Ọ̀rọ̀ Àpẹ̀juwe àti Ọ̀rọ̀ Àpónlè Nínú Èdè Yorùbá – Itumọ̀, Iṣẹ́, àti Àpẹẹrẹ
ÈDÈ YORÙBÁ – ÌṢẸ́ Ọ̀RỌ̀: Ọ̀RỌ̀ ÀPẸJỌ́WÉ ATI Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ̀NLẸ̀ NÍNU GBÒLÓHÙN
Ọ̀RỌ̀ ÀPẸJỌ́WÉ
Ìtúpalẹ̀ Ọ̀rò Àpẹ̀jọ̀wé
Ọ̀rọ̀ àpẹ̀jọ̀wé ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ nínu gbólóhùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń yàn ọ̀rọ̀-orúkọ gẹ́gẹ́ bí àbáwọlé wọn.
Ìṣe Ọ̀rọ̀ Àpẹ̀jọ̀wé Nínú Gbólóhùn
-
Ó lè yàn ọ̀rọ̀-orúkọ ní ipò Olúwa:
- Àpẹẹrẹ:
- Òròkò rere san ju wúrà àti fàdákà lọ.
- Ìwà búkún kò yẹ ènìyàn.
- Àpẹẹrẹ:
-
Ó lè yàn ọ̀rọ̀-orúkọ ní ipò Àbò:
- Àpẹẹrẹ:
- Iníolúwa là ìgi gbígbẹ.
- Ayìndé wọ aṣọ fúnfún.
- Àpẹẹrẹ:
-
A le sẹ́da ọ̀rọ̀ àpẹ̀jọ̀wé láti inú ọ̀rọ̀-ìṣe:
- Àpẹẹrẹ:
- Oro Ise → Ọ̀rọ̀ Àpẹ̀jọ̀wé tí a sẹ́da
- Gá → Gíga
- Lé → Lílẹ̀
- Sùn → Sísùn
- Fé → Fífẹ̀
- Kà → Kíkà
- Àpẹẹrẹ:
-
Àkíyèsí:
- A lè ṣe àtẹ̀numọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpẹ̀jọ̀wé nínú gbólóhùn.
- Àpẹẹrẹ:
- Èrè lílẹ̀ lílẹ̀ ni Bólú ń ṣe.
- Ìbì gíga gíga ni mo ń lọ.
-
Ọ̀rọ̀ Àpẹ̀jọ̀wé ń ṣe ìṣe àtẹ̀numọ́:
- A lè gbé wọn sàájú ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n yàn.
- Àpẹẹrẹ:
- Òmùgò ọmọ kì í dára.
- Àgbèrè aya kò ṣùnwọ̀n.
- Àkò okuta ni a fi ń pa èkùró.
Ọ̀RỌ̀ ÀPỌ̀NLẸ̀
Ìtúpalẹ̀ Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀
Ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí a máa ń fi kún ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe, kí ó le ye ní dáadáa. Wọ́n máa ń ṣe ẹ́pọ̀n nínú gbólóhùn.
Ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀
-
Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀ Pón-n-bẹ̀lẹ̀ (Ti a kò ṣẹ́dà)
- Àpẹẹrẹ:
- Aṣọ rẹ̀ mọ̀ tònì.
- Yẹmí pupa fòò.
- Ilé gà gógórò.
- Àpẹẹrẹ:
-
Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀ tí a ṣẹ̀dà (Ti a ṣàtúnṣe sí ìtúpalẹ̀ rẹ̀)
-
Àpẹẹrẹ:
Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀ Pón-n-bẹ̀lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀ tí a ṣẹ̀dà Tònì Tònìtònì Wèrè Wèrèwèrè Làú Làùlàù Rákò Rákòràkò
-
Ìṣe Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlẹ̀ Nínú Gbólóhùn
-
Ó máa ń tọ́ka sí ìṣẹ̀lè nínú gbólóhùn:
- Àpẹẹrẹ:
- Òlú yọ̀ kéle-kéle wọ ilé.
- Ọmọ náà ń rìn jáùajàu.
- Àpẹẹrẹ:
-
Ó máa ń tọ́ka sí ohun kan tí a ń ṣe tó ti dé gòngò (climax):
- Àpẹẹrẹ:
- Ọ̀kọ̀ náà jóná ráùráù.
- Àdúpé jẹun náà pátápátá.
