JSS 1 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA
ILANA ISE FUN SAA KETA OLODUN KIN-IN-NI (JSSONE)
OSE KIN-IN-NI: ATUNYEWO ISE SAA KEJI
OSE KEJI: EDE: LETA KIKO
ASA: AWON ISE ISEMBAYE ILE YORUBA
OSE KETA: LITIRESO: ASAYAN IWE TI IJOBA YAN
ASA: ISE AGBE
OSE KERIN: EDE: ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN
ASA: ISE ILU LILU
OSE KARUN-UN: EDE: IHUN GBOLOHUN ABODE ATI ATUPALE
GBOLOHUN ABODE
OSE KEFA: ASA: IGBESE TI AGBE YOO GBE KI IRE OKO TO JADE
OSE KEJE: EDE: IHUN GBOLOHUN OLOPO ORO ISE ATI ATUPALE
GBOLOHUN OLOPO ORO ISE
OSE KEJO: ASA: ASA IRAN-RA-ENI LOWO LAWUJO YORUBA
OSE KESAN –AN: ASA: IWA OMOLUABI
OSE KIN-IN NI
ATUNYEWO ISE SAA KEJI
EKA ISE: EDE
ORI ORO: AROKO ATONISONA ONIROYIN (NARRATIVE ESSAY)
Aroko oniroyin je aroko ti o je mo iroyin sise.
AWON IGBESE TI A NI LATI TELE TI A BA N KO AROKO ONIROYIN
- Mimu ori oro ti a fe ko oro le
- Kiko koko ohun ti a fe soro le lori leseese ni ipin afo kookan (in paragraph)
Apeere ori oro aroko oniroyin :
- Ijamba oko kan ti o sele loju mi
- Ayeye isile kan ti won se ni adugbo mi.
- Ere onile-ji-le ti o koja ni ile iwe mi.
IGBELEWON:
- Fun aroko oniroyin loriki
- Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ko aroko oniroyin
- Awon ori oro wo ni o jemo aroko oniroyin
ISE ASETILEWA:
- Simplified Yoruba L1 work book for JSS one. Page 26-27
EKA ISE: ASA
ORI ORO: OGE SISE NI ILE YORUBA(FASHION)
Oge sise je asa imototo ati sise ara losoo
Awon ona ti a n gba se oge laye atijo ati lode-oni
- Aso wiwo
- Iwe wiwe
- Laali lile
- Tiroo lile
- Osun kikun
- Ila kiko
- Itoju irun ori
- Lilo ohun eso lorisirisi
PATAKI OGE SISE
- O n je ki ara eniyan mo toni-toni
- O n le aisan jinna si eniyan
- Ko ki i je ki ara wo ni
- O n bu ewa kun ni
- Tiroo lile maa n ti idoti oju kuro
IGBELEWON:
- Kin ni oge sise?
- Ko awon ona ti Yoruba n gba se oge laye atijo
- N je oge sise se Pataki ni ile Yoruba? Ko Pataki oge sise merin
ISE ASETILEWA:
- Gege bi i akekoo, n je o se Pataki lati toju ara ki o to wa si ile iwe? Salaye Pataki oge sise.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: ORIN IBILE TO JEMO PIPA OGO OBINRIN MO,
ASA IGBEYAWO,ISE AGBE
Orin to je mo asa igbeyawo:
Baba mo mi lo
Fadura sin mi o
Iya mo mi lo
Fadura sin mi o
Kin maa ke’su
Kin maa ka’gbako nile oko
Kin maa ke’su
Kin maa ka’gbako nile oko
Baba mo mi lo
Iya mo mi lo
E fadura sin mi [mediator_tech]
Orin to je mo pipa ogo obinrin mo:
Ibaale
Ibaale o!
Ibaale logo obinrin
Ibaale o!
Olomoge,
Pa ara re mo
Pa ara re mo o!
Ibaale logo obinrin
Ibaale o
Orin ibile to jemo ise Agbe:
Ise Agbe ni’se ile wa
Eni ko sise
A maa jale
Iwe kiko
Lai si oko ati ada
Ko I pe o!
Rara
Koi pe o!
