ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS 3 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA
OMEGA TERM ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS3
YORUBA LANGUAGE
OSE | AKORI EKO |
1 | LETA GBEFE |
2 | ATUNYEWO OWE ILE YORUBA |
3 | AAYAN OGBUFO |
4 | AKANLO EDE |
5 | ISEDA ORO (ISODORUKO) |
6 | EYAN |
Atunyewo lori gbogbo ise saa yii ati idanwo ipari saa keta lori Ede, Asa ati Litireso ede Yoruba |
OSE KINNI
AKORI EKO: LETA GBEFE
Leta gbefe ni leta ti amaa n ko sis ara, ebi bii ore.
Bab, iya, egbon, aburo, ati ojulumo eni gbogbo.
IGBESE LETA GBEFE:
Ti aba n ko leta gbefe iwonyi ni awon ilana ti a gbodo tele:
{a} Adiresi akoleta:
Apa otun ni oke iwe tente ni a oo ko adiresi akoleta gbefe si, nonba ojule, opopona tabi apoti ile – ifiweranse oruko ilu ti a ti n kowe ati ipinle ni yoo wa ninu adiresi.
{b} Deeti:
Eyi ni ojo, osu ati odun ti akoleta kowe re. yoo tele adiresi. Bi apeere:
Command Secondary School
Ipaja,
Lagos.
11th February, 2002.
{d} Ikinii ibere:
Apa osi ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko ikini ibere si pelu ami koma ni ipari. Gbolohun ikini maa n da lori iru asepo ti o wa laarin akoleta ati eni ti a n ko o si. A le ko bayii:
Egbon mi owon,
Baba mi tooto,
Ore mi atata,
{e} Koko leta:
Ifaara ( Ero asedanwo) eyi niipin afo akoko. Idi ti akoleta fi ko leta lo gbogbo saaju laifi akoko sofo. Ti o ba je pe o n fesi si iwe ti won ko si o tele, o ye ki o fi han kiakia.
Bi apeere:
“Mo ni l eta ti o ko ni ojo keji osu yii gba
Ni ana ode yii. Mo dupe gidigidi pe e ko gbagbe wa.
Olorun ko ni gbagbe eyin naa o …..”
Ko tona ki a maa wadii alaafia eni ti a n kowe si
Niwon igba ti ko so fun wa ninu iwe re pe ara oun ko da, bee ni a gbodo year fun batani ikoleta aye ijoun. Apeere:
“inu mi dun lati kowe yii si o, mo si lero
Pe yoo bao ni alaafia ati ara lile …. Se ara n le ?
Eredi ti a fi kowe yala a n fe nnkan lati odo eni ti a n kowe si ni tabi a fe ki o se nnkan fun ni, alaye nnkan bee ni yoo duro bii koko leta wa.
{e} Ipari / ikadii leta: (ikini ipari ati oruko akoleta):
Owo otun ni akoleta yoo sun owo si ni ori pepa ti o ba fe ko ikini ikdii pelu ami koma. Oruko akoleta ni kan ni yoo han ni opin leta pelu ami idanuduro. Bi apeere:
Emi ni ore re
Bayo
[mediator_tech]
APEERE LETA GBEFE:
IBEERE:
Ko leta si ore re ni ilu odikeji lati so ni ekunrere ohun ti oju re ri nipa rogbodiyan to be sile nigba ti awoon adiginjale wa si adugbo re.
34, Agbedegbede Street,
Ile – Ife,
Osun State,
21st December, 2002.
Awoseemo mi tooto,
Mo de weliweli bi eji ale, mot un de warawara bi eji iyaleta. Eye meji ki ije asa. Emi ore re atata ni, katapila oko oke. Bawo ni nnkan? Se esin n jeko?
Idi pataki ti mo fi nko iwe yii ni lati se ekunrere alaye ohun ti oju mi ri nigba ti awon adigunjale was i adugbo wa ni idimu ni aipe yii.
Afere – mojumo ojo abameeta to koja ni wahala yii be. nnkan bii aago kan aajin ni won igara olosa yii wo adugbo wa. Logan ti won de naa ni awon ode ti bere si fon fere.
Onikaluku oulgbe lokunrin – lobinrin bere si san sokoto ija nitori o ti to bii osu meji ti awon ole wonyi ti wa n yow a lenu. Awon onile ati ayalegbe gbogbo gbe iku ta, won ya sita bi esun pelu ibon, ada, obe ere, ofa, olugbongbo igi ati kumo. Se anikan rin ni je omo ejo niya. Ohun ti o wa mu ki rogbodiyan oun ko yoyo ni bi awon ole naa se poora ninu soobu yereku kan bayii ti won sa wo.
Ka to wi ka to fo, adugbo ti kun fofo fun ero. Awon eeyan ti in abo soobu yii. Ibi ti ina yii ti n jo ni awon aja dudu meta kan ti deede sa jade lati pe-n-tuka. Sugbo awon agba taku pe ojo ti a ba ri ibi ni ibi i wole. Oro di woya ija. Ni iseju ahaya, won mu u bale. Won si le awon yooku wonu igbo lo. Ibe ni a si gbo wi pe won yanju gbogbo won si. Bayii ni won si se dana sun eyi to di eeyan ni ita gbangba.
Bi ile ti n mo ni awon olopaa de tawon ti ibon won, ti won si n toju bole mu awon eniyan. Esun ti won fi kan won ni pe won pa eniyan. Oro wa di isu atayan-an-yan-an. Awon alaadugbo fariga, won ni awon yoo dana sun ago olopaa kan soso ti o wa ni agbegbe wa. Opelope Kabiyesi to petu si okan awon ara ilu, oro naa i ba di ija igboro.
Ni akoko rogbodiyan yii, opolopo eniyan ni won fi ara pa felefele, ti eru ati owo ri o segbe ko se e so. Awa paapaa ti a ko fi arak o fi ara pa n dupe lowo Olorun Oba ni. Odidi ojo meta ni oju mi fi n pon bii oju elegun Sango fun oro ado ataju ti awon olopaa fin ni ojo oun.
Oro tr. Oro awon elekeru wonyi ti sun wa o. ijoba kuku n gbiyanju, iyefun ni ko kaju o,I oka ti won gbe kana.
Ba mi ki awon aburo re. ayo ati alaafia ni a o pade.
Emi ni tire ni tooto
Deinde
Ise Amutilewa
1. Ko leta si ore re lati je ki o mo anfaani ti o wa ninu iwe iroyin kika.
2. Ko leta si ore re ni oke okun lati je ki o mo ose ti awon adigunjale n se ni orile-ede wa bayii.
3. Ko leta si ore re kan ti o fidi remi ninu idanwo oniwee mewaa re pe ki o gbagbe oro ana, ki o si tiraka titun idanwo naa se.
OSE KEJI
AKORI EKO: ATUNYEWO OWE ILE YORUBA
Owe ni akojopo oro ti o kun fun ogbon, imo yinle ati iriri awon agba. Owe yii ni awon agba maa n pa lati fi yanju oro to ba ta koko. Ni ile Yoruba, omode kii pa owe ni waju agbalagba lai ma toro iyonda lowo won, omode maa yoo so pe “Tooto o se bi owe”, awon agba ti o wan i ijokoo yoo si dahun pe “wa a ri omiran pa”.
ONA TI OWE GBA WAYE
1. AKIYESI SISE: Awon agba maa n sakiyesi awon isele ti o n sele ni ayika won lati seda owe. Bi apeere:
Bi a ba gba ile, gba ita, aatan la n da a si.
2. ESIN: Opolopo awon owe ti awon baba n la wa maa n pa ni won waye nipase esin ibile won. Bi apeere:
Aigbofa la n woke, ifa kan ko si ni para
3. ASA: Inu okan-o-jokan asa Yoruba ni awon agba ti seda opolopo awon owe. Bi apeere:
Ile la n wo, ki a to so omo loruko.
ISORI OWE
Ona marun-un ni isori owe pin si, awon ni:
i. Owe fun imoran
ii. Owe fun alaye
iii. Owe fun ibawi
iv. Owe fun ikilo
v. Owe fun isiri
1. OWE FUN IMORAN: Ti oro ba doju ru, awon agba ni a maa n to lo fun imoran to ba ye. Ni opolopo igba, owe ni won maa n pa lati to eniyan sona. Bi apeere:
a. Ile ti ko toju eni su, okunkun re maa n soro o rin
b. Alagemo ti bimo tan, aimojo ku sowo omo alagemo
d. Igi ganganran ma gun ni loju, okeere lati n wo o.
e. Oja mewaa ko ju oju en
ҿ. Falana gbo tire, tara eni la a gbo.
2. OWE FUN ALAYE: Awon owe kan wa ti awon agba fi maa n salaye ero okan won fun eni ti won ba a ba soro. Bi apeere:
a. Ki ile to pa osika, ohun rere a ti baje
b. A ku to eni bag be, ki a maa to oro ba nii so
d. Agba to n sare ni aarin oja ni, bi nkan ko le, a je pe o n le nkan.
e. Agbatan ni a n gba ole, bi a ba da so fun ole a paa laro, bi a ba ole nija, a sin-in dele.
ҿ. Ara aimuole le n ko je ki a mop e ologbo n soole.
3. OWE FUN IBAWI: Bi enikan ba n huwa ti ko dara, owe ni awon agba fi maa n ba iru eni bee wi. Bi apeere:
a. Bi omode ba n se bi omode, agba o si se bi agba
b. Aja kii roro ko so oju lo meji
d. Afase gbe ojo n tan ara re je
e. Adiye funfun ko mo ara re lagba
ҿ. A kii ni eran erin lori, ki a tun maa fi ese wa ire nile.
4. OWE FUN IKILO: Ti a ba se akiyesi pe enikan wa ninu ewu ti oun gba-an ko mo tabifura, awon agba maa n pa owe lati kilo fun pe ki o sora. Bi apeere:
a. Bi eit ko ba gbo yinkin, inu kii baje
b. Ise ni oogun ise
d. Alaso ala kii ba elepo sore
e. Agboju logun fi ara re fun osi ta
ҿ. Ese giri nile origofe, anjofe ku, a ko ri enikan.
5. OWE FUN ISIRI: A maa n lo awon owe yii lati tu eniyan ti o wa ninu ibanuje ninu tabi eni ti o ti so iretu nu oro aye re. Bi apeere:
a. Igbeyin ni alayo n ta
b. Kii buru titi ki o ma ku enikan mo ni, eni ti yoo ku ni a ko mo
d. Ajeji owo kan ko gberu dori
e. Ise kii se ni, ki omo eni maa dagba
ҿ. Pipe ni yoo pe, akololo a pe Baba.
Ise Asetilewa
“Adiye funfun ko mo ara re lagba”. So itunmo owe yii.
[mediator_tech]
OSE KETA
AKORI EKO: AAYAN OGBUFO
Aayan ogbufo ni ise itumo ede kan si ede miiran.
Ogbufo ni eni ti o n sise titumo ede kan si ede miiran. Ise ogbufo kuro ni gbefe. Idi nip e ohun ti asafo ede akoko ba so gan-an ni ogufo gbodo tumo si ede keji.
Amuye fun Ogbufo:
Ki asedanwo le yege ninu aayan ogbufo, o gbodo:
a. Gbo ede mejeeji yekeyeke
b. Nimo sipeli Yoruba ode oni ati ilo ami ohun ori oro.
d. Rip e isowokowe oun se e ka.
Isori Aayan Ogbifo:
Aayan ogbufo le je eleyo oro, onigbolohun keekeke, oloro wuuru, tabi olori-ewi. E je ki a bere lati ipile.
