Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì Yoruba Primary 1 Second Term Lesson Notes
DEETI: ỌJỌ́BỌ̀ ỌJỌ́ KỌKÀNLÁ OṢÙ SẸẸRẸ, 2024. KÍLÁÀSÌ: alákọ̀bẹ́rẹ̀ olódún kíní IṢẸ́: YORÙBÁ ỌJỌ́ ORÍ AKẸ́Ẹ̀KỌ́: ỌDÚN MẸ́FÀ SÍ MÉJE ORÍ Ọ̀RỌ̀: Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ: Ayọ̀ Adésànyà et’al(2018) Ìwé Kíkà Àsìkò Tuntun, Ojú ewé Kejì. OHUN ÈLÒ ÌKỌ́NI: Sáàtì tí ó ṣe àfihàn àẁorán nǹkan lórísìírísìí. ÌMỌ̀ ÀTẸ̀YÌNWÁ: Akẹ́kọ̀ọ́ ti ní ìmọ̀ nípa nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ rí ÈRÒŃGBÀ: NÍ ÌPARÍ Ẹ̀KỌ́ YÌÍ, AKẸ́KỌ̀Ọ́ YÓÒ LE ṢE ÀWỌN NǸKAN WỌ̀NYÍ
- Dárúkọ àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé
- Dá àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé mọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
- Ṣàlàyé ìwúlò nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́
ÌJÍRÒRÒ: Àwọn nǹkan tó wà nínú kíláàsì
- Àga
- Tábìlì
- Aago
- Gègé
- Ìwé
- Tabili
- Pátákó ìkọ̀wé
- Ìfàlà
- Fáánù
- Ẹfun ìkọ̀wé
Ìgbésẹ̀ kínńí: olùkọ́ ṣàfihàn àwọn ohun èlò ìkọ́ni Ìgbésẹ̀ kejì : olùkọ́ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìgbésẹ̀ kẹta: olùkọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyè láti dárúkọ àwọn ohun èlò inú kíláàsì Ìgbésẹ̀ kẹrin: olùkọ́ fi ààyè sílẹ̀ fún akẹ́kòó láti ṣe ìdámọ̀ àwọn ohun èlò inú kíláàsì àti ìwúlò wọn ÌGBÉLÉWỌ̀N: olùkó bèèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyì lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Dárúkọ ohun márùn-ún tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ
- Sọ ìwúlò àwọn ohun èló yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́
IKADII: Olùkọ́ kádìí ẹ̀kọ́ náà nílẹ̀ nípa ṣíṣe àlàyé ráńpẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà. IṢÉ ÀṢETILÉWÁ: Ya àwòrán ohun méjì tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ.
Recommend Posts :
- Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì Yoruba Primary 1 Second Term Lesson Notes
- SECOND TERM EXAMINATION 2019 CLASS: PRIMARY 2 SUBJECT: YORUBA LANGUAGE
- Onka ni ede yoruba lati ori ookan de ori ewaa
- Alufabeti Ede Yoruba (The Letters Of The Alphabets In Yoruba)Yoruba Primary 1 First Term Lesson Notes Week 8
- ÀWỌN FAWELI ATI KONSONANTI EDE YORUBA
- A—Aaja. Yorùbá
- Ere Okoto títa ni ile Yoruba
- Akole:onka ni ede Yoruba lati ori ookan de ogun
- Yoruba Primary 1 First Term Examinations
- 3RD TERM EXAM QUESTIONS PRIMARY 1 YORUBA