Àṣà ikinni ni ile Yorùbá
Ikinni jẹ ọna ti a fí kó ọmọdé ni eko ilé. Bí ọmọdé bàa jí ni owuro, ó gbọ́dọ̀ mo bí a ṣe nki bàbà tàbí ìyá rẹ, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá ju lọ.
Ọmọ ọkùnrin yio dobale bẹẹ si ni ọmọ obìnrin yio wa ni ori ikunle
Àwọn ọ̀nà tí a ngba láti kí ara wa ni ile Yoruba
1. Ní àkókò
2. Ní ìgbà
3. Ní irú ipò tí a bá wà tàbí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lowo sì òní tòun
4. Bí a ṣe nki òní ìṣe owó àti bí a tin fà wọn lóhùn
5. Bí a ṣe nki ọba tàbí ìjòyè ilu
Ní àkókò : ni dédé agogo méje aro sì agogo mokanla abo ni Yoruba nki ara wọn báyìí…. Ẹ karo oooo
Ní dẹ́de agogo méjìlá sì àgó merin osan ni Yoruba má nki ara wọn báyìí wípé…. E ka san ooooooo
Ní dẹ́de ago merin ìrólé sì àgó mefa abo… E ku ìrólé oooooo