Atunyewo Asa Iranra-eni-lowo.

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Second Term

 

Week : Week 7

 

Topic :

 

EDE: Akaye Oloro Geere.

ASA: Atunyewo Asa Iranra-eni-lowo.

LIT: Kika iwe apileko ti ijoba yan.

 

OSE KEJE

AKAYE 1

(Ka akaye yii ki o si dahun ibeere ti o tele)

Ojo ko ti awon eegun yoo pidan ni ita Oba. Oba ati awon ijoye ati gbogbo awon ero ti pese wamuwamu si aaye won. Bee ni olukuluku awon eegun nla n ta okiti, won le awon eegun keekeeeke lese wa si ojude Oba. Ariwo n ta gee bee ni kaluku ti n lo juba niwaju Oba ki won to lo jokoo laaye won. Eyi ti o ba de keyin a si juba awon ti o ba niwaju ki o to jokoo. Sugbon okan ganta bayi de, se ni o lo jokoo ni tire leyin ti o ti ki Oba tan, ko tile naani awon ti o ba niwaju rara. Awon naa si kan oro re sinu. Won ni awon yoo maa wo ibi ti yoo ruu wo.

Bi ilu ti n dahun kikankikan ni awon eegun n bo sijo nikookan ti won si n jo bi arira. Eegun oyaju yii kan n yan finafina kiri ni lai beru ohun ti awon yooku le fi oun se.

  1. Kin ni o mu Oba ati awon ijoye ti won fi pese wamuwamu ni ita Oba? A. Oba fe fi eniyan joye B. awon ode fe sun ijala fun Oba. D. awon eegun fe pidan fun Oba E. oba fe se Igbeyawo fun omo re.
  2. Iru iwa wo ni eegun ti o de gbeyin hu si awon elegbe re? A. iwa aladaje B. iwa ika D. iwa odaju E. iwa igberaga
  3. Ki ni awon eegun so nipa eegun ti o de gbeyin? A. won ni awon yoo wo ibi ti yoo ru wo B. won ni awon yoo le kuro laarin won D. won ni awon yoo rojo re fun Alagbaa E. won ni awon yoo rojo re fun Oba
  4. Ohun ti awon eegun koko n se nigba ti won de ita Oba ni pe won ……. A. n pesa fun Oba B. juba fun Oba D. juba fun arawon E. n juba fun awon obi won.
  5. Itumo ‘naani’ gege bi a ti loo ninu ayoka yii ni ……. A. ibinu B. aibikita D. ainilaari E. idunnu

AKAYE 2

Ka ayoka yii ki o si ahun ibeere ti o tele e.

Eniitan je omobibi ilu Oloruntowoju ni ipinle Ogun. Ibanuje to subu lu ayo lo fa sababi oruko ti iya baba re so o yii. Sebi Yoruba bo, won ni: “bi ko ba ni idi, obinrin kii je Kumolu”. Ojo keta ti Ayoke ti i se iya re bi i ni o ki aye pe “O digba o se”.

Bi o tile je pe baba re Alabi se alaisi ninu ijanba oko nigba ti oyun re wa ni osu marun-un. Abeni to je iya baba Eniitan ti le ni aadorin odun ni akoko ti awon obi re fi jade laye sugbon O gbagbo wi pe oju Olorun lo n banii woo mo gege bi oruko ilu wọn. [mediator_tech]

Abeni sa gbogbo ipa re pelu iranlowo Olorun lati ri i pe Eniitan kawe lati alakoobere titi de Ifafiti. Ni ikeyin, Eniitan di Oloselu ati onisowo pataki ni iseju aye re.

IBEERE:

  1. Eniitan je omo ipinle —— A. Oyo B.Ogun C. Osun D.Kwara E. Ondo
  2. “O digba o se” ninu ayoka yii tumo si ki eniyan —– A. sun B.yari C. ku D. ja E.juwo
  3. Bba Eniitan ku ninu ijanba—— A.oko B.omi C. ina D.ile E. okada
  4. —— lo gba pe oju Olorun lo n bani wo mo. A. Abeni B. Ayoke C. Alabi D. Ajiun E. Alani
  5. Eniitan di —– ni isoju aye Abeni. A. Dokita B. Agbejoro C. Oluko D. Awako E.Oloselu

IGBELEWON

  1. Ki ni aroko?
  2. Ki ni aroko onioroyin?
  3. Ko aroko lori ijamba moto ti o se oju re.

AKORI ISE: ASA IRANRA – ENI – LOWO.

Asa iranra – eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo tabi ki a so pe asa iranra eni – lowo ni ona ti awon Yoruba maa n gba soore fun arawon. Orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo. Die lara won ni: (i) Aaro (ii) Ebese (iii) Esusu abbbl

Esusu:-Eleyii ni i se pelu owo. Won maa n da owo yii ni. Won maa n ni eni ti yoo maa gba owo yii laarin arawon. Eni ti o n gba owo yii maa gba owo naa kaakiri lodo awon eniyan (omo egbe). Bi won ba ti n da owo yii ni won maa ko si ara iganna/ogiri (wall) won o maa fa igi kookan si ara iganna, igi yii ni iye ti o duro fun.

Ajo:- Ajo naa dabi esusu ni, won maa n da owo fun olori alajo. O ni iye owo ti eniyan yoo maa da bi agbara eeyan ba se to. Iyato to wa laarin esusu ati ajo ni wi pe gbogbo iye ti eniyan ba da ni eeyan yoo ko nibi esusu sugbon nibi ajo eeyan yoo ko ida kan sile fun olori alajo.

Egbe alafowosowopo: egbe alafowosowopo naa ni won n pe ni egbe alajeseku. Egbe yii wopo wa laarin iyaloja,osise ijoba abbl. Won maa n ni oloye laarin won bi akowe, akapo, ayewe owo wo.ki a ranti wi pe awon egbe yii maa n ni eto ati ofin lati odo ijoba. Eyikeyi ninu omo egbe ni o ni anfaani lati ya owo nibe.

IGBELEWON

  1. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  2. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?.

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ 

1 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe University Press Nig

2 Oyebamji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S2 ) oju iwe 136-146 University Press Nig.

LITIRESO

Kika iwe apileko ti ijoba yan.

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni aroko?
  2. Ki ni aroko onioroyin?
  3. Ko aroko lori ijamba moto ti o se oju re.
  4. Ko ona meta ti awon Yoruba maa n gba ran ara won lowo.
  5. iyato wo lo wa laarin esusu ati ajo?
  6. ya ate faweli airanmupe.

ISE ASETILEWA

  1. Wiwa koto si eyin odi lati dena ogun jija ni …… A. lilo alami B. wiwa yara D. tituuba
  2. Ewo ni ki I se ona ti a n gba dena ogun A. wiwa yara B. tituuba D. idobale
  3. Alore ni …………. Ilu. A. ami B. oluso D. eso
  4. Ori oro wo lo je mo aroko asotan ju nihin-in? A. eto ikaniyan B. bi mo se lo isinmi ti o koja D. olowo lagba.
  5. …………. le je oro fun aroko asotan tabi oniroyin. A. omokunrin wulo ju omobinrin lo B. ile eko mi D. asiko ijoba iselu awarawa E. ojo ibi mi ti o koja

APA KEJI

  1. Ko apeere ori oro aroko oniroyin
  2. Ko ona ti a n gba ogun sile

[mediator_tech]

 

Third Term SS 1 Lesson Notes Yoruba

 

THIRD TERM EXAMINATION FOR PRIMARY SCHOOLS PRIMARY 1 TO PRIMARY 6 YORUBA

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share