Yoruba Primary 3 Second Term Lesson Notes
SUBJECT: EDE – YORUBA
CLASS: BASIC 3 / GRADE 3 / PRIMARY 3
TERM: SECOND TERM (2ND TERM )
WEEK: 1
REVISION OF LAST TERM WORK – WELCOME TEST
Àṣà ikinni ni ile Yorùbá
Ikinni jẹ ọna ti a fí kó ọmọdé ni eko ilé. Bí ọmọdé bàa jí ni owuro, ó gbọ́dọ̀ mo bí a ṣe nki bàbà tàbí ìyá rẹ, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá ju lọ.
Ọmọ ọkùnrin yio dobale bẹẹ si ni ọmọ obìnrin yio wa ni ori ikunle
Àwọn ọ̀nà tí a ngba láti kí ara wa ni ile Yoruba
1. Ní àkókò
2. Ní ìgbà
3. Ní irú ipò tí a bá wà tàbí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lowo sì òní tòun
4. Bí a ṣe nki òní ìṣe owó àti bí a tin fà wọn lóhùn
5. Bí a ṣe nki ọba tàbí ìjòyè ilu
Ní àkókò : ni dédé agogo méje aro sì agogo mokanla abo ni Yoruba nki ara wọn báyìí…. Ẹ karo oooo
Ní dẹ́de agogo méjìlá sì àgó merin osan ni Yoruba má nki ara wọn báyìí wípé…. E ka san ooooooo
Ní dẹ́de ago merin ìrólé sì àgó mefa abo… E ku ìrólé oooooo
Second Term Revision and Readiness Test Yoruba Primary 3 Second Term Lesson Notes Week 1
Oruko: ……………………………………………………….……… Deeti: …………………….
Ise: Ede Yoruba
Kilasi: Oniwe Keta
Isoro n gbesi ni ile aro
1. Ojo ti awon omode lo be ile aro wo je ojo ……………… (a) Abameta (b) Eti (d) Aiku
2. …………………. Ni ohun ti awon alagbede fi maa n finna. (a) Ewiri (b) Omo owu
3. Kini oruko ti a n pe irnse ti alagbe fii n mu irin ninu ina? (a) amuga (b) emu
(d) reeki
4. Bawo ni a se maa n ki alagbede? (a) aroye o (b) aredu o (d) e mo o se o
5. Kini oruko ibi ise alagbede? (a) ile aro (b) ile ita (d) ile oja
Onka ni ede Yoruba
6. Kini oruko nomba yii ni ede Yoruba – 25? (a) aarundinlogbo (b)aarundinlogoji (d) aarundinlogun
7. Kini oruko nomba yii ni ede Yoruba – 40? (a) ogbon (b) ogoji (d) aadota
8. Kini oruko nomba yii ni ede Yoruba – 15? (a) aarudinlogun (b) aarundinlogoji (d) ogun
9. Kini oruko nomba yii ni ede Yoruba – 20? (a) ogbon (b) ogoji (d) ogun
10. Kini oruko nomba yii ni ede Yoruba – 35? (a) aarudinladota(b) aarundinlogoji (d) aarundinlogun
Kika ati kiko gbolohun kekeeke:
11. ……………………….ni o n di irun (a) Sola (b) Peju (d) Yemi
12. …………………………ni o n foe yin (a) Kemi (b) Tayo (d) Sade
13. ……………………………….ni o wo kaba (a) Gbemi (b) Bisi (d) Tayo
14. ………………………..ni o n foe se (a) Gbemi (b) Sola (d) Wunmi
15. ………………………….ni o n je eko (a) Peju (b) Bisi (d) Wunmi
Daruko nkan marun-un ti o wa ni inu ilu.
16. …………………………………………………………..
17. …………………………………………………………..
