Ìwà Ọmọlúwàbí Yoruba JSS 2 Second Term Lesson Notes Week 9
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Second Term
Week : Week 9
Topic :
DE: Akaye Onisorogbesi.
ASA: Iwa Omoluwabi. Kin ni omoluwabi, ojuse omoluwabi ni awujo: (otito siso,iwa pele ati ibowo fun agba)
LIT: Kika Iwe Apileko ti ijoba yan.
OSE KESAN-AN.
IWA OMOLUWABI Deeti………………..
Iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Iwa rere ti o ye ti o si to ki eniyan maa hu ninu ile, ninu ijo, ninu egbe ati laarin ilu ni a pe ni iwa omoluabi. Iru iwa bayi maa wopo laarin awon omo ile iwe. Ibowofagba, iwa iteriba, ikini, otito siso. Iranra eni lowo. Iru iwa bayi maa n mu ibasepo wa laarin ebi ara ore ni. Nitori naa iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Apeere iwa omoluabi ni awujo ni:
- Ikini
- Otito siso
- Iteriba
- Igboran
- Iwa iforiti
- Asa iranra eni lowo
- Iwa pele
- Ibowo fagba
- Ise sise.
IGBELEWON
- Ki ni iwa omoluabi
- Ko iwa omoluabi merin sile
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
1 Eko ede Yoruba titun iwe keta ( S S S ) Oju iwe 105- 118 lati owo Oyebamji Mustaph
2 Oyebamji Mustaph (2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji ( JS S ) Oju iwe 164-173/1-15 university Press Plc.
LITIRESO
Kika iwe apileko ti ijoba yan.
APAPO IGBELEWON
- Ki ni iwa omoluabi
- Ko iwa omoluabi merin sile
ZT%NY@W) @K_
- Ki ni ami ohun?
- Se alaye lekun-un rere lori orisii ami ohun.
ISE ASETILEWA
- Eni ti o ni iwa gidi ni a mo si …….. A. oni ipata B. onijagidijagan D. omoluabi
- Ohun akoko ti a gbodo se ti a ba ji laaro ni ……. A. ki a rin erin B. ki a jeun D. ki a ki awon obi wa.
- Aroko wa gbodo …….. A. pani lerin B. mu ki eniyan sun D. koni logbon
- Orisii aroko to tun wa ni …… A. aroso B. agbaso D. alalaye
- Ti a ba fe ko aroko, a gbodo yan …..A. ikadi B. ifaara D. ori oro
APA KEJI
- ko iwa omoluabi mewaa sile
OSE KEWAA
GBOLOHUN EDE YORUBA
gbolohun ni ipede ti o kun pelu itumo kikun. Orisii eya gbolohun meji ni o wa. Awon eya naa ni: (i) gbolohun ni ilana ihun ati
(ii) gbolohun ni ilana ise tabi ise ti o n je.
- Gbolohun ni Ilana Ihun ni: gbolohun eleyo oro ise (abode), olopo oro ise (onibo) ati alakanpo.
- Gbolohun eleyo oro ise o maa n ni eyo oro ise kan. Apeere: ade pa eku.
- Gbolohun olopo oro ise: o maa n ni ju eyo oro ise kan lo. Apeere: Kunle sare tete lo pon omi
- Gbolohun alakanpo: o maa n gbolohun meji ninu. O si maa ni oro asopo ninu pelu. Apeere: Apeere: Olu je buredi ati eyin.
- Gbolohun ni Ilana Ise/ise ti o n je: apeere gbolohun alalaye, ase, ibeere, kani, ayisodi,
- Gbolohun Alalaye: a maa n fi se alaye. Apeere: ojo ro ni ana.
- Gbolohun Ase: a maa n fi ase. Apeere: jokoo si ibe yen, pa enu re de.
- Gbolohun Ibeere: a maa n fi se iwadii a si maa n lo wuren/atoka ibeere awon bi: nko, nda, se, tani, ki ni, bawo, nibo. Apeere: Se o ti jeun?
- Gbolohun Kani/Iba: Apeere: n ba wa kani mo gbo.
- Gbolohun Ayisodi: a maa n se amulo ko, o, ki i, i. Apeere: Gbade ko ka iwe.
IGBELEWON
- Ko apeere marun-un marun-un fun awon gbolohun yii:
Gbolohun ase, olopo oro ise, abode, alakanpo, ibeere, ayisodi,alalaye.
IWE AKATILEWA:
- Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S1 ) University Press oju iwe 219-222 & 227-230
IWA OMOLUWABI
Awon Yoruba bo won ni iwa rere ni eso eniyan bee si ni oruko rere san ju wura ohun fadaka lo. Gege bi omoluabi, orisiirisii ojuse ati eto ni o se pataki ti a gbodo mojuto tabi fi si okan ni eyi yoo mu ki awon eniyan maa wo eniyan bi omo ti o ni eko. lara awon ojuse naa ni wony:
Ojuse si Obi: Gege bi omoluabi ti a ko ti o si gba eko, o ni awon ojuse ti a gbodo maa se fun awon obi wa tori Yoruba bo won ni ile lati ko eso rode. Omoluwabi gbodo:
Gboran si obi lenu
gboro si obi re lenu.
Jise fun awon obi
Bowo fun awon obi re
Tun oruko obi re se.
Je asoju rere fun obi re nibi gbogbo.
Se ise ile fun obi re
Ijoba: omoluwabi gbodo:
San owo ori
Bowo fun ofin ilu
Da si ise idagbasoke ilu
Je asoju rere fun orile-ede re.
Gbodo kopa ninu idagbasoke oro aje ilu re.
Maa bowo fun Asia orile-ede re.
LITIRESO
Kika iwe apileko ti ijoba yan.
ISE AMURELE
- “Nje” je atona/wuren gbolohun ____ A. Ibeere B. alalaye D. Ase.
-
“E dake” je apeere gbolohun ______ A. Alaye B. Ase D. Ibeere E. Alakanpo
-
______ ni gbolohun ti a ti maa se amulo oro asopo A. Eleyo oro ise B. Olopo oro ise D. Alakanpo
-
Ewo ni ki i se wunren gbolohun ibeere ninu awon wonyi A. awaB. Meloo D. Bawo.
5 Eni ti o ni iwa gidi ni a mo si …….. A. oni ipata B. onijagidijagan D. omoluabi
APA KEJI
- salaye awon gbolohun won yii gbolohun olopo oro ise,gbolohun eleyo oro ise ati gbolohunibeere
- ko iwa omoluabi sile