ONKA YORUBA
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Second Term
Week : Week 1
Topic : Ooka Yoruba
OSE KIN-IN-NI
ONKA YORUBA (301- 500) DEETI……………………
Gege bi a ti a so seyin pe iyato diedie yoo ba onka 20, 40, 60, ati 80 ni kete ti a kuro lori igba (200).
Fun apeere:
20 okoo
40 oji
60 ota
80 orin
300 ni a n pe ni oodunrun.
400 je irinwo ti 500 maa je eedegbeta
(600-100)=500. 600 ni a pe ni egbeta (200 x 3).
300 oodunrun
320 okooleloodunrun
340 ojileloodunrun
360 otaleloodunrun
380 orinleloodunrun
400 irinwo
420 okoolerinwo
440 ojilerinwo
460 otalerinwo
480 orinlerinwo
500 eedegbeta
IGBELEWON
1 Ko awon onka wonyi sile 320, 340, 460, 480, 490
2 ko awon onka wonyi sile 330, 350, 370 430, 470.
IWE AKATILEWA
1 Egbe Akomolede ati Asa (2002) Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longman Nig Ltd oju iwe 24-28
ASA ISOMOLORUKO
AKOONU
- OHUN ELO ISOMOLORUKO
- ETO ISOMOLURUKO
- EWI ATENUDENU TO JE MO IKOMOJADE
Ebun nla gbaa ni Yoruba ka omo si, won si gba wi pe ko si iru dukia ti Olodumare le fun eniyan ti o bori omo. Nitori idi eyi inu won maa n dun pupo nigba ti Oluwa ba yonu si awon idile kan to fi omo titun ta won loore.
Orisirisi ona ni awon Yoruba n gba so omo loruko. Awon miiran a maa wo sababi, asiko ati igba ti won loyun omo naa titi won fibi sile, boya won wa ninu idunnu tabi isoro nigba ti won loyun re ti o wa se pe nigba ti won bii gbogbo oke isoro won di petele, iru ipo bee a maa han ninu oruko omo bee. Oruko Yoruba a tun maa fi iru esin ti idile tabi ebi kan n sin han. Omiran yoo maa fi ise owo ti won se han.
Ni aye atijo, awon obi mejeeji, iya ati baba ni o ni ase lati so omo won loruko ni ojo kejo ti won ba bi omo naa, sugbon oruko ti baba tabi ebi baba ba fun omo ni won maa n te mo o lara ju. Aro kutukutu ni won maa n so omo loruko tori pe owo ero ni asiko owuro je gege bi asa. Baale ile tabi iyaale ile lo maa n dari eto yii, awon obi omo a file ponti, won a fona roka fun awon alejo won.
Leyin pe won a file ponti, won gbodo to ju awon nnkan apeere kan fun eto isomoloruko gan-an. Awon nnka bii oti, orogbo, obi, aadun, omi, iyo, suga, ireke, ataare, oyin, epo pupa ati awon nnkan miran. Awon ohun elo ni a n pe ni eroja isomoloruko. Won a maa fi oruko ti a n pe eroja kookan ati bi eledaa se seda won se adura fun omo naa. Bi apeere, won le fi aadun se adura fun omo naa gege bi oruko re pe aye omo naa yoo dun kale.
Oniruuru orin ni won maa n ko nibi ayeye isomoloruko ti won yoo si maa ke ewi lorisirisi. Ko si ewi kan pato ti a ko le lo ni iru ayeye yii, to ba sa ti ba inu didun lo, yato si awon bii meloo kan bii oku pipe, iremoje, ekun-iyawo.
Apeere orin to je mo ikomojade
A. Iya abiye o ku ewu o
Ewu ina kii pawodi
Awodi o ku ewu
B. Edumare fun wa lolu omo
Edumare fun wa lolu omo
Olu omo maa n da wa lorun o
Edumare fun wa lolu omo
OHUN ELO ISOMOLORUKO IWURE/ADURA |
Odidi ataare lagbaja, wa a dirun, wa a digba |
Obi (abata) obi ni biku, obi ni bi arun ki iku maa pa o. |
Eja aaro Eja re o, ori leja fi n labu ori re o ni buru |
Orogbo orogbo re o, wa gbo wa to |
Oti oti ki i ti, oti ki I te omo yii o ni ko ni ti/te |
Omi tutu omi re o, ko ni gbodi lara re |
Owo ki omo ma rahun owo |
IGBELEWON
1 Ko ohun elo ismoloruko marun sile
2 Bawo ni won se n lo won nibi isomoloruko.
3. Awon ewi atenudenu wo ni a le lo nibi ayeye ikomojade
ORISIRISI ORUKO
AKOONU: Oruko amutorunwa
Oruko abiso
Oruko abiku
Oruko oriko
Oruko amutorunwa ni oruko eyi ti a n pe omo gege bi ona tabi ipo ti omo gba waye nigba ti won bi.
