Onka Yoruba (101 – 300)

OSE KARUN – UN

EKA ISE:    EDE

AKOLE ISE:    Onka Yoruba (101 – 300)

Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.

 

Onka ni bi a se n siro nnkan ni ilana Yoruba.

 

Onka Yoruba lati ookanlelogorun-un de eedegbeta

ONKA FIGOONKA NI EDE YORUBA
101OOkanlelogorun-un
102Eejilelogorun-un
103Eetalelogorun-un
104Eerinlelogorun-un
105Aarundulaa-adofa
106Eerindinlaa-adofa
107Eetadinlaa-adofa
108Eejidinlaa-adofa
109Ookandinlaa – adofa
110Aadofa
111`Ookanlelaa-adofa
112Eejilelaa-adofa
113Eetalelaa-adofa
114Eerinlelaa-adofa
115Aarundinlogofa
116Eerindinlogofa
117Eetedinlogofa
118Eejidinlogofa
119Ookandinlogofa
120Ogofa
121Ookanlelogofa
122Eejilelogofa
123Eetalelogofa
124Eerunlelogofa
125Aarundinlaa-adoje 
126Eerundunlaa-adoje 
127Eetadunlaa-adoje
128Eejidunlaa-adoje
129Oookadinlaa- adooje 
130Aadoje 
131Ookanlelaa –adoje
132Eejilelaa-adoje
133Eetalelaa-adoje 
134Eerunlelaa-adoje 
135Aarundinlo-goje 
136Eerundinlogoje 
137Eetadiinlogoje 
138Eejidinlogoje 
140Ogoje 
141Okandinlogoje 
142Eejilelogoje 
143Eetalegoje 
144Eerunlelogoje 
145Aarundunlaa-adoje 
146Eerundinlaa-adoje 
147Eetadinlaa-adoje 
148Eejidinlaa-adoje 
149Ookandinlaa-adoje 
150Aadojo 
151Ookanlelaa-adojo 
152Eejilelaa-adojo `
153Eetalelaa-adojo 
154Eerunlelaa-adojo 
155Aarundinlogojo 
156Eerundinlogojo 
157Eetadinlogojo 
158Eejidinlogojo 
159Ookandinlogojo 
160Ogojo 
161Ookanlelogojo 
162Eejilelogojo 
163Eetalelogojo 
164Eerunlelogojo 
165Aarundinlaa-adosan-an
166Eerundinlaa-adosan-an 
167Eetadinlaa-adosan-an
168Eejidinlaa-adosan-an 
169Ookandinlaa-adosan-an 
170Aadosan-an 
171Ookanlelaa-adosan-an 
172Eejilelaa-adosan-an 
173Eetalelaa-adosan-an 
174Eerunlelaa-adosan-an 
175Aarundinlogosan-an 
176Eerundinlogosan-an 
177Eetadinlogosan –an 
178Eejidinlogosan-an 
179Ookandinlogosan-an 
180Ogosan-an 
181Ookanlelogosan-an 
181Ooknlelogosan-an
182Eejilelogosan-an 
183Eetalelogan-an 
184Eerunlelogosan-an 
185Aarundinlaa-adowaa
186Eerundunlaa-adowaa
187Eetadinlaa-adowaa
188Eejidinlaa-adowaa
189Ookandinlaa-adowaa 
190Aadowa/igba-o-din kewa 
191Ookanlelaa –adowa
192Eejilelaaa-adowa 
193Eetalelaa-adowa 
194Eerunlelaa-adowa 
195Aarundiin-nigba 
196Eerundin-nigba 
197Eetadin-nigba 
198Eejidin-nigba 
199Ookandin-nigba 
200Igba/ogowaa
201Igba ole-kan
202Igba ole-meji 
203Igba ole-meta  
204Igba ole-merin 
205Igba ole marun-un 
206Igba ole-mefa 
207Igba ole-meje 
208Igba ole-mejo 
209Igba ole-mesan-an 
210Igba ole-mewaa 
211Ookoolenigba-odun mesan (220-9)
212Okoolenigba-odun mejo (220-8) 
213Okoolenigba-odun meje (220-7)
214Okoolenigba-odun mefa (220-6)
215Okoolenigba-odun marun-un (220-5)
216Okoolenigba-odun merun (220-4)
217Okoolenigba –odun meta (220-3)
218Okoolenigba- odun meji (220-2)
219Okoolenigba-odin kan (220-1)
220Okoolenigba 
221Okoolenigba ole-kan 
222Okoolenigba ole-meji 
223Okoolenigba ole-meta 
224Okoolenigba ole- merin
225Okoolenigba ole-marun-un  
226Okoolenigba ole-mefa 
227Okoolenigba ole-meje 
228Okoolenigba ole-mejo 
229Okoolenigba ole-mesan-an 
230Okoolenigba ole-mewaa/ojilenigba odin mewaa
231Ojinlenigba odin-mesan-an 
232Ijilenigba odin-mejo
233Ojilenigba odin-meje 
234Ojilenigba odin- mefa  
235Ojilenigba odin -marun-un
236Ojilenigba odin-merin
237Ojilenigba odin-meta
238Ojilenigba odin-meji
239Ojilenigba odin-kan 
240Ojilenigba 
241Ojilenigba ole-kan 
242Ojilenigba ole-meji 
243Ojilenigba ole-meta 
244Ojilenigba ole-merin 
245Ojilenigba ole-marun-un
246Ojilenigba ole-mefa 
247 Ojilenigba ole-meje 
248 Ojilenigba ole-mejo 
249Ojilenigba ole-mesan-an 
250Ojilenigba odin-mesan-an 
252Otalenigba odin-mejo 
253Otalenigba odin- meje
254Otalenigba odin-mefa 
255Otalenigba odin-marun-un
256Otalenigba odin-merin 
257 Otalenigba odin- meta 
258Otalenigba odin-meji 
259Otalenigba odin-kan 
260Otalenigba 
261Otalenigba ole-kan 
262Otalenigba ole-meji
263Otalenigba ole-meta 
264Otalenigba ole-merin 
265Otalenigba ole-marun-un 
266Otalenigba ole-mefa 
267Otalenigba ole-meje
268Otalenigba ole-mejo 
269 Otalenigba ole-mesan-an 
270 Otalenigba ole-mewa/orulenigba odin-mewaa
271Orinlenigba odin-mesan-an 
272Orinlenigba odin-mejo 
273Orinlenigba odin-meje 
274Orinlenigba odin mefa  
275Orinlenigba odin-marun-un 
276Orinlenigba odin-merin
277Orinlenigba odin-meta 
278Orinlenigba odin-meji 
279Orinlenigba odin-kan 
280Orinlenigba
281Orinlenigba ole-kan 
282Orinlenigba ole-meji 
283Orinlenigba ole-meta 
284Orinlenigba ole-merin 
285Orinlenigba ole-marun-un 
286Orinlenigba ole-mefa 
287Orinlenigba ole-meje 
288Orinlenigba ole-mejo 
289Orinlenigba ole-mesan-an (280+10)
290Orinlelugba ole-mewaa/odunrin odin-mewaa (300-10)
291Odunrun odin mesan-an (300-9)
292Odunrin odin mejo (300-8)
293Odunrin odin meje 300-7)
294Odunrin odin mefa (300-6)
295Odunrun odin marun-un (300-5)
296Odunrun odin merin (300-4)
297Odunrun odin meta (300-3)
298Odunrun odin meji (300-2)
299Odunrun odin kan (300-1)
300Oodunrun 