18. ……………………………………………………………
19. ……………………………………………………………
20. ……………………………………………………………
Akole:onka ni ede Yoruba lati ori aarun de ori ogorun(5-100)
5-Aaron
10-Eewa
15-Aarundinlogun
21-16-Erindinlogun
17-Etadinlogun
18-Ejidinlogun
19-okandinlogun
20-Ogun
21-Okanlelogun
22-Ejilelogun
23-Etalelogun
24-Erinlelogun
25-Arundinlogbon
26-Erindinlogbon
27-Etadinlogbon
28-Ejidinlogbon
29-Okandinlogbon
30-Ogbon
31-okanlelogbon
32-ejilelogbon
33-etalelogbon
34-erinlelogbon
35-Aarundinlogoji
36-erindinlogoji
37-etadinlogoji
38-ejidinlogoji
39-okandinlogoji
40-Ogoji
Ise kilaasi
Daruko awon nomba wonyii ni ede yoruba.
20
25
30
35
40
15
10
5
AKOLE:IPALOWO OJA NI ILE YORUBA
Mini a npe ni ipolowo oja? Ipolowo ni ona ti oja ngba ta ni kiakia tan ni kanmo kanmo, tabi niwarasesa,orisirise ona ni a ngba polowo oja awon naa ni awon wonyii
1 ipolowo oja ni ori lkiri
2 ipolowo oja pelu ipate.
3bipolowo oja lori ero ibanisoro.
4 ipolowo oja lori ero amulumawon.
5 ipolowo oja ninu iwe iroyin.
IPOLOWO OJA LORI IKIRI
Orisirisi ona ni awon ontaja fi polowo oja won ki oja le ta gege bi iru oja ti won npo lowo pelu idunu ati oyaya ni awon otaja fi npolowo oja.
Eje ka gbo die ninu awon oja ti won npolowo ati bi won se npolowo won bii
Agbado sise
Onisu sise
Elewa sise
Onimoinmoin
Eleja tutu
Oniyan.
Alagbado sise:langbe jinna o,oro ku ori ebe oloko ogbowo era gbado o ejagbo o gbona felifeli.
Onisu sise:onisu sise yin ti dele o o gbona felifeli o nto muyemuye onto wee.
Elewa sise:elewa sise yin ti dele o sokudale adalu o gnona felifeli e rewa olo e rewa oloyin eleyi o ni kokoro.abbbl
Ise kilaasi
Salaye bi a nse polowo awon oja wonyii
Alagbado
Elewa
Onisu sise
Imototo Borí Àìsàn Mọ́lẹ̀
Ayo Olopon Akole:Ere idaraya ni ile yoruba(ere ayo
Akole:Ere idaraya ni ile yoruba(ere ayo)
Irole patapata ni a maa nta ayo ni ile yoruba.Abe I gig ti afefe wa ni a ti nta ayo.Eniyan meji ni o maa nta ayo.Igi ti agbe iho mejila si ni a fi nse opon ayo iho mefa mefa fun awon otayo.
Eso igi ni omo ayo koro inu eso igi ni a nsa ti a fi nse omo ayo.Apa otun ni anta ayo si ni ile yoruba.Omo ayo mejidinladota nio ngbe ni oju opon.Omo ayo merin merin ni o ngbe inu iho kankan.Eso igi ni omo ayo koro inu eso igi ni ansa ti afi ase omo ayo.Igigbogboro gidi ti a gbe iho mejila si iho mefa ni apa otun mefa ni apa osi ni a npe ni opon ayo.Awon oluworan ayo ni a noe ni “osefe ayo”
ISE KILAASI
1.Igba wo ni a maa nta ayo ni ile yoruba (a)irole patapata (b)Aro kutukutu
2.Ibo ni a ti nta ayo? (a) ori omi (b)agbe igi
3.Eniyan me lo ni o nta ayo olopon (a)meji (b)merin
4.Apa ibo ni a nta ayo sii (a)osi (b)otun
5.Kini omo ayo (a)eso igi (b)agbalumo
ORIKI IBADAN
Akole:oriki ilu awon akeekoo
Asa oriki se pataki ose koko pupo ni ile yoruba bi a se ni oriki idile bee naa ni a ni oriki orile.
Oriki orile ni oriki ilu kankan ti abti wa gege bi omo yoruba eje ki a gbo oriki awon ilu bi meta
Ilu eko
Ilu ibadan
Ilu egba
ORIKI EKO
Eko adele,eko akete ile ogbon.Eko aromisa legbe legbe.Arodede maja.Okun lotun osa losi.Omi niwaju omi leyin.Omi ni ibi gbogbo.Ka jeba jeba ka je feselu.Ka mumi tupulu si.Eko niyen.Yanmu yanmu eyin igbeti nko?o le gbadie osoo ro.Obalende le yomo leti eni.Eko akete ile ogbon.Eni to deko tuo ogbon,ogbon oni toun dorun alakeji.