IGBELEWON:
- Fun oge sise ni oriki
- Ko ona marun-un ti Yoruba n gba soge laye atijo
- Ko orin ibile ti o je mo pipa ogo obinrin mo,ise agbe ati asa igbeyawo
ISE ASETILEWA:
- Ko orin ibile kan ti o je mo Eto Eko.
OSE KEJI
EKA ISE: EDE
ORI ORO: LETA KIKO
Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran
ORISI LETA
- Leta gbefe
- Leta Aigbefe
AWON IYATO TI O WA LAARIN LETA GBEFE ATI LETA AIGBEFE
LETA GBEFE | LETA AIGBEFE |
O je leta ti a n ko si baba,iya Egbon, aburo ati ojulumo | O je leta ti a n ko si awon eniyan ti o wa ni ipo giga tabi oga ileese |
Adireesi kan ni o maa n ni | Adireesi meji ni o n ni |
Ko nilo ori oro(Topic) | Ori oro pondondan ninu leta yii |
O fi aye sile fun awada tabi efe sise
| Kos i aaye fun awada tabi efe |
Ifamisi oruko akoleta ko pondandan ninu leta gbefe | Ifamisi oruko akoleta pondandan |
Oruko akoleta nikan ni o se Pataki ni ikini ipari | Oruko akoleta ni kikun(With surname) se Pataki labe ifamisi oruko |
[mediator_tech]
IGBELEWON:
- Kin ni leta?
- Ona meloo ni leta pin si?
- Ko iyato marun-un laarin irufe leta ti o wa
ISE ASETILEWA:
- Ko leta si baba re lati wa san owo ile-iwe re ki awon alase eto eko ma a ba di o lowo ise ni ile iwe.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: AWON ISE ISEMBAYE ILE YORUBA
Ise isembaye je ise ti a jogun ba lati iran kan de iran miiran ti a si n ko won bi a ti n dagba
Awon ise isembaye Yoruba ni wonyi;
- Ise Agbe
- Ilu lilu
- Ikoko mimo
- eni hihun
- aro dida
- Ise ode
- Ise onidiri
- Ise akope
- Ise Alagbede
- Ise ona bii;
- Ona igi
- Ona okuta
- Ona awo abbl
IGBELEWON:
- Fun ise isembaye loriki
- Ko ise isembaye meje
ISE ASETILEWA:
- Ise isembaye wo ni e jogun ba ninu ebi yii? Salaye lekun-un rere.
OSE KEJI
EKA ISE: LITIRESO
Kika iwe asayan ti ijoba yan fun saa yii
Ayoka Ewi YORUBA LAKKOOTUN
IGBELEWON:
Ninu ewi yorruba Lakotun ko eko marun-un ti ewi naa ko e gege bii akeekoo
ISE ASETILEWA:
- Ko eko marun ti imele akekoo ko e gege bi I akekoo
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISE AGBE
Ise Agbe je kiko ati mimo nipa oko riro tabi dida
Ise Agbe je ise akoko se eda,gege bi a se ri I ninu Bibeli ninu iwe Genesiisi ori kin in ni ese .
Awon to n pese ohun elo ti a n je ni a n pen i AGBE
OHUN ELO ISE AGBE NI AYE ATIJO ATI NI ODE ONI
- Oko
- Ada
- Aake
- Obe
- Ero irole tabi iko ebe
- Ero ktakata
- Oogun ajile abbl
ORISI AGBE TI O WA
- AGBE ALAROJE: Iwonba oko fun atije ebi ni agbe alaroje maa n da.Awon ohun ogbin bii; isu ogede,agbado, ata,ati ewebe ni won maa n gbin. Ni gba miiran ti o ba seku ni won maa n ta loja
- AGBE ALADA-N-LA/OLOKO N-LA: Awon wonyi ni won n fi ise agbe se ise loju mejeeji.won a maa da oko nla bii; oko koko,oko roba,oko agbo,oko owu,oko obi,oko ope oyinbo,oko anamo,oko egusi abbl.
Agbe alada-n-la pin si ona meji.Awon niyi;
- Agbe olohun ogbin: Awon ni o n gbin gbogbo ounje ti a n je kaari aye
- Agbe olohun osin: Awon Agbe wonyi lo n sin oniruuru ohun osin bii; Aja,Ewure, Elede, Adiye, Ehoro, Oya, Eja, Igbin, Oyin abbl
IGBELEWON:
- Fun ise Agbe ni oriki
- Orisi agbe meloo ni o wa?
