Ohun Elo Ogun jija

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Second Term

 

Week : Week 5

 

Topic :

EDE: Aroko Asotan/Oniroyin ( kiko aroko).

ASA: Eto Isigun, Ipalemo ogun jija, awon ohun elo ogun jija ati ete

ogun jija.

LIT: Litireso Alohun to je mo esin ibile- orin oro, sango pipe, esu pipe, oya pipe. Abbl.

 

 

 

WEEK 1

EDE: Atunyewo ise saa kin-in-ni

ASA: Atunyewo ise saa kin-in-ni

LIT: Atunyewo ise saa kin-in-ni

 

 

OSE KARUN-UN

AROKO ASOTAN/ONIROYIN Deeti………………..

AKOONU:

  • Itumo
  • Apeere.
  • Igbese.

Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.

Aroko oniroyin: ni a n pe ni aroko asotan. Iru aroko yii ni a ti maa n so itan isele ti a fi oju ri tabi eyi ti a kopa ninu re, tabi ti a gbo lati enu enikan. Aroko yii maa n so nipa ohun to ti sele seyin ni. Die ninu awon ori oro ti a le ko aroko oniroyin le lori ni wonyi:-

  1. Ija igboro kan to soju mi
  2. Ijamba moto kan ti mo wa ninu re
  3. Ojo kan ti a ko le gbagbe
  4. Ayeye ojo ibi kan ti mo lo

Awon igbese ti a gbodo gbe bi a ba fe ko aroko asotan ni:-

  1. A gbodo yan ori oro ti a fe so itan le lori
  2. A gbodo so ilu tabi ibi ti isele naa ti se
  3. Agbodo so ohun to gbe ni de ibi isile naa tabi nnkan to fa sababi isele naa
  4. A gbodo so itan naa lekun rere bo se waye gan-an
  5. A gbodo kadi itan wa pelu eko mani-gbagbe kan tabi imoran.

IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) 49-51 Longman Nig Plc.

AWON OHUN ELO OGUN JIJA Deeti………………..

Ki ilu kan to ja ilu miiran. A je wi pe ede aiyede ti wa laarin won. Leyin eyi ni won o ta arawon lolobo pe ki won o mura ogun jija (ipeninija ) sile . Awon ode ilu ni won saba maa n lo ja ogun. Eleyi wopo laarin awon iran eso ikoyi. Won o paroko ranse. Ose, osun, kaninkanin ninu igba kan. Etu, ota ibon, ado ati awon nnkan ijanba ninu igba miiran. Won a ni ki oba ilu keji o yan okan ninu aroko yii. Ota, ibon, ahaya yii tumo si ogun nigba ti osun, ose tumo si alaafia pe awon fara mo ohun ti awon ilu keji yii so. Awon ohun eelo ogun jija ni ibon, ofa, ada, obe, ahaya, etu, kumo, kannakanna, esin, oogun lorisiirisii.

Ipalemo Ogun Jija: ki won to ja ogun nile Yoruba, ilu yoo lo beere lowo ifa bi ohun yoo ti ri, ohun ti won gbodo koko se ki won to ja ogun. Won yoo bo ifa. Won yoo rubo Ogun ki Ogun ma fi eje won we. Ki ohun ija won bi ida, ibon ma koju ija si won. Won o tun rubo si Esu laalu ogiri oko ki Esu ma ba a se won, ki Esu se awon ota won.Leyin eyi ni won yoo ko awon odo kunrin jo pelu awon omo ode fun imura sile de ogun.

Eto Isigun: awon omo ogun ni won koko maa n siwaju ogun nigba ti awon oloye ogun yoo tele won gege bi ipo won ba se ga to. Balogun ati awon isongbe re ni o maa n keyin ogun.

WEEK 2

EDE: Aroso Alapejuwe (ilana bi a se le ko aroko Yoruba )

ASA: Asa Iranra Eni lowo- Ajo, Esusu, Egbe Alafowosowopo

LIT: Litireso Alohun to je mo Esin Ibile- Iyere Ifa, Iwi, Ijala Iremoje.

 

 

 

IGBELEWON

  1. KI ni awon nnkan ti won fi maa n paroko ogun jija?
  2. Ko awon ohun elo ogun jija mewaa sile.
  3. Salaye lori ipalemo ogun.

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

1 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 75-86 university Press Plc.

2 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 1-15 University Press Plc.

LITIRESO

AWON EWI ALOHUN AJEMESIN ABALAYE

 

– Iyere Ifa

– Esa Egungun / Iwi

– Sango Pipe

Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.

Iyere Ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.

Esa Egungun/Iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. Tako-tabo idile oloje lo le pe esa.