- Àpẹẹrẹ:
-
Ó máa ń tọ́ka ibi pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé:
- Àpẹẹrẹ:
- Àwọn ológìnní sá pamọ́ sínú igbó.
- Rémílékún ṣe ìgbéyàwó ní ilé ìjọsìn.
- Jọláde lọ kì Kábíyèsí ní ààfín.
- Àpẹẹrẹ:
-
Ó n tọ́ka ìdí tí ìṣẹ̀lẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀:
- Àpẹẹrẹ:
- À ń ṣe iṣé kí a lè ní owó.
- Sádé kò kàwé nítorí kò ní owó.
- Òbí ń tọ ọmọ kí wọ́n lè fún wọ́n ní ìsinmi.
- Àpẹẹrẹ:
-
A ń lo ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ̀ láti fi irísí nnkan hàn:
- Àpẹẹrẹ:
- Òṣùpá náà mólẹ̀ ròkòsò.
- Iná náà ń wọ rákòràkò.
- Àpẹẹrẹ:
ÌGBÉLẸ̀WỌ́N
- Kọ ìṣe ọ̀rọ̀ àpẹ̀jọ̀wé àti ọ̀rọ̀ àpọ́nlẹ̀ méjì méjì pẹ̀lú àpẹẹrẹ.
ÌṢẸ́ ÀSETÍLẸ̀WỌ́N
- Orisun: Yorùbá Àkàyèg̣è Ìwé Àmúṣèsè fún Ìlé Ẹ̀kọ́ Sékóndiri Kẹ̀kẹ́rẹ́ Ìwé Kìn-ìn-ni
- Awon Onkọwe: O. L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki
- Oju iwe: 16, Ẹkọ Kẹtàlá
ÈDÈ YORÙBÁ – Ọ̀NKA (101 – 200)
Ọ̀nka Yorùbá ni ìlànà tí a fi ń kà nnkan ní irọrùn.
101 – 120
- 101 – Òókànlélógórùn-ún
- 102 – Èjìlélógórùn-ún
- 103 – Ẹ̀tàlélógórùn-ún
- 104 – Ẹ̀rìnlélógórùn-ún
- 105 – Ààrùndínláàdófà
- 110 – Ààdófà
- 115 – Ààrùndínlógófà
- 120 – Ògófà
121 – 140
- 121 – Òókànlélógófà
- 125 – Ààrùndínláàdójé
- 130 – Ààdójé
- 135 – Ààrùndínlógójé
- 140 – Ògójé
141 – 160
- 141 – Òókànlélógójé
- 145 – Ààrùndínláàdójọ
- 150 – Ààdójọ
- 155 – Ààrùndínlógójọ
- 160 – Ògójọ
161 – 180
- 165 – Ààrùndínláàdósán
- 170 – Ààdósán
- 175 – Ààrùndínlógósán
- 180 – Ògósán
181 – 200
- 190 – Ààdówà
- 195 – Ààrùndínnìgbà
- 200 – Ìgbà
ÌGBÉLẸ̀WỌ́N
- Kí ni ọ̀nka?
- Kà ọ̀nka Yorùbá láti 101 dé 200.
-
Oro apejuwe maa n toka si ____ inu gbolohun.
a) Isori oro
b) Isele
c) Oro-oruko
d) Awon eeyan -
Oro apejuwe le yan oro-oruko ni ipo ____.
a) Oluwa ati abo
b) Opo ati adako
c) Alakori ati alajemo
d) Opo ati awujo -
Oro apejuwe ti a seda ni a maa n ri lati ara ____.
a) Oro-aponle
b) Oro-ise
c) Oro-oruko
d) Oro-atunyewo -
“Ibi giga giga ni mo n lo” je apeere ____ oro apejuwe.
a) Ti a seda
b) Pon-n-bele
c) Atunyewo
d) Alakanpo -
Oro apejuwe n se ise ____.
a) Atunse gbolohun
b) Atonumo
c) Akoso oro
d) Oro isele -
Oro-aponle maa n fi kon itumo ____ han.
a) Oro-ise
b) Oro-oruko
c) Oro-atunse
d) Oro-abuda -
Oro-aponle pon-n-bele ni awon oro ti a ko ____.
a) Seda
b) Seda kuro
c) Fikun
d) Fi idi re mule -
“Yemi pupa foo” je apeere ____ oro-aponle.
a) Ti a seda
b) Pon-n-bele
c) Atonumo
d) Alakanpo -
Oro aponle ti a seda maa n se ise ____ oro-aponle pon-n-bele.
