Igbagbo Awon Yoruba Nipa Olorun Eledumare

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Third  Term

 

Week : Week 1

 

Topic :

 

OSE KIN-IN-NI

 

EDE

LETA GBEFE

AKOONU: Leta

Adiresi

Deeti

Ikini ibere

Koko oro

Asokagba

Ikini ipari

Leta kiko ni ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Oun ni o duro fun aroko pipa ranse lode oni. A maa n fi ero ara eni han ninu iru leta (aroko) yii. Leta  pin si orisii meji awon naa ni: leta gbefe ati leta aigbefe. Leta gbefe ni leta si obi,ore, ibatan ati awon miiran ti o sun moni. Ilana leta gbefe ni: adiresi, deeti, ikini ibere, koko aroko, ikini ipari.

Kiko  adireesi:

oke apa otun ni a maa n ko adiresi eni ti o n ko leta si. Adiresi yii maa n ni awon nnkan wonyi ninu: nomba, adugbo,opopona, ipinle.

Fun apeere:

3, Opopona Ajibola,

Adugbo Bodija,

Ilu eko.

12-02-2021.

 

 

 

Kiko deeti: leyin ti a ba ko leta tan, a o ko deeti ojo, osu ati odun ti a ko  leta. Fun apeere: 22 : 3 : 2011. tabi 22 Erena, 2007.

Ikini ibere: apa owo osi lori ila ti o tele deeti ni a maa n ko eyi si. Fun apeere:

Omo mi owon, Omo mi tooto, Iya mi atata, Ore mi owon, Egbon mi tooto, Tunji mi atata,.

Koko oro: nibi ni a ti maa n ko ohun ti o mu wa ko leta gan-an. Ona meta ni abala yii pin si. Awon naa ni: ifaara (introduction) aarin (body      of the leta) igunle (conclution). Ninu ifaara ni a ti maa ko idi ti a fi ko leta lerefe tabi ni soki, inu aarin leta ni a ti maa n se alaye lekunrere fun eni  ti   a ko leta si nigba ti igunle maa je ibi ti a ti maa se igunle leta wa. Ni abala igunle yii, a le ki eniyan nibe.

Ipari ati oruko akoleta: apa owo osi ni isale ni eyi maa n wa. Fun apeere:

Emi ni omo yin,

Babatunde.

 

 

Baba re,

Adewale

 

Ore re,

Folashade.

 

 

 

 

IGBELWON

  • ko adireesi ile iwe re sile.
  • Se alaye perete lori koko oro leta.

 

IWE AKATILEWA

Oyembamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun (s.s.s 1) iwe kin-in-ni. University Press Plc. Oju iwe 17-19.

ASA

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA OLODUMARE

Akoonu: igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.

Orisiirisii oruko Olodumare

Ifihan ero Yoruba lori oruko Olodumare

Ohun ti opolopo awon eniyan lero ni wi pe awon Yoruba ko mo Olorun tele afi igba ti awon elesin Kristi ati awon islam to de. Iro patapata ni eyi. Awon Yoruba ti n sin Olorun ki awon elesin ajeji to de. Lara awon ohun ti o je ki a mo ni oniruuru oruko ti a n pe Olorun. Oun ni a n pe ni Olodumare tabi Eledumare,Olu orun,Olorun, Eledaa, Adedaa, Obanjigi, Oba ogo abbl.

Awon yoruba beru Olorun pupo bakan naa ni a si tun bowo fun. Idi niyi ti a ki I fi ku giri lo ba tabi ki a maa beere nnkan lowo re. Dipo bee a yan awon orisa kan gege bi asoju wa tabi alagbawi wa lodo re. Awon iru orisa bee ni Ogun, Sango, Orunmila, Obatala abbl. Awon wonyi ni awon Yoruba maa ran si Olorun nigba ti won ba fe gba nnkan lowo re.

Die lara awon oruko ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olorun ni:

  • Olowogbooro
  • Eleti gbaroye
  • Atererekaye
  • Awimayehun
  • Olodumare
  • Obanjigi
  • Olorun
  • Olu Orun
  • Oba Ogo.
  • Kabiyesi
  • Kaa bi o sii
  • Oba A tee ree kaye
  • Jingbinikin
  • Arogunmatidi
  • Arabaribiti
  • Aribirabata.

 

IGBELEWON

Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.

IWE AKATILEWA

1 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.oju iwe 95-97

2 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.oju iwe 181-18

 

 

IFAARA LORI LITIRESO ALOHUN TI A N FI ORO INU WON DA WON MO.

Awon litireso wonyi ki i ni isori kan taara, won o je mo esin bee naa ni won o je mo ayeye lo ju. Apeere won ni oriki, ofo, ese ifa, itandonwe, oro akonilenu, aalo, ewidowe, ede asiko abbl.

A     Oriki Orile (family name/praise): Oriki orile ni ewi alohun ti o da lori baba nla eni ati ibi ti won ti se wa. Apeere oriki orile ni onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Opomulero, Olofa, Ologbin-in Olufe, Iloko abbl.

B     OFO (incantation): Ofo je oro agbara ti awon Yoruba maa n lo pelu oogun. Ofo ni o n fi igbagbo awon Yoruba han ninu agbara oro. Aarin awon adahunse ati onisegun ni o ti wopo. Awon nnkan ti a fi maa n da mo ni: A ki i, oro ase, ebe, awitunwi, iforodara, afiwe.

D     ESE IFA (ifa divination ): Awon ni oro agbara ti awon onifa maa n lo. Awon babalawo/onifa ni o maa n da ifa. Awon ti won maa n da ifa maa n wo aso funfun, bata funfun pelu inu mimo. Awon ohun ti a fi maa n da ese ifa ni: Adia fun, ebo riru, awon oruko emi airi.

E     ORO AKONILENU; awon oro ti o soro sare pe ni oro akonilenu. Apeere oro akonilenu ni: obo n gbe obo gun ope, Alira n lora rela, Mo je dodo nido ma wa fi owo dodo pa omo onidodo ni idodo.

 

IGBELEWON

  • Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
  • Ko oriki orile marun-un sile.
  • Salaye perete lori ofo.

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 55-58 Copromutt (publishers) Nigeria Limited

 

APAPO IGBELWON

  • ko adireesi ile iwe re sile.
  • Se alaye perete lori koko oro leta.
  • Ko orisii ewi alohun marun-un ti a n fi oro inu won da won mo.
  • Salaye meta ninu won.
  • Ko oruko Olodumare mejo sile.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Ko ewi alohun ajemayeye mewaa sile ati ibi ti okookan ti wopo.

 

ISE ASETILEWA

  • Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
  • Ibi ti adireesi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
  • Adireesi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta  ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun.
  • Ewo ni ki i se ara won? (a) oro akonilenu (b) iyere ifa (d) oriki.
  • Ewo ni itan ati oro bi ‘omo’ ti maa n wopo? (a) oro akonilenu (b) iyere ifa (d) oriki.

APA KEJI

  1. Ko adireesi ile re sile.
  2. Ko awon ewi ti a fi oro inu won da won mo ki o si salaye meta ninu won.

 

 

 

 

 

 

 

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share