1. AAYAN OGBUFO ELEYO-ORO
ENGLISH YORUBA
/a/
abandon fi sile/ko sile
ability ilese nnkan
abstain fa seyin/ta kete
academic ajemakada
academic staff osise ajemakada
accident ijanba
accountant akowe owo
administration isakoso
administrator asakaso
audience onwonran/ongbo
agenda agbese ipade
approach ifojuwo/ona imuse
assistance iranwo
/b/
boundary aala
back bite soro eni leyin
backbone eegun/ogooto-ehin
bag apo/oke
baggage eru
bald pipari
banana ogede wewe
bandit olosa
bane iparun/iku
/c/
constitution ofin ipinle
cult awo
course abala eko
certificate iwe eri
capital letter leta nla
chalk efun ikowe/sooki
chalk board patako ikowe
change iyipada
cheating isojooro
chorus elegbe
citation afo-ikan saara
classroom yara ikekoo
climax otente
cognition imo-nnkan
command ase
communication ibanisoro
compare fi we
competition idije
concept ero
conference apero
consequence abajade
convention asa
correct tona
culture asa
/d/
deceit etan
decision ipinu
deify so dorisa/so di ibo
discover roye/wa ri
dominate gaba
duration akoko
dedication ifisori
disorder idaru-dapo
displace gba nipo
divination isayewo
delete yo
demotion idapada
denote duro fun
detail orinkinniwin
detective otelemuye
device ete
diagram aworan atoka
dictation apeko
discuss jiroro/soro le lori
/e/
education imo eko
empty ofifo
environment ayika/sakaani
et.al atawon yooku
ethnic group iran
experiment se danwo
expose gbesaye/tu asiri
editor olootu
emphasize tenumo
English eko ede geesi
entertainment idaraya
entrance abawole
equal ba dogba
error/mistake asise
evidence eri
examine danwo/se agbeyewo
exhaustive wawodele/akidele
exhibition ipate
expert agba oje
explanation alaye
/f/
feudal onisokole
folk dance ijo awujo kan
folk tale alo onitan
free ainide
fulfilment aseyori
fail feeli/ko yege
filter ase
final ipari
fine art eko ise ona
foreign language ede ajeji
/g/
group egbe
geography eko nipa aye
group work ise elegbejegbe
guideline ilana itosona
/h/
humorous apanilerin-in
historian opitan/onimo itan
head ori
hero olu eda itan
home work ise asetilewa
/i/
idea oye
identity se idamo
ideology ero baye seri
i.e. iyen ni pe
illegal aibofinmu
imitate farawe
immoral ajemo iwa aito
invent pilese
illustration isapere
industry ise owo-iseda
/j/
judge gbe lewon
joke apara
/k/
know mo
knowledge imo
/l/
lack aini
law ofin
lawless alaikofinsi
legal bofinmu
legend itan kayeefi akoni
link sopo
laboratory (school) yara eko sayensi
lesson ise ijoko kan
letter leta
lingua franca ede egbegberin
/m/
mislead si lona
mimic isinje
memorize ko sori
method ona
model awose
modification ipon
mood imulara
motivate moriya
moral iwa eto eko
motion picture aworan sinima
myth itan iwasw
/n/
nursery ile iwe jele o sinmi
null asofo
newspaper iwe iroyin
/o/
observe sakiyesi
orator ameso-oro
omit fo
overlap wonu ara won
oppose lodi si
option iwofun
out put amujade
/p/
pass yege
peasant alaroje
philosophy imo ijinle
public ita gbangba
projector ero agbaworanyo
pattern batani
pause idanuduro
practise fikora
perception ifojumo
presentation igbekale
period akoko ise
[mediator_tech]
photograph foto
physics eko fisiisi
place ibi kan
planning ifetosi
precede saaju
professor ojogbon
progress itesiwaju
promotion igbega
proof imudaniloju
pronounce pe
proposal aba
/q/
Quality awomo
Question ibeere
Quotation ayolo
/r/
race eya
racial ajemeya
reify so dohun
resolve yanju
resolution iyanju
reverse iyipada
rude rifin
rudeness arifin
rule ofin
radio redio
rank ipo
realism ibayemu
reason/cause idi
recapitulate mu wa sirananti
reciprocal owowewo
recite ran
record(playing) awo
refer tokasi
relation ibatan
repeat tun ka
repetition awitunwi
report ijabo
represent duro fun
research iwadii
retained da si
reward fa seyin
revise ipinlere
revision tun yewo
ridicule atunyewo
role yeye
religious man okunrin amesin
/s/
Secular aimesinlo
Separation ipinya
Stage ori itage
Set seeti
Solo orin adako
Socialism eto alajoni
Speak fo / safo
Sequence iteletele
speech afo
Sign ami
screen ate agbaworan-tan
Similarity ifarajora
Specific pato
Situation aye
Special oto
Stubborness isori kunkun
Skill imoose
Surprise ibalojii
Simultaneous alajowa
Suspense ikolayasoke
Stammerer akololo
/t/
Task ise kayeefi
Tale itan
Technology imo ogbon
Terms ipele
Tier isini ipo
Transfer isini ipo
Teaching ikoni
Tension inu – fu – edo – fu
Thought ero
Title akole
Tragedy ere oladojude
Transform ayipada
/u/
Unit ida
Unity iwapo lodindi
/v/
Verify wadii okodoro
Vibrate gbon
Victim afaragbabi
Victimize se nibi
Villain asebi
Vague sainitumo pato
Variation eda
Verse ewi
/w/
Word oro
Wonder iyanu
Workbook iwe ise amuse
/y/
Yes beeni
Yuletide keresimesi
OSE KERIN
AKORIN EKO: ISEDA ORO{ISODOURKO}
Ifaara:
Isodoruko ni sisedia oro-oruko
Tuntun latin ara isori oro miiran
Orisii oro meji ni o wan i ede yoruba. Awon ni oro ipile ati oro atowoda tabi oro ti a seda.
