OONKA Láti Aadọta De Ọgọrun-ún (51-100) Yoruba JSS 1 First Term Lesson Notes Week 8
Ọsẹ Kẹjọ
ẸKA IṢẸ: ẸDE
AKỌLE IṢẸ: ONKA – OỌKÀLẸẸDOTA DE OGORUN-UN (51-100).
- Ọọkan lẹẹdọta = 50+1=51
- Ẹẹji lẹẹdọta = 50+2=52
- Ẹeta lẹẹdọta = 50+3=53
- Ẹerin lẹẹdọta = 50+4=54
- Aarun din logota = 60-5=55
- Ẹerin din logota = 60-4=56
- Ẹeta din logota = 60-3=57
- Ẹẹji din logota = 60-2=58
- Ọọkan din logota = 60-1=59
- Ọgọta = 60
- Ọọkan lẹ logota = 60+1=61
- Ẹẹji lẹ logota = 60+2=62
- Ẹeta lẹ logota = 60+3=63
- Ẹerin lẹ logota = 60+4=64
- Aarun din laadorin = 70-5=65
- Ẹerin din laadorin = 70-4=66
- Ẹeta din laadorin = 70-3=67
- Ẹẹji din laadorin = 70-2=68
- Ọọkan din laadorin = 70-1=69
- Aadorin = 70
- Ọọkan lẹ laadorin = 70+1=71
- Ẹẹji lẹ laadorin = 70+2=72
- Ẹeta lẹ laadorin = 70+3=73
- Ẹerin lẹ laadorin = 70+4=74
- Aarun din logorin = 80-5=75
- Ẹerin din logorin = 80-4=76
- Ẹeta din logorin = 80-3=77
- Ẹẹji din logorin = 80-2=78
- Ọọkan din logorin = 80-1=79
- Ọgọrin = 80
- Ọọkan lẹ logorin = 80+1=81
- Ẹẹji lẹ logorin = 80+2=82
- Ẹeta lẹ logorin = 80+3=83
- Ẹerin lẹ logorin = 80+4=84
- Aarun din laadorun-un = 90-5=85
- Ẹerin din laadorun-un = 90-4=86
- Ẹeta din laadorun-un = 90-3=87
- Ẹẹji din laadorun-un = 90-2=88
- Ọọkan din laadorun-un = 90-1=89
- Aadorun-un = 90
- Ọọkan lẹ laadorun-un = 90+1=91
- Ẹẹji lẹ laadorun-un = 90+2=92
- Ẹeta lẹ laadorun-un = 90+3=93
- Ẹerin lẹ laadorun-un = 90+4=94
- Aarun din logorun-un = 100-5=95
- Ẹerin din logorun-un = 100-4=96
- Ẹeta din logorun-un = 100-3=97
- Ẹẹji din logorun-un = 100-2=98
- Ọọkan din logorun-un = 100-1=99
- Ọgọrun-un = 100
ẸKA IṢẸ: ASA
AKỌLE IṢẸ: ASA ATI OHUN ELO ISOMOLORUKO.
Asa isomoloruko ni ọna ti a n gba fun ọmọ tuntun ni orukọ ti yoo maa jẹ titi lae ni ile Yoruba. Ọmọ tuntun ni Yoruba ni a n so lorukọ ni ọjọ kẹfa ti a ba ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin tabi ibeji. Ni ibo miiran, ọjọ kẹsan-an ni wọn n so ọmọkunrin lorukọ, ọjọ keje ni ti ọmọbinrin ati awọn ibeji ni ọjọ kẹjọ.
Die lara ohun elo isomoloruko niyi:
- Ohunelo: Iwure/adura
Apẹẹrẹ: Obi – Bibi lobi n biku danu, bibi lobi n baarun danu, obi a bi ibi aye re danu. - Orogbo: Orogbo maa n gbo saye ni, o o gboo, waa to, waa gbo kejekeje, o ko ni gbo igbo iya.
- Oyin: A kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o o koni je ikoso laye.
- Oti: Oti kii ti, oko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko nit e
- Epo pupa: Epo ni iroju obe, aye re a roju.
- Iyo: Iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu inu awon obi re dun.
- Ataare: Ataare kii bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun, oye re a kun fomo.
- Aadun: Aadun ni a n ba nile aadun, ibaje oni wole to o.
- Ireke: A kii ba kikan ninu ireke, ikoro ko ni wo aye re lae, aye re yoo dun
- Omi tutu: Omi la buwe, omi la bumu enikan kii ba omi sota, koo mu to.
ẸKA IṢẸ: LITIRESO
AKỌLE IṢẸ: AWON LITIRESO APILEKO ITAN AROSO – KIKA IWE TI IJỌBA YAN
Igbelewon:
- Kin ni asa isomoloruko?
- Ko ohun elo isomoloruko marun-un ki o si sọ bi a ṣe n fi wure fun ọmọ tuntun.
- Ko onka lati ọọkàn lẹẹdọta de ọgọrun-un.
Ise Asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege fun JSS1.