a) Aponle
b) Apetunpe
c) Atunse
d) Abuda -
“Oko naa jona raurau” je apeere oro-aponle ti n toka si ____.
a) Ibi ti isele ti sele
b) Ipele isele to ti de gongo
c) Idi ti isele fi sele
d) Oro-aponle pon-n-bele -
“Remilekun se igbeyawo ni ile ijosin” je apeere oro-aponle ti n toka si ____.
a) Ibi ti isele ti sele
b) Idi ti isele fi sele
c) Igbese isele
d) Oro-aponle pon-n-bele -
Oro-aponle maa n toka si ____.
a) Sise kan pato
b) Ibi ti isele ti sele
c) Opo ati adako
d) Opo ati awujo -
“Sade ko kawe nitori ko lowo” je apeere oro-aponle ti n toka si ____.
a) Idi ti isele fi sele
b) Ibi ti isele ti sele
c) Igbese isele
d) Oro-aponle pon-n-bele -
“Osupa naa mole rokoso” je apeere oro-aponle ti n toka si ____.
a) Irisi nnkan
b) Ibi ti isele ti sele
c) Idi ti isele fi sele
d) Aponle pon-n-bele -
Oro aponle maa n je ki gbolohun ____.
a) Ye kedere
b) Kere sit
c) Sise eto oro
d) Kuro ninu gbolohun
-
Kini oro apejuwe?
Ans: Oro apejuwe ni awon oro ti o n toka isele inu gbolohun, o si maa n yan oro-oruko. -
Ki ni ise oro apejuwe ninu gbolohun?
Ans: Oro apejuwe maa n se ise atenumo ati apejuwe oro-oruko ninu gbolohun. -
Bawo ni a se le seda oro apejuwe?
Ans: A le seda oro apejuwe lati inu oro-ise. Fun apeere, “ga” di “giga” ati “le” di “lile”. -
Kini oro-aponle?
Ans: Oro-aponle ni oro ti o fi kon itumo oro-ise han ninu gbolohun. -
Ki ni isori oro-aponle?
Ans: Oro-aponle pin si meji: pon-n-bele ati ti a seda. -
Kini apeere oro-aponle pon-n-bele?
Ans: Apeere ni “Aso re mo toni” ati “Yemi pupa foo”. -
Kini oro-aponle ti a seda?
Ans: Oro-aponle ti a seda ni awon oro to je atunse oro-aponle pon-n-bele, fun apeere: “Toni” di “Tonitoni”. -
Kini ise oro-aponle ninu gbolohun?
Ans: Oro-aponle maa n se ise apejuwe isele, ipari isele, ibi isele, ati idi isele. -
Bawo ni a se lo oro-aponle lati fi han ibi ti isele ti sele?
Ans: Apeere ni: “Remilekun se igbeyawo ni ile ijosin”. -
Bawo ni oro-aponle se le toka si idi ti isele fi sele?
Ans: Apeere ni: “Sade ko kawe nitori ko lowo”. -
Kini idi ti a fi n lo oro-aponle?
Ans: A n lo oro-aponle lati fi irisi, ipo, tabi idi isele han ninu gbolohun. -
Kini apeere oro-aponle ti o n fi irisi nnkan han?
Ans: Apeere ni “Osupa naa mole rokoso”. -
Bawo ni a se le fi oro-apejuwe yan oro-oruko ni ipo abo?
Ans: Fun apeere: “Inioluwa la igi gbigbe”. -
Kini idi ti oro-aponle fi se pataki ninu ede Yoruba?
Ans: Oro-aponle maa n fi itumo gbolohun ye kedere. -
Kini iyato laarin oro-apejuwe ati oro-aponle?
Ans: Oro-apejuwe n se apejuwe oro-oruko, lakoko ti oro-aponle n fi itumo oro-ise han.
Evaluation Questions
- Ki ni oro apejuwe?
- So isori oro apejuwe meji.
- Fun apeere oro apejuwe ti a seda meji.
- Ki ni oro-aponle?
- So isori oro-aponle meji.
- Fun apeere oro-aponle pon-n-bele meji.
- Fun apeere oro-aponle ti a seda meji.
- Bawo ni a se le fi oro-aponle toka si ibi ti isele ti sele?
- Fun apeere oro-aponle ti o n fi idi ti isele fi sele han.
- Kini ipa oro-aponle ninu ede Yoruba?