Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì Yoruba Primary 1 Second Term Lesson Notes
DEETI: ỌJỌ́BỌ̀ ỌJỌ́ KỌKÀNLÁ OṢÙ SẸẸRẸ, 2024. KÍLÁÀSÌ: alákọ̀bẹ́rẹ̀ olódún kíní IṢẸ́: YORÙBÁ ỌJỌ́ ORÍ AKẸ́Ẹ̀KỌ́: ỌDÚN MẸ́FÀ SÍ MÉJE ORÍ Ọ̀RỌ̀: Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ: Ayọ̀ Adésànyà et’al(2018) Ìwé Kíkà Àsìkò Tuntun, Ojú ewé Kejì. OHUN ÈLÒ ÌKỌ́NI: Sáàtì tí ó ṣe àfihàn àẁorán nǹkan lórísìírísìí. ÌMỌ̀ ÀTẸ̀YÌNWÁ: Akẹ́kọ̀ọ́ ti ní ìmọ̀ nípa nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ rí ÈRÒŃGBÀ: NÍ ÌPARÍ Ẹ̀KỌ́ YÌÍ, AKẸ́KỌ̀Ọ́ YÓÒ LE ṢE ÀWỌN NǸKAN WỌ̀NYÍ
- Dárúkọ àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé
- Dá àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé mọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
- Ṣàlàyé ìwúlò nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́
ÌJÍRÒRÒ: Àwọn nǹkan tó wà nínú kíláàsì
- Àga
- Tábìlì
- Aago
- Gègé
- Ìwé
- Tabili
- Pátákó ìkọ̀wé
- Ìfàlà
- Fáánù
- Ẹfun ìkọ̀wé
Ìgbésẹ̀ kínńí: olùkọ́ ṣàfihàn àwọn ohun èlò ìkọ́ni Ìgbésẹ̀ kejì : olùkọ́ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìgbésẹ̀ kẹta: olùkọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyè láti dárúkọ àwọn ohun èlò inú kíláàsì Ìgbésẹ̀ kẹrin: olùkọ́ fi ààyè sílẹ̀ fún akẹ́kòó láti ṣe ìdámọ̀ àwọn ohun èlò inú kíláàsì àti ìwúlò wọn ÌGBÉLÉWỌ̀N: olùkó bèèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyì lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Dárúkọ ohun márùn-ún tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ
- Sọ ìwúlò àwọn ohun èló yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́
IKADII: Olùkọ́ kádìí ẹ̀kọ́ náà nílẹ̀ nípa ṣíṣe àlàyé ráńpẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà. IṢÉ ÀṢETILÉWÁ: Ya àwòrán ohun méjì tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ.
Related
Related Posts
Discovering Agriculture: Fun Lessons for Primary 1 Explorers


Meaning of Sounds and Music Cultural and Creative Arts Primary 1 First Term Lesson Notes Week 2
A—Aaja. Yorùbá
About The Author
Edu Delight Tutors
Am a dedicated educator with a passion for learning and a keen interest in technology. I believe that technology can revolutionize education and am committed to creating an online hub of knowledge, inspiration, and growth for both educators and students. Welcome to Edu Delight Tutors, where learning knows no boundaries.