Àrọ̀kọ̀ Atonisona Alapejuwe Yoruba JSS 1 First Term Lesson Notes Week 10

Yorùbá JSS 1 First Term Lesson Notes Week 10


EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AROKO ATONISONA ALAPEJUWE

Aroko jẹ ohun ti a ro ti a ṣe akosile.

Aroko alapejuwe ni aroko ti o ma n ṣapejuwe eniyan, ibi kan, ati nkan to n ṣe gege bi a ṣe rii gan-an.

Apeere:

  1. Oja ilu mi
  2. Ẹgbẹ mi
  3. Ile-iwe mi
  4. Ounjẹ ti mo fẹran
  5. Ilu mi

Aroko Lori Ile-Iwe Mi

Oruko Ile-eko mi ni Edu Delight International School. O wa ni Ojule Keji-Ikerin, Opopona Ile-Epo, Oke-odo, Ipile Eko. Oludasile ile-iwe mi ni Dokita Dosumu. Ile-iwe mi jẹ ile oloke mẹta mẹta ti o ni ẹgbẹ kegbe, ti a si fi ilẹkun onirin si enu ona abawole rẹ.

Ile-iwe mi ni awo ewe gege bi aso ile-iwe wa. Iyara ikawe fun kilaasi girama ati alakobere po jantirere, bẹ́ẹ̀ ni ofisi àwọn oluko ati alase ile-iwe naa ko kere niye.

A ni yara ero ayara bi asa, yara imo sayensi, yara imo ede, yara ibi ikawe ati iyawe, yara ijeun.

A fi ododo ṣe ile-iwe mi, losoo bẹ́ẹ̀. Leyin ile-iwe mi, a ni papa isere fun awọn ere idaraya bi boolu alafese gba, ere idije, boolu alafowo gba, abbl.

Apapọ awọn ọmọ-ile mi le ni ọgọ̀run, awọn oluko wa le ni aadota. Awọn ọmọ ile-iwe mi jẹ ọmọ gidi nitori wọn n kọ wa ni eko-iwa, akojopo eko ile, bi a ti n huwa ni awujo ati eko Bibeli.

Ti a ba n sọ nipa awọn oluko wa, awọn oluko wa jẹ dangajia, wọn ni oyaya, iwa pẹlẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn mọ bí a ti n ba awọn obi ṣe.

Ọpọ awọn obi feran ile-iwe mi púpọ̀ nitori pé ibẹ ni awọn looko-looko ti o di ipo giga mu ni orílẹ̀-èdè yii ti jade, bẹ́ẹ̀ ni esin idanwo ase kegbe wo ile-ẹkọ giga ti yunifaasiti wọn maa n dara pọ̀. Mo fẹran ile-iwe mi nitori pé:

  • Awọn oluko wa kun ọjọ osuwon
  • O ni awọn ero ikawe igbalode
  • Agbegbe rẹ dun-un kawe
  • Wọn n kọ ni bi ati n jẹ ọmọ rere ni ile ati fun orílẹ̀-èdè lapapọ

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: OYA JIJE ATI OHUN ELO OYE JIJE

Bí a ṣe n joye ni ilu kan yato si bí a ṣe n joye ni ilu miran.

Makan-makan ni oye jije jẹ ni ile Yoruba.

Oniruuru Oye Jije ni Ile Yoruba

  1. Oye Oba
  2. Oye Baale
  3. Oye Iyalode
  4. Oye Ajiroba
  5. Oye Bobajiro
  6. Oye Iyalaje
  7. Oye Afobaje
  8. Oye Majekobaje
  9. Oye Ile
  10. Oye Eleto
  11. Oye Baba-Isegun
  12. Oye Gbajumo

Ohun Eelo Oye Jije

  1. Ewe Oye
  2. Etutu Lorisirisi
  3. Ileke Owo, Orun, Ese
  4. Ade-Oba
  5. Ilu Lorisirisi
  6. Igba Oye
  7. Irukere

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO-EWI

Ewi apileko litireso jẹ ijinle oro ti oku fun laakaye, ogbon ati oye ti a fi ona ede ati oro ijinle gbekele.

Awon Koko Ti A Ni Lati Tele Ti Aba N Ko Ewi Apileko:

  1. Eni Ti O Ko Ewi Naa: Mímọ̀ itan igbesi aye akewi
  2. Koko Oro: Onka-ewi gbodo mo koko ti ewi naa dale lori
  3. Eko Ti Ewi Naa N Ko Wa: Se Pataki lati mo
  4. Ona Ede Ati Asa Ti O Suyo: Onkawe gbodo le toka asa Yoruba ati oniruuru ona ede bii, owe, akanlo ede, afiwe, asorege abbl.

Igbelewon

  1. Kin ni aroko?
  2. Fun aroko atonisona alapejuwe loriki
  3. Ko apeere aroko alapejuwe mẹta
  4. Ko oniruuru oye jije ni ile Yoruba marun ati ohun elo oye naa
  5. Fun ewi apileko litireso ni oriki
  6. Ko ilana kiko litireso naa

Ise Asetilewa: Ko aroko lori ounje ti o fẹran ju


Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share