 

Eka ise:- Asa 

Akole ise: ise akanse kan ni Awujo  Yoruba (project)

Gege bi a se salaye ninu idanilekoo ti o koja pe oniruru ise isenbaye/abinibi ni a n se ni ile Yoruba. 

Lara ise akanse ile awujo Yoruba ti a oo da wole ni sise ni ose yii ni ;

  1. Aro dida 
  2. Ikoko mimo 

 

Eka ise:- litreso 

Akole ise:- litreso alohun to je mo ayeye /kika iwe apileko ti ijoba fowo si.

Lara litreso alohun ti o je  mo ayeye ni, 

  1. Rara 
  2. Bolojo 
  3. Alamo 

 

Rara 

Rara je litreso atigbadegba lawujo Yoruba. A n lo o lati fi oba, ijoye, olowo, olola, gbajum han .

Awon obinrin ile to  mo atupale oriki oko daadaa maa n fi rara sisun pon oko le. Tokunrin tobinrin ni o n sun rara.  Ewi yii wopo ni agbegbe Iseyin, Ogbomoso, Ede, Ikirun, Ibadan.  Apeere, 

            Akanni o 

            Omo lofamojo    

            Omo ola lomi 

            Kekere olowo oko mi o 

            T ‘ori’ lukuluku 

            B ‘emo eebo

Bolojo 

A n ko orin bolojo lati fi se  aponle, tu asiri, se efe, soro nipa oro ilu, oro aje, ki eniyan to n se rere ati lati dekun iwa aito. 

Awon okunrin yewa ni o saba maa n ko orin bolojo. A n ko orin bolojo ni ibi ayeye igbeyawo isomoloruko, oye jije, isile abbl. Apeere 

    Bo sale e wa ba mi lale

    Bo si je koro wa ba mi o jare 

    Bo sale e wa ba mi lale 

    Ohun o ba fi mi se 

    Gbogbo aye ni n o ro o fun 

 

Alamo 

Won n salamo lati bu eniyan ti n huwa ibaje bee ni won n loo lati ki eni to ba n nawo fun won ni bi ayeye.

Ewi yii gbajumo laarin awon ekiti. Awon obinrin ni o maa n salamo pelu eka ede ekiti.

Igbelewon :

  • Kin ni onka?
  • Ka onka lati 101-300
  • Mu ise akanse kan ni awujo ki o si salaye lekun un rere
  • Daruko awon litireso alohun ajemayeye ki o si salaye

Ise asetilewa: mu okan lara ise akanse ile Yoruba wonyi ki o fi se ise se:

  1. Ikoko mimo
  2. Eni hihun