Sango Pipe: ni ewi awon Adosu Sango awon ni olusin Sango, o le je okunrin tabi obinrin, ko si eni ti ko le ki oriki Sango. Asiko ti won ba n bo Sango tabi se odun Sango ni Sango pipe ti maa n waye ju.

Oya Pipe: Oya pipe je ewi alohun esin abalaye esin Oya. Won maa n pe e ni akoko odun oya. Awon olubo re ni a n pe ni Iya Oya. Oro inu re maa n da lori ife oko, eewo Oya agbo tabi irun re (agbo) ko gbodo de ojubo oya. Ounje fun irubo amala ati obe ilasa ati ewure. Apeere Oya Pipe:

A-a-seeperi arewa obinrin

Oya oriri, nle oloro Sango

Afinju irunmole ti n be lodo Sango

Afinju iyawo ti n ba oko re rode ……..

Orin Oro/Arungbe: awon oloro ni won n ko orin ni akoko odun re (odun oro) won n fi orin yiibi oniwabaje lati le dekun iwa ibaje tabi lati fit un asiri ohun ikoko ti won ro pe eni Kankan ko mo. Awon oloye oro Ajana, Lala, Eleeti Oro. Ounje Oro: efo ekuya, asaro, obuko, adiye, iyan ati obe egusi. Eewo: obinrin ko gbodo ri Oro. A ki i ajeku Oro. Apeere orin Oro ni:

Ta n pe Tisa nibi Oro? (2ce)

Abi sokoto tofetofe

Ta n pe Tisa nidi Oro?

Oro ma soko

Ile ni e wa to

Obinrin wo o, o ku pi……

Esu-Pipe: Awon Olubo re ni won n pe e ni akoko odun won. Esu je iranse/olopaa Olodumare. Obinrin ni o wopo laaarin awon Aworo Esu, awon okunrin maa n da ere si ori.

Ounje Esu: epo,ebo.

Eewo Esu: adi ati obi.

Apeere Ewi Alohun Esu Pipe:

Esu laalu ogiri oko,laaroye afada toro-epo

Okunrin kukuru,okunrin gogoro laalu

Abani woran ba o rid a

Elekun n sunkun, Laaroye n s’eje.

Ijala Ere Ode: Awon Ode ati alagbede ni won n sun ijala ni akoko odun lati fi yin Ogun ati lati fi wa oju rere re tabi lati fi ki agba ode.

Oloye: Oluode, Jagun, Ode abogun,

Ounje Ogun: aja, iya, obi, emu, esun isu, akukodie.

Ohun Elo Orin Ijala: fere ekutu, ilu dundun, ati ilu agree.

Apeere Ijala Ode ni:

Ogun lakaaye osinmole,

Onile kangunkangun oke orun,

O lomi nile feje we,

O laso nile fi morimo bora.

Ogun aladaa meji,

O fikan sanko, o fikan yena…

 

WEEK 3

EDE: Aroko Asapejuwe ( kiko aroko alapejuwe).

ASA: Asa Iranra eni lowo (owe, aaro, arokodoko, ebese )

LIT: Kika Iwe Apileko: ere onise ti ijoba yan

 

IGBELEWON

Salaye ewi alohun ajemesin marun-un.

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) YORUBA LI BOOK 2 Corpromutt Publishers Oju Iwe 16-17.

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc Oju Iwe 14-16.

APAPO IGBELEWON

  1. Ki ni aroko oniroyin/asotan?
  2. Ko aroko lori ojo ibi re ti o koja
  3. Ko ilapa ero lori “Ojo kan ti nko le gbagbe”
  4. Salaye ewi alohun ajemesin marun-un.
  5. Ko aroko lori ‘ile iwe mi’

ISE ASETILEWA

  1. Ti won ba fun wa ni akaye ohun ti won fe ki a se ni ki a ……A. ronu B. sa ere kiri D. fa ogbon inu re yo
  2. Ota ibon, etu je aroko ….. A. alaafia B. ipalemo ise ode D. ogun jija.
  3. Awon ti ogun ba ko lati ilu kan si omiran ni a n pe ni ….. A. jagunjagun B. iwofa D. eru
  4. Awon ……. ni olusin ogun A. olounje B. ode D. onirara.
  5. …….. ni won n fi ijala bo A. ogun B. ifa D. sango.

 

 

WEEK 4

EDE: Aroso Oniroyin/Asotan ( ilana)

ASA: Ogun Jija (awon ohun ti o n fa ogun jija ati ohun ti ko ye ko fa ogun jija, awon oloye ogun).

LIT: kika iwe ere onise.

 

 

APA KEJI

  1. Ko ohun elo ogun jija meji sile
  2. Ko merin sile ninu ewi atenudenu to je mo esin abalaye
Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share