Oro ipile:
Eyi ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere ni: ori, ile, oju, iku, owo, aja, ewe, ati bee bee lo.
Oro atowoda:
Iwonyi ni awon oro ti a le seda won nipa lilo afomo, sise apetunpe tabi ona miiran. Bi apeere:
I + fe = ife
Ati + de = atide
Orisii ona isodourko:
{i} lilo afoma ibere:
A le kan afomo ibere po mo oro-ise to je mofiimu ipile lati seda oro-oruko tuntun. Bi apeere:
Afomo ibere oro ise oro-oruko
(mofiimu ipile) (ayorisi)
I + dajo = idajo
I + tiju = itiju
e + to = eto
e + ko = eko
ai + bikita = aibikita
ai + san = aisan
alai + sunwon = alaisunwon
on + woran = onworan
on + te = onte
oni + bara = onibara
oni + aso = oniaso
ati + je = atije
{ii} Lilo afomo aarin:
A le lo afomo aarin bii “ki”, “ku”, ‘ni”, “ji”, “si”, “de”, ni aarin apetunpe mofiimu ipile to je oro-oruko. bi apeere:
[mediator_tech]
Mofiimu afomo mofiimu oro-oruko
Adaduro aarin ipile ti a seda
Iran ki iran = irankiiran
Ona ki ona = onakona
Ije ku ije = ijekuje
Agba ni agba = agbalagba
Ile ji ile = ilejile
Ore si ore = oresoore
Ile de ile = iledele
Omo de omo = omodomo
{iii} Sise apetunpe:
A le seda oro-oruko nipa sise apetunpe kikun bii:
{a} apetunpe oro-oruko. bi apeeere
Oro-oruko oro-oruko oro-oruko
Ose ose = oseoose
Osu osu = osuoosu
Odun odun = odoodun
{b} apetunpe apola-ise: Bi apeere:
Oro-oruko oro-oruko apola-ise oro-oruko ti a seda
se ise sise = sisesise
wo ile = wole = wolewole
pa eja = peja = pejapeja
[d] apetunpe elebe:
A le seda oro-oruko nipa sise apetunpe elebe fun oro-ise tabi apola-ise. a o se apetunpe konsonanti ibere oro-ise, a o wa kan odidi oro-ise tabi apola-ise naa mo ni iwaju, ki a to wa fi fawelii ‘I’ {olohun Oke] ya isupo konsonanti akoko mejeeji laaarin. Bi apeere:
Fawelii “I”
ro = r – r + ro = riro
ta = t – t + ta = tia
je = j – j + je = jije
{iv} Sise akanpo oro-oruko:
A le seda oro-oruko tuntun nipa sise:
{a} akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han. Bi apeere:
oro-oruko oro-oruko oro-oruko ti a seda
etu ibon = etuubon
eto ilu = etoolu
ile iwe = ileewe
{b} akanpo oro-oruko inu eyi ti isunki yoo ti waye. Bi apeere:
oro-oruko oro-oruko oro-oruko ti a seda
ori oke = oroke
irun agbon = irungbon
eran oko = eranko
{d} akanpo afomo ibere ati apetunpe oro-oruko. bi apeere:
afomo ibere oro-oruko oro-oruko oro-oruko ti a seda
oni ose ose = olosoose
oni osu osu = olosoosu
{e] akanpo afomo ibere oni mo oro-oruko meji.bi apeere
afomo oro-oruko oro-oruko oro-oruko ti a seda
oni iwa ika = oniwaaka
oni omo oba = olomooba
{v} a le lo afomo ibere onisilebu kan ati apola-ise lati seda or-oruko miiran. Bi apeere:
Afomo ibere apola-ise oro-oruko ti a seda
a + panirun = apanirun
a + ji isu wa = ajisuwa
o + ba aye je = obayeje
{iv} Asunki odidi gbolohun:
A le seda oro-oruko nipa sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. bi apeere:
gbolohun oro-oruko ti a seda
oba feran mi = obafemi
ifa ni eti = ifaleti
ifa ye mi = ifayemi
{vii} Lilo ami asoropo:
A tun le lo ami asoropo lati so awon oro eyo inu gbolohun po di oro-oruko tuntun. Bi apeere:
a-kuru-ye-ijo
alagba-lugbu-odo-ti-gbe-onigbere-teja-teja
ISORI ISODORUKO
Orisiirisii isodoruko inu ede yoruba ni:
{i] isodoruko afoyemo: A maa n fi afomo ibere, ‘a’ tabi’ ‘I’ tabi ‘ati’ kun oro-ise tabi ki a se apetunpe elebe fun oro-ise ti abayori re yoo je oro-oruko afoyemo. Bi apeere:
i + fe = ife
i + gbagbo = igbagbo
a + bo = abo
a + jo = ajo
ra + re = rira
ati + mu = atimu
ati + je = atije
{ii} isodoruko oluse:
Isodoruko oluse ni oro ti a lo lati fi ropo apola-oro-oruko oluse. Apeere, eni ti o mo on we ni omuwe. A n seda isodoruko yii nipa.
{a} fifi afomo ibere ‘a’, ‘o’, ‘on’, ‘mo oro-ise. apeere:
a + kowe = akowe {eni ti o koi we}
o + seke = oseke {eni to n se eke}
on + woran = onworan (eni to n wo iran}
{b} fifi afomo ibere: ‘oni’ kun oro-oruko. apeere:
oni + ipese = olupese(eni to n pese)
oni + eran = eleran (eni to n ta eran)
(d) sise apetunpe kikun fun apola-ise. bi apeere:
Pana + pana = panapan(eni to n pa ina)
daran + daran = darandaran (eni to n da-eran)
{iii} isodoruko elo:
Isodoruko elo ni apola-oruko ti a fi n ropo, apola-oruko ti o n so ohun ti a fi n se nnkan nipa fifi afomo ibere ‘a’, ‘I’ ati ‘on’ kun oro-ise. bi apeere:
a – se = ase
i – gbale = igbale
on – te = onte
{iv} isodoruko ayisodi:
Isodoruko ayisodi n waye nipa lilo oro atoka iyisodi ‘ai’ ‘ati’ ‘a’ bi afomo ibere fun oro-ise tabi apola-ise. bi apeere:
Afomo ibere apola-ise oro-oruko ti a seda
ai – kawe = aikawe
ai – jeun = aijeun
a – reru-ma-so = arerumaso
{v} isodoruko ini:
Isodoruko ini le waye nipa lilo afomo ibere ‘oni’ ‘abi’ mo oro-oruko tabi apola-ise yoo toka eni ti o n nnkan. Bi apeere:
Oni – oko = oloko
Oni – bata = onibata
Abi – oyun = aboyun
{vi} isodoruko atokun:
Isodoruko atokun n toka ibi kan tabi igba kan nipa lilo afomo ibere ‘ati’ ati oro-oruko papo. Bi apeere:
ati – ile = atile
ati – aaro = ataaro
ati – ana = atana
{vii} isodoruko akopo:
Eyi ni oro-oruko iseda ti a fi n ko gbogbo nnkan po. Eyi le waye nipa.
- Sise apetunpe kikun fun oro-oruko. apeere:
ojumo + ojumo = ojoojumo
owo + owo = owoowo
- Lilo afomo aarin ‘ki’ pelu sise apetunpe oro-oruko…. bi apeere:
oko + ki + oko = okokoko
egbe + ki + egbe = egbekegbe
eni + ki + eni = enikeni
{viii} isoduroko atenumo:
Isodoruko atenumo n waye nipa lilo oro-atenumo ‘ni’ bi afomo aarin si apetunpe oro-oruko kikun. Bi apeere:
agba + ni + agba = agbalagba
opo + ni + opo = opolopo
iyan + ni + iyan = iyanniyan
ogbo + ni + ogbo = ogbologbo.