ORIKI IBADAN
Ibadan mesi ogo,nle oluyole,nibi ole gbe jare oloun.Ibadan majamaja lase kara iwaju leru.Ibadan ilu ojo,ilu ajayi,ilu ibikunle,ilu ogunmola,ologbodo keri keri loju ogun.Ibadan kii gbonile biko se ajayi.Aki waye ja ma larun kan lara ija igbooro larun Ibadan.
ORIKI EGBA
Egba omo lisabi
Oniruru egba po nile alake.Olugbonjobi lori won.Ija kan ijs kan,ti won nja loja,lo ntuluu egba orile,nlo so sodeke di baba ohun labe olumo.Oniruru egba po nile alake.Egba agura,egba oke ona,egba owu,egba alake,gbogbo won lo gba ijaye lalejo labe olumo.
Ise kilasi
1.ilu wo n aki bayi pe mesi ogo (a)Ibadan (b)eko
2.ilu wo ni aki bayii pe aromisa legbe legbe (a)epe (b)eko.
3.ilu wo ni a ki bayii pe omo lisabi,olugbonjobi lori won (a)ibadan (b)egba
Koko Ise: Ise oro Ise ninu gbolohun
Oro Ise ni emi gbolohun. Ohun kan naa ni opomulero to n toka isele inu gbolohun. Bi apeere:
-Dupe ‘pon’ omi.
Sade ‘ra’ bata.
Olu n ‘ro’ amala ni ori ina.
Ti a ba yo oro ise: pon, ra, ro kuro ninu awon gbolohun oke wonyi, ko lee ni itumo.
Ise Oro Ise:Oro Ise ni o maa n toka isele inu gbolohun. Eyi ni ohun ti oluwa se. Awon oro naa la fi sinu awon nisale yii.
– Sola (pon) omi.
– Dare (ko) ile.
– Jide (ge) igi.
– Iyabo (ka) iwe.
-Funmi (be) isu.
Ati bee bee lo.
Oro Ise le sise gege bi odindi gbolohun ki o si gbe oye oro wa jade
Bi apeere :
Jade.
Jeun.
Sun.
Sare. Ati bee bee lo.
A le lo oro ise lati pase iyisodi fun eniyan nipa lilo “ma” saaju ninu ihun gbolohun
Bi apeere ”
Ma sun.
Ma sare. Ati bee bee lo.
A n fi oro ise se ibeere nipa lilo wunre asebeere: da, nko ati bee bee lo.
Bi apeere:
Titi da?
Tope nko?
Èdè Yorùbá : akanlo ede ati itunmo re
Class: Pry three
Subject: Yoruba Studies
Akole: akanlo ede ati itunmo re
1. Se aya gbangba!
Itumo: ki eniyan doju ko isoro lai beru
2. Ya apa!
Itumo: ki eniyan ma mọ itoju owo tabi ohun ti a fi owo ra
3. Edun arinle!
Itumo: eni ti o ti lowo ri sugbon ti opa da rago tàbí kushe
4. Fi aake kori!
Itumo: ki eniyan ko jale lati se nkan
5. Fi ìgbà gba ga..
Itumo: idije,ki ẹniyan koju ara won lati dan agbara won woo
Akanlo ede ni ile Yoruba
Akanlo ede
Ise kilaasi
So itumo awon akanlo ede wonyii
1. Se aya gbangba
2. Edu arinle
3. Fi ìgbà gba ga
4. Ya apa
5. Fi aake kori
SECOND TERM EXAMINATION
CLASS: PRIMARY 3 SUBJECT: YORUBA LANGUAGE
NAME:……………………………………………………………………………………
IWE KIKA: – OTITO BORI
1.) Ilu wo ni itan yii ti sele _____ (a) Ayekooto (b) Ayedande
2.) Kini ise Mosun (a) alapata (b) onisowo
3.) Talo se ijanba fun Mosun? (a) Alake (b) Ayoka
4.) Bawo ni won se koba Mosun? (a) won gbe lo si ile ejo (b) won fi oja fayawo ranse si iso re
5.) Bawo ni Mosun se bo ninu isoro re?
