IBA ISELE ORÍKÌ ORÍṢI IBA ÌṢẸ̀LẸ̀
Subject : Yoruba
Class: SS 3
TERM: FIRST TERM
WEEK: WEEK 4
OSE KERIN
IBA-ISELE
– Oriki
– Orisii iba-isele
– Awon wunren ti o toka iba-isele
Akonu:
ORI-ORO: ASIKO ATI IBA ISELE
ORIKI
EYA IBA ISELE
AKOONU
Asiko je oro girama ti a maa n lo lati fi toka si asiko ti isele kan waye. Orisii asiko meji lo wa ninu ede Yoruba.
- Asiko afanamoni.
- Asiko ojo iwaju.
Asiko Afanamoni: ni isele ti o ti sele koja tabi eyi ti o sele lowolowo ni asiko yii. Apeere
Olu lo ile
Baba je amala
Asiko Ojo Iwaju: eyi ni isele ti ko tii sele sugbon ti o si maa sele ni ojo iwaju. Apeere:
Bade yoo lo si ilu oba.
Baba yoo joba.
Iba Isele: Eyi ni oro girama ti o maa n siwaju oro-ise lati toka si iba isele ni pato
Eya iba-isele
Orisii iba-isele meta lo wa ninu ede Yoruba
- Iba-isele Adawa
- Iba-isele Aisetan
Aterere/Baraku
- Iba-isele Asetan
Ibere /Ipari
Iba-isele ninu asiko afanamonii
- Iba-isele Adawa
Iba-isele ninu asiko afanamonii ko ni atoka Kankan. Apeere:
Olu lo si oja
Won ra moto
- Iba-isele aisetan aterere
Eyi ni isele ti o si n lo lowolowo, isele ti ko kii pari, erun oro-ise ‘n’ ni atoka re. Apeere
Bolu n korin.
Won n fo aso.
Iba-Isele Aisetan Baraku
Eyi ni isele ti o maa n sele ni gbogbo igba. Atoka iba-isele yii ni a maa, maa n. Apeere:
Dayo a maa pariwo soro
Maa maa n we ni alaale
iii. Iba-Isele Asetan: Asetan ibere. Eyi ni isele ti ibere re ti bere sugbon ti gbogbo isele maa ko ti i pari tan. Atoka iba-isele yii ni, ti n, ti maa n ati maa. Apeere
Mama ti n dana
Bade ti maa n jeun
Sade a ti maa bo
Asetan Ipari: Eyi ni isele ti o ti pari patapata. Atoka iba-isele yii ni ‘ti’. Apeere:
Ayo ti korin.
Mama ti gbale.
Bolu ti de.
IGBELEWON
Kin ni iba-isele?
Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 174-176
ASA
IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE
Akoonu
Awon Yoruba gba pe oso ati aje wa, won tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe, o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si, ti won ko ni so o mo oso ati aje.
Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna-dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso
-ajogunba
wiwo egbe oso bee naa ni ti aje o le je, nipa ajogunba/wiwo egbe aje
Iyato laarin oso ati aye
Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso nigba ti awon aje je obinrin.
Litireso:- KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN
Iran keta ati ikerin
IGBELEWON
- a. Kin ni iba-isele?
- Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati aje.
APAPO IGBELEWON
- a. Kin ni iba-isele?
- Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati ajo.
3 Kin ni iba-isele?
4 Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari
ISE SISE
- Salaye lori ise abinibi kan ti o yeo yekeyeke
- Ipaje ni
- Ko apeere mejo.
IWE AKATILEWA
Mustapha, O.Eko Ede Yoruba Titun S.S. 2 o.i 85 – 93
ISE ASETILEWA
- ____ ni isele ti o ti bere sugbon ti ko tii pari (a) asetan ibere (b) aterere (d) aisetan
2 Atoka fun iba – isele aisetan aterere ni ____ (a) ni (b) n (d) ti
- Iba-isele ti ko ni atoka kankan ni ____ (a) Adawa (b) asetan (d) aisetan
- Kin lo poju ninu ohun ti oso ati aje n lo agbara won fun? (a) ire (b) ibe (d) alaafia
- ____ ni won n lo si inu to n run Adigun. (a) Apoogun (b) Apooro epa ijebu (d) oogun jedi
APA KEJI
- Salaye awon iba-isele won yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.
Iba- isele asetan ibere
Iba-isele aisetan aterere
Iba-isele aisetan baraku
Iba-isele asetan ipari
- Salaye lekun-un rere ohun ti o sele si Adigun ati owo ti won fi ran-an nise.