FONOLOJI EDE YORUBA
OSE KINNI
AKORI EKO: FONOLOJI EDE YORUBA
Fonoloji ni imo eto amulo iro lapapo. Eko ti o je mo bi a se n to iro papo ninu oro ede Yoruba ti oro ede Yoruba si fi yori si gbolohun ede Yoruba ni a n pen i fonoloji.
Iro Faweli: Eyi ni awon iro ti a maa n gbe jade nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edo foro oo. Orisii iro faweli meji ni o wa ninu ede Yoruba, awon ni:
Iro faweli airanmupe: a, e, ȩ, i, o, ǫ, u
Iro faweli aranmupe: an, en, in, on, un
Iro Konsonanti ede Yoruba: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ş, t, w, y
Iro Ohun: orisii meta ni iro ohun ede Yoruba, awon ni:
- Iro ohun oke / (mi)
- Iro ohun aarin — (re)
- Iro ohun isale \ (do)
Apeere amulo iro ede Yoruba pelu ami ohun lori:
- Igbaale
- Agbalagba
- Omoboriola
Ise Asetilewa
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku. Ni ile Yoruba, ayeye isinku agba je ohun Pataki ti o fese mule ni awujo awon Yoruba paapaa ti o ba je agbalagba ti o fi owo rori ku.
Inawo ati ipalemo oku maa n po fun awon molebi ati ana oku. Gbogbo molebi oku ti o wan i irinajo ati ti itosi ni won gbodo peju pese si ibi isinku naa.
Igbese Isinku ni ilu Yoruba
- Itufo ikede
- Ile oku gbigbe
- Wiwe oku
- Oku tite
- Oku sinsin
- Igbalejo
Iranse olodumare ni iku je. Oun ni Adebola maa n ran lati mu eniyan ti akoko to da ba to lo si orun. Awon Yoruba gbagbo wipe gbese ni iku, ko si eda ti ko ni san-an. Won ni “Aye” ni oja orun ni ile. Irinajo ni awon Yoruba ka iku si. Idi niyi ti won fi maa n sin awon nkan jije, mimu aso ati bata mo oku agba ki o le ri nkan lo ni irinajo aye. Awon oba ni ile Yoruba tile maa n ni abobak ti yoo maa ran-an lowo ni ona orun.
Ise Asetilewa
- Eni ti ara san pa
- Eni ti o pokunsi
- Oku abuke
- Oku aboyun
- Oku onigbese