(a) omode kunrin kan lo tu asiri (b) iya Arugbo kan lo tu asiri
ALO APAMO
1.) Alo o, alo o, opo baba alo kan laelae, opo baba alo kan laelae, ojo to ba de fila pupa ni iku de ba a, kini o (a) abela (b) atupa
2.) Alo o, alo o, ile gbajumo kiki imieran, kini o (a) osan (b) ibepe
3.) Alo o, alo o, oruku tindin tindin, oruku tindin tindin, oruko bi igba omo, gbogbo won lo yaje, kini o (a) ata (b) ewa
4.) Alo o, alo o, okun nho yaya, osa nho yaya, omo buruku tori ibo, kini o (a) irin (b) omorogun
5.) Alo o, alo o, ikoko rugudu feyin tigbo, kini o (a) igbin (b) ijapa
ALO APAGBE: IJAPA ATI ERIN
1.) Ijpa ati ____________ jo nse ore po (a) Ekun (b) Erin
2.) Awon Oba ilu maa fi ____________ bo ori won (a) Eranko (b) Eye
3.) _____________ se ileri fun ijapa (a) Ijoye (b) Oba
4.) Ijapa ologbon ewe fun erin ni ______________ aladun (a) robo (b) akara
5.) _______________ ni won fi din (a) orobo (b) oyin
SISE KANGO
1.) Iya __________ fe din kango (a) Alake (b) Adunni
2.) Baba ya _____________ wa lati oko (a) Agbado (b) Isu
3.) O bu epo____________ sinu agbada (a) ororo (b) epo pupo
4.) Kini alefi kango je (a) eko (b) ewa
5.) O da ina sinu ___________ (a) kanga (b) aaro
Yoruba Second Term Examination Primary 3
NAME:…………………………………………………………………………………… OTITO BORI
1. Ilu wo ni itan yii ti sele _____ (a) Ayokooto (b) Ayedande
2. Kii ni ise Mosun (a) agbejoro (b) onisowo
3. Talo se ijanba fun Mosun? (a) Agbalagba kan (b) Omodekunrin kan
4. Bawo ni won se ko ba Mosun? (a) won ba Mosun ja (b) won fi oja fayawo ranse si iso re
5. Bawo ni Mosun se bo ninu isoro re? (a) awon olopaa fi sile (b) omode kunrin kan lo tu asiri
ALO APAMO
1. Alo o, alo o, opo baba alo kan laelae, opo baba alo kan laelae, ojo to ba de fila pupa ni iku de ba a o, kini o (a) abela (b) omorogun
2. Alo o, alo o, ikoko rugudu feyin tigbo, kini o (a) ijapa (b) igbin
3. Alo o, alo o, kini koja niwaju oba ti ko ki oba, kini o (a) agbara (b) sigidi
4. Alo o, alo o, awe obi kana je doyo, kini o (a) enu (b) ahon
5. Alo o, alo o, yara kotopo, kiki egun, ki ni o (a) enu (b) ibepe
ALO APAGBE: IJAPA ATI ERIN
1. Kini awon oba fi maa nbo ori won laye atijo (a) eranko nla (b) eranko wewe
2. Bawo ni ijapa se je si erin (a) ota (b) ore
3. Ona wo ni ijapa gba mu erin wo ilu (a) o fun ni akara (b) o fun ni robo aladun
4. Ileri wo ni kabiyesi se fun ijapa (a) o da ohun ini resi meji (b) o je ijapa ni iya
5. Eko wo ni itan yii ko wa? (a) okowa ki a maa sora ni ile aye (b) o kowa ki a maa sora fun awon odale ore
SISE KANGO
1. Iya __________ fe din kango (a) Ayoka (b) Adunni
2. ________ ya agbado wa lati oko (a) Egbon (b) Baba
3. Iya Adunni re agbado naa sinu ______ nla kan (a) ikoko (b) agba
4. O bu epo pupa sinu _______ (a) ina (b) agbada
5. Nigba ti __________ gbona daadaa (a) epo (b) omi