Yorùbá JSS 1 First Term Lesson Notes Week 9
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE
ILANA FUN KIKO AROKO
- Yiyan Ori-oro: Yan akọle pataki ti aroko rẹ yoo tẹle.
- Sise Ilapa Ero: Ronu jinlẹ ki o si ṣeto ero rẹ ni kọọkan ipin ti aroko rẹ.
- Kiko Aroko:
- Aroko yẹ ki o jẹ kedere ati ṣoki.
- Lo awọn koko pataki ninu aroko rẹ.
- Ṣe ipari ti o mu gbogbo ero rẹ pọ.
- Ojulowo Ede: Lo ede Yoruba to peye ati ṣafikun afiwe ti o yẹ.
ORISI AROKO
- Aroko Atonisona Alepejuwe: Aroko ti o n ṣapejuwe ohun kan tabi iṣẹlẹ.
- Aroko Asariyanjiyan: Aroko ti o n ṣakoso tabi ṣe idanwo ọrọ kan.
- Aroko Atonisona Oniroyin: Aroko ti o n sọ itan tabi awọn iroyin.
- Aroko Onileta: Aroko ti o n ṣe akojọpọ ati ọrọ pẹlu ọna ayaworan.
- Aroko Ajemo: Aroko ti o n fi ojuṣe tabi awọn ohun pataki han.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL
- Oruko Abiso: Oruko ti a fun omo ni ibamu pẹlu ipo ebi nigba ti a bi.
- Apeere:
- Fijabi: Omo ti a bi nigba ija ninu ebi.
- Abosede: Omo ti a bi ni ọjọ Sẹsẹ.
- Oruko Amutorunwa: Oruko ti a fun omo da lori ipo ti o wa nigba ti a bi.
- Apeere:
- Taiwo: Omo ti o kọkọ jade nigba ti a bi ibeji.
- Kehinde: Omo ti o kehin nigba ti a bi ibeji.
- Oruko Oriki: Oruko iwuri ti a n fi fun omo tuntun.
- Apeere:
- Adeola: Ado ati owo.
- Ayinde: Eni ti a n yìn.
- Oruko Abiku: Oruko ti a fun omo ti o n ku ni igba mejeji.
- Apeere:
- Kosoko: Omo ti o n ku ni igba mejeji.
- Oruko Inagije: Oruko ti a fi n pe eniyan ti o ni iwa rere.
- Apeere:
- Ibadiaran: Eni ti o ni iwa rere.
- Oruko Idile: Oruko ti o ni ibatan si ipo idile tabi iṣẹ abinibi.
- Apeere:
- Idile Oloye: Oyebode.
- Idile Oba: Adeniyi.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN
Litireso Apileko Ere-Onitan: Iwe ere ti onkowe kọ lati sọ itan tabi iṣẹlẹ kan.
Awọn Ohun ti Onkowe Litireso Ere-Onitan Gbodo Fi Sokan:
- Igbesi-aye Onkowe: Mọ nipa igbesi-aye onkowe.
- Itan Inu Iwe: Mọ itan inu iwe naa.
- Awon Eda Itan: Mọ awọn ẹda itan inu iwe.
- Ibudo Itan: Mọ ibi itan naa ti waye.
- Koko Oro-Onkawe: Mọ ohun ti itan naa da lori.
- Asa Yoruba: Mọ asa Yoruba ti o yẹ.
- Ihuwasi Eda Itan: Mọ ihuwasi awọn ẹda itan.
Igbelewon
- Kini aroko?
- Ko ilana kiko aroko.
- Daruko orisi aroko marun-un.
- Fun asa isomoloruko ni oriki.
- Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun-un ki o si salaye pelu apeere.
- Kini litireso apileko ere-onitan?
- Ko awon ohun ti onkowe litireso ere-onitan gbodo fi sokan.
Ise Asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone
OSE KESA-AN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.
Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re lori pepa
ILANA FUN KIKO AROKO
- yiyan Ori-oro: A ni lati fa ila teere si abe ori-oro ti a n ko aroko le lori
- sise ilapa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero okan wa ni okookan ninu ipinro kookan ki o le ye onkawe
- Kiko Aroko:-
- Alaroko gbodo ronu ohun ti o ye ki o je ifaara, ko gbodo gun ju
- Aarin aroko ni a o ti lo awon ojulowo koko oro bi a se lo won ninu ilapa ero. sipeli akoto ode-oni ni ki a fi ko aroko yii
- Ikadii:- eyi ni ipari aroko
- Ojulowo ede se pataki ninu aroko bii, Afiwe, akanlo ede abbl , ni akekoo gbodo se amulo.
ORISI AROKO
- Aroko atonisona alepejuwe
- Aroko asariyanjiyan
- Aroko onileta
- Aroko ajemo – isipaya abbl
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL.
Gege bi owe Yoruba ti o wipe “ile la n wo, ki ato so omo loruko” A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, ki won to fun omo loruko, won a se akiyesi iru ipo ti omo wa nigba ti iya re bii tabi ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa.
A pin oruko jije ni ile Yoruba si isori isori. Awon ni wonyi
- Oruko Abiso
- Oruko Amutorunwa
- Oruko Abiku
- Oruko Inagije
- Oruko Idile
Oruko Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni ibamu pelu iru ipo ti ebi baba tabi iya omo naa wa nigba ti abi
Apeere ati itumo
- Fijabi- omo ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi
- Kuponiyi – omo ti a bi leyin iku alafokantan tabi akikanju
- Abosede – omo ti a bi lojo ose
- Odunjo – omo ti a bi lasiko odun ifa tabi odun miiran abbl
Oruko amutorunwa:- Eyi ni oruko ti a fun omo gege bi ipo ti omo wa nigba ti iya re bi. Apeere,
- Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti a bi ibeji
- Kehinde: omo ti o keyinde nigba ti a bi ibejiIdowu: omo ti a bi tele ibeji
- Alaba: omo ti a bi tele idowu
- Idogbe: omo ti a bi tele alaba
- idoha: omo ti a bi tele idogbe
- Olugbodi: omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa
- Ilori: omo ti a bi nigba ti iya re ko se nnkan osun
- Omope: omo ti o lo ju osu mesan-an lo ninu iya re ki a to bi.
Oruko oriki: Eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun. Won n lo o lati fi ki ni tabi gbori yin fun eniyan. Apeere,
Adeola, Abefe, Aduke, Adufe, Amoke, Asake, Ayinde, Ariike, Akanni abbl
Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi a se nbi ni o n ku, nigba ti a ba tun bi won pada ti won a tun pada ku. Apeere
Kosoko, kukoyi, durojaye, oruko tan duroriike, bamijokoo, abii na, omotunde, aja, durosimi, kokumo malomo abbl.
Oruko inajije: eyi ni oruko apeje ti ore tabi ebi fi n pe eniyan. O je oruko gbajumo. Apeere,
Ibadiaran, Idileke, Owonifaari, olowojebutu, epolanta, Aponbepore, Awelewa, Ekufunjowo, Eyinmenugun, Dudummadan abbl.
oruko idile: Opo idile ni o maa n fun awon omo ni oruko ni ibamu pelu ipo idile tabi ibamu pelu orisa, ise abinibi ti idile naa n se. apeere,
Idile oloye: Oyebele, Oyediran, Oyewole, Oyekanmi
Idile Oba: Adeooti, Adekanmibi, Adeniyi, Adesola
Idile ola: Oladoye, Oladapo, Olayeni, Olajide
Idile Olorisa: Orisatele, Orisaseye, Orisagbemi, Aborisade
Idile Alawo/Onifa: Faleti, Fabunmi, Fafuke, Fagbohun.
Idile Eleeyin: Olojede, Ojewole, Eeyinjobi
Idile Ede: Oderinde, Odewole, Odeyemi abbl.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN
Litireso apileko ere-onitan ni iwe ere atinude ti onkowe ko lati so ohun ti o sele ninu itan tabi ti o sele loju aye.
Apeere iwe ere-onitan ni “Efusetan Aniwura ti Akinwumi Isola ko
Onkawe ere-onitan gbode mo awon koko wonyi,
- O gbodo mo nipa igbesi-aye onkowe
- O gbodo mo itan inu iwe naa
- O gbodo mo awon eda itan inu iwe naa
- O gbodo mo ibudo itan – adugbo tabi ilu ti ere naa ti waye
- Onkawe gbodo maa fi oye ba awon isele inu ere-onitan naa lo ni sise-n-tele.
- Koko oro-onkawe gbodo mo ohun ti itan naa dale lori , ki o si le toko si ete ti won ri ko.
- O gbo mo asa Yoruba ti o suyo
- O gbodo mo nipa ihuwasi eda itan
- Akekoo gbedo sakiyesi ohun ti o gbadun ninu ere-onitan naa.
Igbelewon:
- Kin ni aroko?
- Ko ilana kiko aroko
- Daruko orisi aroko marunun
- Fun asa isomoloruko ni oriki
- Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun un ki o si salaye pelu apeere
- Kini litireso apileko ere onitan?
- Ko awon ohun ti onkawelitireso ere onitan gbodo fi sokan
Ise asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone