Ò̩SÈ̩ KIINI
AKOONU ISE
1 EDÉ, ÀSA ATI LITIRESO:s
Agbeyewo idanwo taamu to koja; idahun si awon ibeere.
2. ÈDÈ:
Òǹkà láti e̩gbe̩rún me̩waa titi de e̩gbàáwàá (10,000-20,000).
LITIRESO: Kika iwe litireso ti a yan fun taamu yii:- Agbeyewo oro akoso Onkowe, ohun ti itan naa da lori.
ÀKÓÓNU IS̩É̩
ÒǸKÀ LÁTI E̩GBE̩RÚN ME̩WAA TITI DE E̩GBÀÁWÀÁ (10,000-20,000)
10,000 – E̩gbàárùn-ún ———– 2000 x 5
11,000 – È̩é̩dé̩gbàafà ———— 2000 x 6-1000
12,000 – E̩gbàafà ————— 2000 x 6
13,000 – È̩é̩dé̩gbàaje ———– 2000 x 7-1000
14,000 – E̩gbàaje ————– 2000 x 7
15,000 – È̩é̩dé̩gbàajo̩ ———- 2000 x 8-1000
16,000 – E̩gbàajo̩ ————– 2000 x 8
17,000 – È̩é̩degbàasàn-án ——- 2000 x 9-1000
18,000 – E̩gbàasàn-án ——– 2000 x 9
19,000 – È̩é̩dè̩gbàawá ——– 2000 x 10-1000
20,000 – E̩gbàawàá (tàbí ò̩ké̩ kan) 2000 x 10
ÀKÍYÈSÍ
20 – Okòó
40 – Òjì
60 – Ò̩ta
80 – Ò̩rin
ÌGBÉLÉWÒ̩N:
1. Nó̩ḿbà wo ló dúró fún òǹkà Yorùbá yìí: e̩gbàajo̩?
A. 15,000
B. 19,000
D. 16,000
E. 8,000
2. Èwo nínú àwo̩n wò̩nyí ló dúró fún òjìlélé̩gbàarin ó dín méjì?
A. 3088
B. 8038
D. 3038
E. 8380
IS̩É̩ ÀKÀNS̩E
Ko̩ àwo̩n nó̩ḿbà wò̩nyí ní òǹkà Yorùbá:
4,020
10,040
8,080
6,190
18,080
LITIRESO: Kika iwe litires̩ò̩ ti a yan fun taamu yii:- Agbeyè̩wò oro akoso Onkowe, ohun ti itan naa da lori.
About The Author
Edu Delight Tutors
Am a dedicated educator with a passion for learning and a keen interest in technology. I believe that technology can revolutionize education and am committed to creating an online hub of knowledge, inspiration, and growth for both educators and students. Welcome to Edu Delight Tutors, where learning knows no boundaries.