Itoju Alaboyun (1)Igbagbo Yoruba nipa agan, omo bibi ati abiku.

Ò̩SÈ̩ 3

EDE: Akoto siwaju JEC 1974; Agbeyewo ipinnu 1974 ti ijoba apapo lori akoto Yoruba (Joint Consultative                     Committee-JCC

ASA: Itoju Alaboyun

(1)Igbagbo Yoruba nipa agan, omo bibi ati abiku.

Awon ti oyun nini wa fun (tokotaya).

Ona ti a le gba din bibi abiku ku lawujo wa;

Orisiirisii jenotaipu eje to wa ati awon to le fe ara won.

     

Akoto Siwaju JEC 1974; Agbeyewo Ipinnu 1974 Ti Ijoba Apapo Lori Akoto Yoruba (Joint Consultative           Committee-JCC.

Àko̩tó̩ ni ìlànà tí a fi ń ko̩ èdè sílè̩ ló̩nà tó tó̩. Èyí ni kíkó̩ sípé̩lì èdè sílè̩ ní o̩na tó boju mu. O̩duń 1842 ni ede Yoruba di kíko̩ sílè̩, pè̩lú ìrànwó̩ Samuel Ajayi Crowther. Ìpade ako̩ko̩ wáyé ni 28-29/1/1875 laaarin awo̩n Ìjo̩ Síe̩me̩è̩sì, Mé̩tó̩díìsì àti Kátólíìkì ní ilé O̩ló̩run Mímó̩ ni ilu Èkó.

Ni os̩ù ké̩sàn-án, o̩dun, 1974, Ìjo̩ba Àpapò̩ yan igbimo̩ kan lati s̩is̩é̩ lori àko̩tó̩. Àbájáde ìgbìmò̩ yii ni ako̩to̩ ti a ń lo ní èdè Yoruba di òní.

SÍPÉ̩LI̩ ÀTIJÒ̩ SÍPÉ̩LI̩ TITUN                      
1.       Aiya 1.       Àyà
2.       Aiye 2.       Ayé
3.       E̩iye̩ 3.       E̩ye̩
4.       Nwo̩n 4.       Wo̩n
5.       O̩tta 5.       Ò̩tà
6.       Oshogbo 6.       Òs̩ogbo
7.       Shade 7.       S̩adé
8.       O̩kùrin 8.       O̩kùnrin
9.       E̩iye̩le 9.       E̩ye̩lé

 

IGBELEWON:

  1. Sípélì yii kò bá àko̩tó̩ titun mu.
  2. O̩ló̩pàá
  3. Yoo
  4. Tinyin
  5. Náà

Ò̩rò̩ tí àko̩tó̩ rè dára ni ——————–

  1. Aké̩kò̩ó̩
  2. Ò̩ffà
  3. Shágámù
  4. È̩nyin.

Tún àwo̩n sípé̩lì ò̩rò̩ wò̩nyí ko̩ ni ìlànà àko̩tó̩ òde-òní:

  1. Wípé
  2. Nígbagbogbo
  • Nígbàtí
  1. Jé̩kí
  2. E̩iye̩lé
  3. Gégébí

 

 

 

ASA: Itoju oyun

Itoju Alaboyun (1) Igbagbo Yoruba nipa agan, omo bibi ati abiku. Awon ti oyun nini wa fun (tokotaya).Ona ti a le gba din bibi abiku ku lawujo wa; Orisiirisii jenotaipu eje to wa ati awon to le fe ara won.

Ìtó̩jú Aláboyún

 

AKORI ISE: – OYUN NINI. ITOJU ATI OMO

Obinrin ti ko bimo ni leyin ojo pipe ni ile oko ni won n pe agan. Awon yoruba ka omo bibi si pupo, won gba pe ko si bi oro eniyan ti le po to ti ko ba bimo, aye asan ni oluwa re wa. Abiku nigba miran le so obinrin di agan.

Itoju oyun laarin osu kinni si iketa ko le. Obinrin ko gbodo naju. ki oyun re maa baa wale. oko gbodo maa ran an lowo ninu ise ile. leyin osu keta ni oko aboyun yoo to wa onisegun ti yoo maa toju aboyun lati ri pe oyun naa ko baje tabi bi omo ti ko pe ojo.

               Aajo fun aboyun leyin osu keta ni wonyii

  1. OYUN DIDE : -Bi oyun ba di osu meta ni won o ti dee . Ki oyun maa baje lara obinrin ni won se maa n de oyun titi di akoko ti yoo bimo. Osu kesan-an, tabi to ojo b ape ni won yoo to ja oogun na asile, ki aboyun si bimo.
  1. EEWO KIKA FUN ABOYUN : – Awon nnkan ti asa yoruba ko gbe aboyun laaye lati se ni an pe ni eewo. ona lati daabo bo oyun inu ni o bi eewo. Bi apeere
  2.           Alaboyun ko gbudo sise lile
  3.           Alaboyun ko gbudo rin ninu orun tabi ni oru

            III.          Ko gbodo je igbin, ki om ore maa ba dota

  1.           Oko aboyun to je ode gbodo sora pipa eranko abami ni akoko ti iyawo re wa ninu oyun.
  1. ASEJE FUN ABOYUN
  1. AGBO WIWE ATI MINU : Onisegun agbebi yoo se orisirisi aseje tabi agbo fun aboyun
  1. OSE AWEBI ATI AGBO ABIWERE : Ti oyun ba ti osu mejo onisegun yoo fun-un ni agbo abiwere, eyi yoo mu ara de.

ITOJU OYUN TI ODE ONI

Bi obinrin baa ti loyun ni yoo ti lo fi oruko sile ni ile iwisan ijoba ipinle tabi ibile ni agbegbe refun ayewo ati itoju. Alaboyun yoo maa lo si ile iwosan bee loorekoore gege bi adehun tito ti yoo fi bimo.

  1.           Idanilekoo ati ayewo omo inu
  2.           Oogun ati abere

  III.          Ounje afaralokun

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share