi eniyan ba ko si wahala tabi nilo owo,won maa n fi omo tabi nkan ini ti o niye lori duro lati ya owo.Igba ti iru eni bee ba to san-an tan ni yoo to gba nnkan-ki-nnkan ti o fi dogo pada.
OWO ELE KIKO/SOGUN DOGOJI : -Awon eeyan to ba wo wahala ni won maa n ko owo ele lati bo asiri ara won.Ilopo meji owo ti won ya ni won yoo san pada,idi niyi ti won fi n pe e ni sogun dogoji.
ESUSU/EESU: – Awon opo eniyan le maa ko owo pamo lati fe fi se nnkan gidi ni ojo iwaju.Eyi je ara ona ti a fi n gba lati fi ni owo lowo,ko si ere ninu eesu,iye ti eniyan bad a ni yoo ko.Won yoo yan olori ti yoo maa dari won.Bakan naa ni won yoo ti maa pade yala ni osoose tabi osoosu.
AJO : – Awon eeyan yoo maa da owo jo ni ojoojumo si owo akoko da,oun naa ni yoo se eto pinpin ajo ti osu ba pari.Gbogbo eni ti o bad a ajo ni yoo ko kari.
IGBELEWON.
1a. Kin ni asa iranra-eni-lowo?
2b. Salaye ona ti awon Yoruba ngba ran ara won lowo laye atijo.
IWE KIKA.
- Simplified Yoruba language literature and culture 0.i 79-81.
- Iwe igbaradi fun idanwo asekagba Yoruba 0.i.111-113,165-167.
- Exam focus Yoruba language 0.i 4-5.
ISE AMURELE
- ———– Ni ohun ti a ka to ye ni yekeyeke. [a] akaye [b] oro [d] gbolohun.
- Akaye maa n je ki a mo boya ———– [a] akekoo mo oro o pe daadaa. [b] ohun ti akekoo ka ye e daradara. [d] akekoo ri ohun ti onkowe ko.
- Dandan ni a maa n san ——– pada [a] owe [b] san diedie [d] aaro.
- gbogbo owo ti a ba da ni a maa ko ninu ——— [a] esusu [b] ajo [d] owo ele.
- Dandan ni pipese ounje ninu ——— [a] eesu [b] owe [d] aaro.
APA KEJI.
- Salaye orisiirisii ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo laye atijo.
- Kin ni iyato to wa laarin aaro ati owe?
2b. Daruko ona meji ti awon Yoruba fi n gba lati ko owe jo.
OSE KEWAA
ORI –ORO -;LILO AKANLO-EDE NI GBOLOHUN
AKOONU
Eyi ni lilo akanlo-ede ti a ti gbe yewo ni gbolohun lati fi itumo won han.
Gomina Raji Fasola se gudugudu meje yaaya mefa ni ipinle Eko.
Gbogbo ise ti Alaaja n se lati odun yii wa, ajadi apere lo n pa owo si.
Nigba ti okunrin naa da wahala sile tan ni o ba fie se fee.
Iya ibeji tuto soke osi fi oju gba a nigba ti o gbo pe omo re feraku.
Omi ti Sola bu fun baba agba ti sewon.
IGBELEWON
Lo akanlo-ede marun-un ni gbolohun.
ASA
ORI-ORO -;ASA IRANRA-ENI-LOWO
AKOONU
Owo ele
San die-die.
Fifi omo duro.
: – Ona ti awon Yoruba fi n ran ara won lowo.
Owo ele kiko
Awon eniyan ti won ba wo wahala ni won maa n ko owo ele lati bo asiri ara won.I lopo meji owo ti won baya ni won yoo san pada,idi niyi ti won fi n pe e ni sogun-dogoji.
Sandie-die / osomaalo : –
Eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san owo re die-die titi yoo fi tan.Oja bee le je nnkan elo ile tabi nnkan ini.Agidi ni osomaalo fi maa n gba owo won ni aye atijo.Won si wopo laarin awon ijesa.
Fifi omo tabi nnkan ini duro: –
Bi eniyan ba ko si wahala tabi nilo owo,won maa n fi omo tabi nnkan ini ti o niye lori duro lati ya owo.Igba ti iru eni bee ba to san owo ti o ya tan ni yoo to gba nnkan – ki –kan ti o ba fi dogo pada.
LITIRESO
Kika iwe litireso ti ijoba yan ‘Ijapa Tiroko’.
IGBELEWON.
- Salaye ona meta ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo.
IWE KIKA.
- Iwe imo ede.asa,ati litireso fun sekondiri agba.0.i 260.
- Sinplified Yoruba language literature and culture 0.i 77.
ISE AMURELE.
- Ija wa laarin——- [A] Kike ati Bolu [b] Kike ati Kunbi [d] Kunbi ati Bunmi.
- —– ni o wa jise fun Olu. [a] Desola [b] Kike [d] Bunmi.
- ——– ni Olu ro pe o ti fi ile oko sile. [a] Kunbi [b] Bunmi [d] Kike.
- Nigba wo ni eni ti o fi nnkan duro fi yawo to le ri nnkan naa gba? [a] nigba to ba ku. [b] nigba ti o b ape [d] nigba ti o ba san owo ti o ya pada.
- Osomaalo wopo laarin awon ——- [a] ijebu [b] ijesa [d] Ekiti.
APA KEJI.
- Se agekuru itan ti o ka ninu iwe Ijapa Tiroko.
- Daruko awon ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo.ki o si salaye meji ninu won.