- Salaye orisi agbe lekun un rere
- Daruko awon ohun elo ise agbe laye atijo ati lode-oni
ISE ASETILEWA:
Ko ohun elo ise agbe laye atijo ati lode oni marun-un
OSE KERIN- IN
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN
Oro ise ni koko fonran to n toka isele tabi nnkan ti oluwa n se ninu gbolohun
Oro ise ni opomulero gbolohun.Lai si oro ise ninu gbolohun, gbolohun ko le ni itumo
ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN
- O maa n toka isele inu gbolohun laaarin oluwa ati abo(oro ise kikun). Apeere;
- Iyabo je isu
- Adufe ka iwe
- Ige pa ejo
- Kii gba abo ninu gbolohun.( oro miiran kii jeyo leyin oro ise) Apeere;
- Yemi sun
- Toju kawe
- Olu da?
- Olorun wa abbl
- O maa n gba abo ninu gbolohun(oro miiran le jeyo leyin oro ise). Apeere;
- Aja gbe eran
- Kehinde ra keke
- Layemi ge igi
- O maa n sise akanpo: eyi ni akanpo oro ise ati aro oruko ti o bere pelu faweli (ipaje a maa waye).Apeere;
- Se + ere = sere
- Je+ isu = jesu
- Gun+ iyan = gunyan
- Ko + orin = korin
IGBELEWON:
- Kin ni oro ise?
- N je loooto ni pe oro ise se Pataki ninu gbolohun
- Salaye ise ti oro ise n se ninu gbolohun
ISE ASETILEWA:
- Ko gbolohun kikun marun-un ki o si fa ila si oro ise inu re
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ISE ILU LILU
- Itan so pe eniyan ni Ayan ni igba aye re
- Oruko abiso re ni “Kusanrin Ayan “
- Itan so pe oun ni eni akoko ti o koko lu ilu ni ile Yoruba
- Ile Barapa ni o ti wa
- Leyin iku re ni awon onilu egbe re so o di Orisa
- Ise ilu lilu ni a n pen i “Ise Ayan”
- Awon ti o n fi ilu se ise se ni a n pen i “Alayan”
- Ise ilu lilu je ise àti rán-dé-ìran. [mediator_tech]
ORISI ILU TI A N LU NI ILE YORUBA:
- Ilu Bata
- Ilu Benbe
- Ilu Gbedu
- Ilu Dundun
- Ilu Igbin
- Ilu Agere
- Ilu Gongo
IWULO ILU LILU:
- O wa fun idaraya ati faaji
- A n lu ilu nibi inawo bii; igbeyawo,ikomojade,isinku agba,oye jije,isile,odun ibile lorisirisi
- A n lo ilu lati fi tufo oku oba,oku ijoye,oku agba,oku awon olorisa
- A n lo ilu lati fi ye awon oba ati ijoye ilu si
- A n lo ilu ni ile ijosin lati fi yin Olodumare,ile iwe,ibi apejo oloselu abbl
IGBELEWON:
- So itan soki nipa ilu lilu ni ile Yoruba
- Ko orisi ilu marun-un ni ile Yoruba
- Ko iwulo ilu ni awujo Yoruba
ISE ASETILEWA:
Ko iwulo ilu lilu meta pere ni ile ijosin.
OSE KARUN-UN
EKA ISE: EDE
ORI ORO: IHUN GBOLOHUN ABODE ATI ATUPALE GBOLOHUN ABODE
Gbolohun ni akojopo oro ti o ni oro ise ati ise yi o n je ninu ipede
Gbolohun ni olori iso
GBOLOHUN ABODE/ELEYO-ORO ISE
Gbolohun abode tabi eleyo oro ise je gbolohun ti kii gun ti ko si ni ju eyo oro ise kan lo. Apeere;
- Ade je iresi
- Adufe fe iyawo
- Sade mu omi
IHUN GBOLOHUN ABODE/ELEYO ORO ISE
- O le je oro ise nikan. Apeere; jade,joko,dide lo
- O le je oluwa,oro ise kan ati oro aponle.apeere;
- Baba sun fonfon
- Ile ga gogoro
- O le je oluwa,oro ise kan ati abo.apeere
- Anike je ewa
- Ige gba ise
- Yemi ka iwe
- O le je oluwa,oro ise kan,abo ati apola atokun.apeere;
- Tunde ra keke ni ana
- Subomi ta aso ni oja
- Bimpe da omi si ile
- O le je oluwa,oro ise kan ati apola atokun.apeere
- Mo lo si odo
- Abiola lo si oja abbl
IGBELEWON:
- Fun gbolohun abode ni oriki
- Oruko miiran won i a le pe gbolohun abode
- Salaye ihun gbolohun abode pelu apeere
ISE ASETILEWA:
Ko gbolohun abode marun-un ki o si fa ila si oro ise inu re.