[mediator_tech]
OSE KAUN
AKORI EKO: EYAN
Eyan ni wunren ti a fi n yan oro-oruko ninu apola-oruko lati itumo oro-oruko. Bi apeere:
Ile tuntun ni mo n gbe
Aso ala ni mow o.
ORISII EYAN INU ISO:
{i} Eyan asapejuwe:
Ise eyan asepejuwe ni lati pon oro-oruko ni ona ti yoo fi ye eniyan yekeyeke, oro apejuwe pin si:
[a] Oro apejuwe ipile: iwonyi ni rere, dudu, kekere, nla, funfun, pupa. Bi apeere:
Olu je omo rere.
Amala funfun ni mo ro.
Ounje kekere ko le yo mi.
[b] Oro apejuwe ti a seda nipa sise apetunpe lati se atenuwo. Apeere:
Yan: yiyan – eja yiyan ni mo fe. {eja ti a yan}.
Dun: didun – omi didun ni mo fi pogi. {omi ti o dun}
Nla: nla-nla – oke nla-nla wa ni Efon-Alaaye.
{ii} Eyan ajoruko:
Eyan ajoruko ni oro-oruko tabi oro-aropo-oruko ti a n lo lati yan oro-oruko miiran. Bi apeere:
Abule odu ni mo n gbe.
Ewure toorera ni awon ijo gbe lo.
Ile wa ni a ti n bo.
Oju Nikee wa ni araa mi.
Eyan ajoruko pin si orisii meji. eyi ni: eyan ajoruko onibaatan, ati eyan ajoruko alaaje.
[a] Eyan ajoruko onibaatan le je:
{i} Alaitenumo ti a lo lati fi ini han. Won le ni orisii itumo. Bi apeere:
Ile orisa – {ile ti a ti n bo oriisa}
{ile ti orisa ko}
Ajaa ode – {aja ti won fi n se ode}
{aja ti o je ti ode}
{ii} Alatenumo: ‘ti’ ti o je erun onibaatan maa n waye laarin oro-oruko ati eyan. Bi apeere:
Ile ti orisa
Aja ti ojo
Omo tire – {eyan aropo-oruko}
{b} Eyan ajoruko alalaje:
Oro-oruko ati eyan re maa n toka si nnkan kan naa. Bi apeere:
Dokita oyinbo ni mo fe ri {iyen dukita to je oyinbo}
Okunrin oloro yen ni o ra moto. {okunrin yii naa ni oloro}
Tisa na omo alaigboran. {omo naa ni ko gboran}
{iii} Eyan asafihan:
Eyan asafihan ni o maa n toka si ohun ti a n soro ni pato. Atoka eyan asafihan ni: wonyi, yen, yii, wonyen. Bi apeere:
Oro yii ti sun mi..
Ise wonyi le ju.
Bata naa wu mi.
Okunade gan-an ni mo fe ri.
{iv} Eyan- Atoka Asafihan
Wunren atoka won ni wonyi: ke, naa, kan, kan naa, gan-an, paapaa, nikan. A le lo ju eyo atoka kan lo ninu iso. Apeere:
Ilu ni a n gbe = ile kan naa ni a n gbe
Bewaji lo bi o = bewaji gan-an lo bi o
Oun ko kuku bikita = oun paapaa ko kuku bikita
{v} Eyan Asonka:
Iye nnkan ni a n fi eyin eyi toka ninu gbolohun. Bi apeere:
Omode meta n sere
Iwe mewaa ni mo ka
Iyawo kan ni o ye okunrin.
{vi} Eyan awe gbolohun asapejuwe/ Awe gbolohun asapejuwe:-
Ni ara gbolohun ni a ti n seda eyan yii lati fi kun itumo oro-oruko. ‘ti’ ni wunren atoka won. Bi apeere eyan awe gbolohun asapejuwe ni a fala si nidii yii:
Aso wu sola = aso ti a ra wu sola
Owo ko to ra bata = owo ti o san ko to ra bata.
Bab re ti de = baba ti a n soro re ti de