ORUKO ITUMO
Tiawo/Kehinde akobi ninu awon ibeji(aburo)
Kehinde omo ti a bi tele Taiwo
Idowu omo ti a bi tele awon ibeji
Ige omo ti o ba ese waye
Dada omo ti irun ori re ta koko
Ajayi omo ti o da oju bole nigba ti a bi
Oke omo ti o di ara re sinu apo felefele waye
Olugbodi omo ti ika owo re tabi ika ese re pe mefa
ORIKI ABISO: Awon oruko ti o n toka si ipo tabi aaye ti awon obi omo wa nigba ti won bi omo naa.
ORUKO ITUMO
Abiodun/Adebodun omo ti a bi ni akoko odun Pataki kan
Babawale/Babatunde omobinrin ti a bi leyin iku baba re agba
Iyabo/Yetunde/Yewande omombinrin ti a bi leyin iku iya re agba
Abiona omobinrin ti iya re bi si oju ona
Abiose/Abosede omo ti a bi ni ojo ose (aiku)
Abiara omo ti oyun re ko ti I han ti baba re fi ku.
ORUKO ABIKU: Abiku ni omo ti a bi ti n ku lemlemo. Apeere oruko won ni Enilolobo, Kukoyi, Malomo, Kosoko, Durojaye.
ORUKO IDILE: Awon oruko wonyi ni se pelu, esin tabi ipo ebi ni awujo
ESIN ORUKO
Ifa Awoseeka, Fabunmi, Faleti, Dopemu.
Ogun Ogunbiyi, Ogunleye, ogundiran
Sanponna Babayemi, Obafemi, Anibaba
ORUKO ORIKI: Awon oruko yii je oruko ti a fi n pon eeyan le.
ORUKO OKUNRIN ORUKO OBINRIN
Alani, Ajani, Alabi, Adio, Alao Amoke Ajike, Ayinke, Ajihun, Akanke
Asamu, Ayinla, Ajagbe Adunni, Alake Asake, Ajoke.
IGBELEWON
- Ko ohun elo isomoloruko meje sile ki o si salaye bi a se n lo won.
- Ko onka lati 400-500.
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book Two Copromutt Publisher oju iwe 87-88
EWI ALOHUN AJEMAYEYE
Orisirisii ewi atenudenu ni a ni ni ile Yoruba ti a maa lo nibi ayeye, awon ewi atenudenu yii ko lo n ka. Lara iru awon ewi bayii ni a ti ri Rara, Olele, Oku-pipe, Alamo, Ege, Ekun-Iyawo, Efe, Dadakuada, Etiyeri ati bee bee lo.
Bi orisirisii ayeye se wa bii ayeye igbeyawo, isinku agba, ikomojade, isile, oye jije ati bee bee lo, bee naa ni awon Yoruba ni oniruru ewi ti o ba okookan mu sugbon awon ewi alohun ti a le lo nibi igbeyawo ni a fe gbe yewo.
Bi o tile je pe ekun iyawo gan ni ewi atenudenu ti a ya soto fun aseye igbeyawo, ti o si gbe oruko iyawo lori, awon ewi atenudenu kan wa to je pe ojo ni won, sasa ni ibi ayeye ti won kii ti lo won. Iru awon ewi atenudenu bee ma n waye nibi ayeye igbeyawo bakan naa. Die ninu awon ewi naa ni rara, ege, olele, apepe, obitun, dadakuada ati bolojo.
LITIRESO ATENUDENU EYA/AGBEGBE
Rara Oyo
Olele Ijesa
Biripo Ikale/Ilaje
Ekun iyawo Oyo
Bolojo Ye wa(Egbado)
Alamo Ekiti
Adamo Ife
Igbala Egba
Dadakuada igbomina
Orin etiyeri Oyo
Ege/Ariwo Egba
Orin Edi Ile-ife
Obitun Ondo
Apepe Ijebu
IWE AKATILEWA
1 Egbe Akomolede ati Asa (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) Longan Nig Ltd oju iwe123-127.
APAPO IGBELEWON
- Ko ohun elo isomoloruko meje sile ki o si salaye bi a se n lo won.
- Ko onka lati 400-500.
- Ko ohun elo ismoloruko marun sile
- Bawo ni won se n lo won nibi isomoloruko.
- Awon ewi atenudenu wo ni a le lo nibi ayeye ikomojade
- Ko aroko lori bi o se lo isinmi keresimesi.
ISE ASETILEWA
- 500 ni A. irinwo B. igba D. oodunrun E. eedegbeta.
- Marundinleedegbeta ni A. 95 B. 295 D. 495 E. 395.
- Ewi alohun ti o wopo ni Ijebu ni A. Apepe B. Obitun D. ekun iyawo E. rara.
- Ewi alohun ti o wopo ni dadakuada ni A. apepe B. Obitun D. Dadakuada E. rara.
- Omo ti o doju bole nigba ti a bi ni A. Ajayi B. Dada D. Idowu E. Taye.
APA KEJI
- Ko onka lati 400-500.
- Ko oruko amutorunwa marun pelu alaye.