OSE KEFA
EKA ISE: ASA
ORI ORO: AWON IGBESE TI AGBE YOO GBE KI IRE OKO TO JADE
Awon to n fi ise oko riro se ise ati bi a se n toju ohun osin ni a n pen i “Agbe”
Awon igbese naa leseese ni yi:
- Awon agbe ni lati se itoju oko won loore-koore nipa lilo ero irole,katakataata,iko ebe
- Won gbodo se amulo oogun ajile(fertilizer)
- Rira irugbin ti o ba asiko ogbin mu
- Awon agbe olohun osin gbodo koi le fun ohun osin won
- Ayika ohun osin gbodo mo toni-toni
- Ounje amaradan ati amara-dagba lore-koore fun awon ohun osin
- Ayewo ara ni gbogbo igba fun awon ohun osin
PATAKI /ANFAANI ISE AGBE LAWUJO
- Awon agbe lo n pese ounje lawujo
- Ise agbe n pese ise fun ogunlogo eniyan lawujo
- O n pese ohun elo ise fun awon ile ise gbogbo bii;awon to n se iwe, won ile ise ona igi abbl
- Ise agbe n pese owo si apo ijoba nitori pupo awon ohun ogbin ni ile yii ni a n fi sowo si oke okun bii; koko
IGBELEWON:
- Awon won ni Agbe?
- Ona meloo ni a le pin awon agbe si?
- So igbese ti agbe ni lati gbe ki ire oko to jade
- Ko Pataki ise agbe merin ni awujo wa
ISE ASETILEWA:
- N je loooto nipe awon agbe se Pataki ni awujo? Ko koko marun un lati gbe idahun re lese.
OSE KEJE
EKA ISE: EDE
ORI ORO: IHUN GBOLOHUN OLOPO ORO ISE ATI ITUPALE RE
Gbolohun olopo oro ise ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.oruko miiran fun gbolohun yii ni ‘gbolohun onibo’
Gbolohun onibo pin si ona meta.awon niyi;
- Gbolohun onibo asaponle
- Gbolohun onibo asapejuwe
- Gbolohun onibo asodoruko
GBOLOHUN ONIBO ASAPONLE
Eyi ni gbolohun ti a fi n se aponle oro ninu gbolohun nipa lilo atoka “ti” tabi “bi”. Apeere ;
- Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere
- Ti awon ode ba fon fere awon ole yoo sa
- Awon akekoo yoo se aseyori bi awon oluko ba ko omo daadaa
- Ti awon oluko ba ko omo daadaa,awon akeekoo yoo se aseyori.
GBOLOHUN ONIBO ASAPEJUWE
Inu apola oruko ni gbolohun yii maa n wa(eyi ni oro oruko kan soso pelu isori oro oruko miiran). Atoka ‘ti’ ni a n lo.
- Ile ti Ola n gbe dara
- Tuned ra aso ti o ni awo ewe
- Oko ti oluko ra rewa
GBOLHUN ONIBO ASODORUKO
Atoka gbolohun yin ii “pe”. Atokka yii maa n yipada di oro oruko ninu gbolohun.Apeere;
- Pe o o le jale o dun mi pupo
- O dara pe o gbegba-o-roke ninu idanwob asekagba.
- O dara pe o ri ise si ile-epo abbl.
IGBELEWON:
- Kin ni gbolohun olopo oro ise
- Ona meloo ni o pin sii?
- Salaye orisi gbolohun olopo oro ise
- Ko apeere gbolohun olopo oro ise
ISE ASETILEWA:
- Ko apeere gbolohun olopo oro ise marun –un ki o si fa ila si oro ise inu re.
OSE KEJO
EKA ISE:A SA
ORI ORO: ASA IRAN-RA-ENI LOWO LAWUJO YORUBA
Asa iran-ra –eni lowo je ona ti awon yoruba n gba ran ara won lowo nibi ise won gbogbo
Yoruba gbagbo ninu ki won se iranwo fun omonikeji. Won a maa ko ara jo lati da oko,koi le,ko ebe,kore oko,fo epo,gbe odo,la ona,gbe koto abbl. Ba kan naa,won a maa se iranlowo owo fun ara won nipa dida ajo, dida esusu ati kikorajopo lati da egbe alafowosowopo ode oni sílè. [mediator_tech]
ORISI ONA TI YORUBA N GBA RAN ARA WON LOWO LAYE ATIJO
- Ajo
- Esusu
- Ebese
- Owe
- Aaro
- Arokodoko
IGBELEWON:
- Salaye asa iran-ra-eni lowo ni soki
- Daruko awon ona ti Yoruba n gba ran ara won lowo ni ile Yoruba
ISE ASETILEWA:
- Salaye ona iranra-eni-lowo ode-oni ni kikun.
OSE KESAN-AN
EKA EDE: IASA
ORI ORO: IWA OMOLUABI
Omoluabi ni omo ti a bi, ti a ko, ti o si gba eko rere
Yoruba bo won ni “ile ni a ti n ko eso rode”. Iwa omoluabi bere lati inu ile.
AWON IWA OMOLUABI
- Iwa ikini: dandan ki omo okunrin ti a ko lati ile ire ki o dobale fun awon obi re ni geere ti o ba ji ni owuro,ba kan naa lo pon dandan fun omo obinrin ki o kunle ese mejeeji fun awon obi re nitori awon ni alagbato Olodumare fun won.kii se awon obi eni nikan ni a gbodo maa ki,gbogbo awon ti o ju ni lo lojo ori ibaa se egbon eni, oluko,aladugbo,awon agba akekoo ni ile eko,abbl ni a gbodo maa kin i igba gbogbo.
- Ibowo ati iteriba fun agba: iwa ikini ko so pe eniyan ni ibowo fun agba nikan.bibowo fun agba ninu oro enu, ise jije,gbigba eru lowo agba ati awon ohun amuye miiran lo n fihan iru eni ti eniyan je
- Iwa pele lawujo: pupo omo lo huwa janduku lawujo ti won ti ba oruko ebi ati ojo iwaju won je.iwa pel nibikibi ti a bat i ba ara wa yala ni ile iwe,ibi ikose,ibi ijeun,ori ila,yara idanwo,ile ijosin ati ni awujo se Pataki fun omo oluwabi.
- Otito siso: otito lo n gbe eniyan leke. Ni ibikibi ti a bat i ba ara wa gege bi omo oluwabi a gbodo le jeri w ape oloooto eniyan ni wa
- Iwa igbonran: ninu iwe mimo bibeli,igbonran llo n fi han boya a gba Olorun gbo.ba kan naa ,igbonran lo n fi han iru omo ti a je ati iru ile ti a ti jade wa.ni ile eko igboran si awon alase,igboran si awon oluko,igboran si Olorun se koko
- Iwa iran-ra-eni-lowo:Asa yii wopo laaarin awon omo Yoruba.o n fi han pe a nife ara wa.riran obi lowo ninu ile,sise irnwo fun omolakeji eni se Pataki gege bi omoluabi.
AWON IWA TI KO YE OMOLUABI
- Ojukokoro
- Ole
- Imele
- Iwa aigbonran
- Igberaga
- Ipanle
- Iro pipa
- Oole ,abbl
IGBELEWON:
- Ta ni omoluabi?
- Ko iwa omoluabi marun-un pelu alaye
- Ko awon iwa ti ko ye omoluabi ni ile Yoruba
ISE ASETILEWA:
- Gege bi akekoo ti o ni iwa omoluabi, ko iwa marun-un ti ko ye ki a ba lowo omoluabi ni ile Yoruba ki o si salaye.
[mediator_tech]
Third Term JSS 1 EXAMS QUESTIONS YORUBA
ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS 3 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA