Silebu Ninu Èdè Yorùbá JSS 1 First Term Lesson Notes Week 4

OSE KERIN

EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: SILEBU

Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo. Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.

Ihun oro orusilebu kan le je:

  1. Faweli nikan – (F)
  2. Apapo konsonanti ati faweli (KF)
  3. Konsonanti aranmupe asesilebu (N)

Apeere faweli nikan:

Gbogbo faweli aramupe ati aramupe je ihun oro onisilebu kan:

  • a, e, i, o, u
  • an, en, in, on, un

Lilo won:

  • Mo-ra-a (silebu kan ni “a, i, on, ati un”)
  • Mo-ri-i
  • Tolu mo-on
  • Baba-fun-un

Apeere apapo konsonanti ati faweli (KF):

  • Lo – KF
  • Je – KF
  • Sun – KF
  • Fe – KF
  • Gba – KF
  • Ta – KF
  • Ge – KF
  • Ke – KF
  • Ra – KF
  • Ran – KF

EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won

Asa ikini je okan lara iwa omoluabi. O je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere dandan ni ki omokurin dobale gbalaja ki omobirin si wa lori ikunle ti won ba n ki agba.

Ikini ni aarin eya Yoruba:

Ede Ajumolo

  • Ede Adugbo
  • Ilu
  • E kaa-aro – Wen kaaaro (Ijebu)
  • Nkoo Oro – Ekiti
  • In kuo u ro o – Ilesa
  • O koo ri ro – Akoko
  • E kaaro – Ife

Apeere miran:

  • Alangbaa ti wo le – Oyo
  • Olo do gba ti ole – Ijesa
  • Ijon gba ti wo le – Ijebu

Ounje eya Yoruba:

Ouje je ohunkohun ti eniyan tabi eranko n je tabi mu ti o si n sara lore. Orisirisi awon agbegbe ni ile Yoruba ni o ni iru ounje ti won feran.

  • Ondo ati Ekiti – Iyan
  • Ijebu – Ikokore
  • Egba – Laafu
  • Ibadan – Oka/amola

Ona ti a n gba se awon ounje ni ile Yoruba:

  1. Ewa:
    • Won a sa ewa
    • Won a gbe omi ka ori ina
    • Bi omi ba ho, won a da ewa sii
    • Won a re alubosa sii
    • Bi ewa ba ti fe jinna, won a fi ata lilo epo ati iyo sii
    • Leyin ti o ba ti jinna, o ti di jije
  2. Oole / Moin Moin:
    • Won a bo eepo ewa kuro
    • Won a lo ewa pelu ata ati alubosa
    • Won a pon ewa sinu ewe
    • Won a gbe e kana
    • Bi o ba jina, o di jije
  3. Akara:
    • Won a bo ewa
    • Won a lo ewa pelu ata
    • Won a gbe epo kana
    • Won a re alubosa si ewa lilo
    • Won a da ewa lilo die die sinu epo gbigba
    • Bi o ba din tan, o di jije
  4. Isu Sise:
    • Won a bo eepo ara isu danu
    • Won a gee si wewe
    • Won a gbe ekana pelu omi
    • Won a fi iyo sii, won a si de ikoko naa
    • Bi o ba jina, o jije
  5. Iyan:
    • Won a be isu
    • Won a gee si wewe
    • Won a da isu si ori ina pelu omi ninu re
    • Won kii fi iyo si bi isu jije
    • Bi o ba jinna, won a gun ninu odo
    • Leyin eyi, won a fi obe ti o wu won jee
  6. Asaro:
    • Won a be epo isu danu
    • Won a gee si wewe
    • Won a gbe omi lena
    • Won a da eroja bi ata, epo, eja, iyo, ede alubosa abbl sinu re
    • Bi omi ba ti ho, won a da isu sii
    • Won a roo po
    • Bi o ba jinna, o di jije

Igbelewon:

  1. Fun ounje ni oriki.
  2. Ko eya Yoruba merin ki o si ko ounje ti won feran ju.
  3. Kin ni silebu?
  4. Ko ihun silebu pelu apeere meji meji.

Ise asetilewa: Bawo ni a se n se ekuru ati obe gbegiri nin ile Yoruba.